Wọn yọ ọkan ati ọwọ oku lọ ni mọṣuari l’Ekoo

Spread the love

Lọwolọwọ bayii, ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko ti bẹrẹ iwadii lori ọna ti oku kan gba sọnu ni mọṣuari ti wọn gbe e pamọ si, to si jẹ pe lẹyin ti wọn ri oku naa pada, wọn ti yọ ọkan re, bẹẹ ni wọn ti ge ọwọ rẹ lọ.

Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja, nileeṣẹ ọlọpaa ṣafihan awọn afurasi meje tọwọ tẹ lori iṣẹlẹ naa. Lara wọn ni Oluṣesi Owamade ati Micheal Oluṣẹgun, ti wọn jẹ oṣiṣẹ Ọsibitu St. Rapheal Devine Mercy Specialist Hospital, wọn ni awọn mejeeji ni alaabojuto yara ti ẹya ara oku naa ti sọnu.

Awọn marun-un mi-in ti wọn maa n gbẹlẹ oku: Razaki Abẹsopiti, ẹni aadọta ọdun, Ọkẹowo Kazeem, ẹni ọdun mẹrindinlaaadọta, Babatunde Giwa, ẹni aadọta ọdun, Ade Aliu, ẹni ọdun mẹtalelogoji, ati Musiliu Yakubu, ẹni ọdun mẹrindinlọgọta, ni wọn tun mu pe wọn lọwọ ninu iwa ọdaran naa.

Kọmisanna ọlọpaa nipinlẹ Eko, Imohimi Edgal, sọ pe aburo oloogbe naa, Anthony Lawani, lo mu ẹsun lọ si teṣan ọlọpaa pe oun ko ri oku ẹgbọn oun ni mọṣuari mọ. Ẹsun yii ni kọmisanna ọlọpaa fi to ẹka to n ṣewadii iwa ọdaran ni Panti, Yaba, leti.

Lasiko iwadii ni wọn ri i pe Oluṣesi Owamade, ẹni ọdun mokanlelogoji, lo ṣeeṣi gbe oku naa fun awọn mi-in.

Lọna ati ri oku olokuu gba pada, niṣe ni wọn gba awọn to maa n gbẹlẹ oku to n ṣiṣẹ ni iboji to wa ni Sabo, Ikorodu, wọn ni ki wọn ba awọn hu oku naa jade, ki awọn le gbe e fun awọn to ni in.

Edgal ni lasiko ti wọn n ṣe eleyii ni wọn ti ge awọn ẹya ara oku naa kuro, iyẹn ọrun ọwọ rẹ mejeeji, ati ọkan oloogbe naa, bẹẹ awọn ọlọpaa ko ti i le sọ ni pato nnkan ti wọn fẹẹ fi i ṣe.

Ọga ọlọpaa naa ni iwadii ṣi n tẹsiwaju lori iṣẹlẹ yii, ati pe awọn ṣi n wa ọkan ninu awọn ti wọn jọ hu oku yii, Anifowoshe, ẹni to ti sa lọ bayii.

O ni laipẹ lawọn maa gbe awọn afurasi naa lọ si kootu.

 

(2)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.