Wọn ti yan Ogunṣua tuntun niluu Mọdakẹkẹ

Spread the love

Fọfọọfọ ni aafin Ogunṣua ti ilu Mọdakẹkẹ kun lọsan-an Tọsidee to kọja, nigba ti wọn n ja ewe-oye le Ogunṣua tuntun, Ọba Moses Ọladẹjọ Oyediran, Ajombadi kẹta lori.

 

Baba ẹni ọdun mejilelaaadọrun-un ọhun lo jẹ Balogun niluu Mọdakẹkẹ ko too di pe Ogunṣua ana, Ọba Francis Ọlatunji Adedoyin, waja lọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹjọ, ọdun yii.

 

Gẹgẹ bii aṣa awọn eeyan ilu naa, Balogun lo maa n kangun si ọba, ti ọba ba si ti waja, Balogun ni yoo bọ sori akete naa lai ni ariyanjiyan kankan ninu, bẹẹ ni Oloye Ọtun yoo bọ sipo Balogun, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

 

Eyi lo fa a ti awọn afọbajẹ ilu Mọdakẹkẹ, pẹlu awọn ijoye atawọn alaṣẹ kansu ibẹ fi mu Ọba Oyediran lati ile Ajombadi, o si di Ogunṣua ti ilu Mọdakẹkẹ lọsẹ to kọja tilu-tifọn.

 

Ọba Oyediran ni Ogunṣua kọkandinlogun ti yoo jẹ niluu Mọdakẹkẹ latigba ti wọn ti tẹ ilu naa do, o si ṣeleri lati lo ọgbọn ati imọ ti Ọlọrun fun un fun idagbasoke ilu Mọdakẹkẹ.

 

(12)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.