Yisa tẹwọn de, lo ba ta tirela ọga ẹ ni gbanjo

Spread the love

Tẹwọn de ni ọkunrin Ibo kan to pe orukọ ara ẹ ni Yisa Nwachukwu. Ọkada Bajaj lo ji ti wọn fi ran an lẹwọn tẹlẹ, to di ọkan ninu awọn torukọ wọn wa ninu iwe ẹwọn. Ṣugbọn ọwọ awọn ọlọpaa tun ti tẹ ẹ bayii, nigba to ji tirela ọga ẹ, to tu awọn ẹya ara ọkọ nla naa palẹ, to si ta a ni gbanjo fun Yusuf Sanusi to wa niluu Ọta, nipinlẹ Ogun.

Nigba to n ṣalaye bọrọ naa ṣe jẹ lẹyin tọwọ ba a tan, Yisa sọ pe oun ko deede sọ mọto ọga oun di ẹran toun bẹrẹ si i kun yẹlẹyẹlẹ lati ta a. O ni ọga oun naa, Alaaji Owonifaari, toun n ṣiṣẹ fun gẹgẹ bii dẹrẹba ni ko sanwo oṣu foun, iyẹn loun ṣe ronu lati ta mọto tirela MAN DIESEL naa ni gbanjo.

Nwachukuwu fi kun un pe Nssuka, nipinlẹ Enugu, loun kọri si lẹyin toun ti pinnu lati ta tirela ọga oun, ṣugbọn niṣe lọkọ naa yọnu loju ọna, ko ṣiṣẹ mọ. O ni nigba toun ko si lowo toun yoo fi tun un ṣe loun ṣe pe onibaara oun, Yusuf Sanusi, pe ko maa bọ kawọn yanju ọrọ ọkọ nla toun fẹẹ ta fun un naa.

Ilu Ọrẹ, nipinlẹ Ondo, lo ni Yusuf ti waa ba oun, awọn si ṣeto bi wọn ṣe fi ọkọ to maa n wọ mọto to ba taku (Towing vehicle) wọ tirela naa lati ibẹ lọ s’Ọta, nipinlẹ Ogun. Ẹgberun lọna irinwo (400,000), lo ni oun ta tirela naa fun Yusfuf Sanusi.

Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ sọ f’ALAROYE pe nibi ti wọn ti n tu ọkọ nla naa palẹ ni ọja irin Ojolowo, to wa l’Ọta, ni olobo ti ta DPO teṣan ọlọpaa Onipaanu, SP Ṣangobiyi Johnson, tiyẹn fi ko awọn ọlọpaa sodi, ti wọn si mu Yisa to ta ẹru elẹru ati Yusuf to ra a lọwọ ẹ.

Nigba to n dupẹ lọwọ awọn ọlọpaa to mu awọn afurasi meji yii, Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Ahmed Iliyasu, rọ awọn to n gbaayan siṣẹ lati mọ ẹni ti wọn fẹẹ fun niṣẹ daadaa, ki wọn ma lọọ fi awọn ole bii Yisa Nwachukuwu ṣe oṣiṣẹ wọn.

(19)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.