Wọn yọ ọlọpaa mẹta niṣẹ l’Ekoo, wọn ni ki ọkan foju ba ọga agba wọn fun idajọ

Spread the love

****Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, ti yọ mẹta ninu wọn, Sajẹnti Gbemunu Afọlabi, Sajẹnti Afọlabi Oluwaṣeun ati Kọburu Adigun Ọmọtayọ, lẹnu iṣẹ fun ẹsun iwa ibajẹ. Alukoro wọn, CSP Chike Oti, lo sọ eyi di mimọ ninu atẹjade to fi sita lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii.

Teṣan ọlọpaa Ijanikin, niluu Eko lawọn mẹtẹẹta ti n ṣiṣẹ. Oti ni lẹyin iwadii ẹka ileeṣẹ naa to maa n ṣe iwadii iwa ibajẹ lẹnu iṣẹ ni wọn paṣẹ pe ki awọn gbe igbesẹ yii, nitori wọn fidi rẹ mulẹ pe awọn mẹtẹẹta yii jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn naa.

Ni ti ẹni kẹrin wọn, iyẹn Insipẹkitọ Amiete, Oti ni awọn ti gbe iwe ẹsun rẹ lọ si iwaju igbakeji ọga agba ọlọpaa ti ẹkun keji, ki awọn fi le gba aṣẹ ki awọn too le e lẹnu iṣẹ naa.

Lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu to kọja, ni awọn agbofinro yii mu Theodore Ifunanya, ẹni to n gbe lorileede Togo, lasiko to wale ọdun, wọn ni awọn fura si i pe adigunjale ni. Lasiko ti wọn n yẹ ara rẹ wo ni wọn ba ẹgbẹrun lọna irinwo din laaadọta owo ilẹ okeere  (350,000.00 Cefas), nikaawọ rẹ, ti wọn si gba a.

Lẹyin iwadii, wọn ri i pe Ifunnaya ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an, ṣugbọn nigba ti wọn da a silẹ to si beere owo ti wọn gba lọwọ rẹ ni awọn eeyan yii kọ jalẹ lati da a pada fun un.

Ọrọ yii ni ọmọkunrin naa fi to ọga ọlọpaa to wa ni teṣan Area K, laduugbo Marọgbọ, ACP Hope Okafor, leti, ẹni to paṣẹ pe ki wọn da owo rẹ pada fun un lẹsẹkẹsẹ.

Lẹsẹkẹsẹ ni ọga ọlọpaa naa fi ẹjọ awọn afurasi kanda ninu iṣẹ ọlọpaa yii sun Imohimi Edgal to jẹ kọmisanna ọlọpaa nipinlẹ Eko,  ẹni to paṣẹ pe ki wọn ṣewadii wọn. Ninu aṣẹ ti Edgal pa, o ni ki wọn gbe ọga ọlọpaa teṣan Ijanikin, CSP Eugene Ubine, kuro ni ibi to wa, nitori iwa rẹ fi han pe ko kunju oṣuwọn lati mojuto awọn ọlọpaa to wa labẹ rẹ.

 

(10)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.