Yusuf to fọ ṣọọbu ni Lafẹnwa loun jẹbi, ladajọ ba ni ki wọn da a pada sẹwọn

Spread the love

Ọgba ẹwọn ti wọn ti gbe ọmọkunrin kan, Yusuf Shittu, ọmọ ọdun mẹrinlelogun, wa si kootu majisireeti Iṣabọ ni adajọ tun paṣẹ pe ki wọn da a pada si, iyẹn lẹyin to jẹwọ pe loootọ loun fọ ṣọọbu ni Lafẹnwa, Abẹokuta.

 

Ọsẹ to kọja yii ni kootu ṣafihan Yusuf. Inspẹkitọ Ajewọle Richard lo fidi ẹ mulẹ pe ni nnkan bii aago meje alẹ ọjọ kẹrinla, oṣu kẹjọ yii, Yusuf gba ọna ẹburu wọ inu sọọbu kan to jẹ ti Idowu Akirinọla, nibi ti iyẹn ko awọn irin to n ta si, o si ji irin oju fẹrẹse kan, atawọn irinṣẹ meji mi-in ti wọn fi irin sẹ.

 

Apapọ iye ohun to ji naa ni wọn lo jẹ egbẹrun lọna ọgọrin Naira (80,000). Agbefọba ṣalaye pe ẹsun meji ni olujẹjọ yii n jẹjọ rẹ, akọkọ ni fifọ ṣọọbu wọle, ikeji si ni jiji ọja nibẹ, eyi ti mejeeji lodi sofin iwa ọdaran ti wọn gbe kalẹ nipinlẹ Ogun lọdun 2006, to si ni ijya ẹwọn labẹ ofin.

 

Nigba to n dahun si ẹsun ti wọn fi kan an, Yusuf ni loootọ loun huwa naa. O loun wọle sinu ṣọọbu yii lọna ẹburu, oun si jale gẹgẹ bi ile-ẹjọ ṣe wi. O ni boun ti jẹwọ yii, oun fẹ ki kootu naa ṣiju aanu wo oun, oun ko ni i ṣẹ bẹẹ mọ.

Adajọ O.A Ọnagoruwa to gbọ ẹjọ rẹ paṣẹ pe ki wọn da a pada sọgba ẹwọn na, to ba di ọla ti i ṣe ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kọkandinlọgbọn, ki wọn tun gbe e wa si kootu, nigba naa loun yoo dajọ rẹ ni ibamu pẹlu alakalẹ ofin ole jija to ṣẹ si.

(45)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.