Yẹmi to gun afẹsọna ẹ pa n’Ijakọ ti wa latimọle

Spread the love

Ololufẹ ni awọn eeyan ojule keje, opopona Alade, Owode Ijakọ, nipinlẹ Ogun, mọ Yẹmi Salaudeen ati Oluwakẹmi Ilo si. Bo tilẹ jẹ pe wọn maa n ja, ko sẹni to mọ pe Yẹmi yoo ba ariyanjiyan to maa n waye laarin wọn de ibi gigun ololufẹ ẹ pa. Afi lọjọ Abameta, Sannde, ọjọ kẹjọ, oṣu kẹrin yii, ti wọn ni Yẹmi wọle gun Kẹmi pa, iyẹn naa lo si sọ ọmọkunrin naa di ero atimọle ọlọpaa bayii.

Gẹgẹ bi Iya Kẹmi, Tawakalitu Ilo, ṣe ṣalaye f’ALAROYE, o ni ni nnkan bii aago meji aabọ oru ọjọ Sannde ni wọn waa ji oun nibi toun sun si pe koun waa wo ọmọ oun ninu agbara ẹjẹ, pe ẹnikan ti gun un bajẹ. Iya to n ta ounjẹ yii ṣalaye pe ẹru ba oun nigba toun ba ọmọ oun nilẹẹlẹ to n pọkaka iku, lawọn eeyan ba sare ran oun lọwọ lati gbe e de ọsibitu, ṣugbọn loju ọna ni Kẹmi, ọmọ ọdun mẹẹẹdọgbọn, dakẹ si.

Obinrin naa sọ pe ẹsẹkẹsẹ toun ri ọmọ oun ninu ẹjẹ loun ranti ileri iku ti Yẹmi, afẹsọna ẹ, ṣe fun un niṣoju oun, o ni ojowu buruku kan ni Yẹmi, ọpọ igba lo ti lu ọmọ oun lalubami lai jẹ pe o ti fẹ ẹ sile bii iyawo, ohun to si maa n tori ẹ na an ko ṣẹlẹ.

Iya Kẹmi sọ pe afẹsọna ọmọ oun maa n fẹsun kan an pe o n fẹ awọn ọkunrin mi-in yatọ soun, eyi ti ko ri bẹẹ. o ni Kẹmi maa n waa ba oun ta ounjẹ fawọn kọsitọma ni, ko si ẹni to n fẹ ninu wọn. Ṣugbọn owu jije ki i jẹ ki Yẹmi gbadun, niṣe lo si maa n lu ọmọ oun lori ohun ti ko ṣẹlẹ rara.

Tawa fi kun un pe ọpọ igba ni Yẹmi ti lu ọmọ oun ti Kẹmi ko jẹ koun gbọ, to jẹ awọn araale ni wọn yoo maa sọ ohun to ṣẹlẹ laarin wọn foun nigba ti afẹsọna ẹ ba wale waa lu u.

Awọn iwa yii lo su ọmọ oun to fi loun ko fẹ Yẹmi mọ, iyẹn naa lo fa atẹjiṣe idunkooko mọ ni ti Yẹmi fi n sọwọ sori foonu Kẹmi pe oun yoo pa a ni. Iya Kẹmi sọ pe o tun waa leri fun ọmọ oun ati oun naa, o si fẹrẹ bu oun pa lọjọ to wa sile awọn gbẹyin pẹlu, ko si pẹ lẹyin iyẹn ni wọn waa gun Kẹmi pa mọle.

Awọn ọdọ adugbo gbe iṣẹlẹ naa kari nigba ti Kẹmi ku, wọn wa Yẹmi lọ sile rẹ, ibi to si ti n di baagi rẹ to fẹẹ maa sa lọ ni wọn ba a, ni wọn ba gba baagi lọwọ ẹ, wọn si fa a fọlọpaa.

Ohun ti a gbọ nipa ọmọkunrin ti wọn ni ikorita Iyana Ilogbo lo maa n duro si pẹlu awọn ṣọja kan ti wọn yoo maa gbowo lọwọ awọn awakọ ni pe ko niṣẹ gidi kan lọwọ. Wọn ni ayederu ṣọja ni, ati pe iwe idanimọ iṣẹ ologun to wa lọwọ oun nikan to marun-un, nitori bo ti n pe ara ẹ ni ṣọja ni yoo maa sọ pe ọmọ ajọ Sifu Difẹnsi loun. O tun ni ti awọn Man O war ati Ligeon pẹlu, bẹẹ lo ni ti Navy naa mọ ọn.

Ṣa, atimọle ni Yẹmi Salaudeen ti wọn fura si ọhun wa bayii, nibi to ti n ran awọn ọlọpaa lọwọ ninu iwadii wọn.

Pic: Kẹmi Ilo nigba to wa laye

Yẹmi Salaudeen ti wọn lo gun un pa.

(40)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.