Wọn ti tun bẹrẹ: ara yin lẹ n tan jẹ, awa kọ

Spread the love

Awọn oloṣelu fẹran ki wọn maa tan ara wọn. Wọn yoo maa tan ara wọn, wọn yoo si ṣe bi awọn n tan araalu, wọn ko mọ pe ki i ṣe gbogbo araalu naa kuku loponu, pupọ ninu awọn eeyan ilu lo gbọn ju awọn oloṣelu yii lọ. Nigba ti Ọgbẹni Raufu Arẹgbẹṣọla yoo gbe ijọba silẹ, ti awọn oniroyin ba a sọrọ, ohun to sọ ni pe oun n lọ sile lọọ sinmi ni, oun ko ni i ṣe oṣelu fun igba pipẹ. Wọn tun beere lọwọ ẹ nigba keji, o ni oun ko raaye gbadun iyawo oun lati ọjọ yii wa, oun n lọọ jokoo ti iyawo oun nile ni. Ṣugbọn ọkunrin yii ko ti i lo ọsẹ kan nile bayii ti awọn kan ti n kọwe wa, ti wọn ni ki ijọba apapọ tete fun Arẹgbẹ ni iṣẹ kan ko maa ṣe fun wọn, iwe ti wọn n to fun un ni bi yoo ṣe di minisita tabi olori ileeṣẹ ijọba apapọ kan. Wọn pọn ọn le sinu iwe ti wọn kọ yii, wọn ni injinnia to moye ni, o mọ iṣẹ ẹnjinni naa debi gongo. Ko sẹni to mọ boya Arẹgbẹ lo sọ fun wọn pe injinia loun ati iru iṣẹ injinni to ti ṣe ko too di oloṣelu, to si di gomina. Wọn ni Arẹgbẹ lo gbe ipinlẹ Ọṣun debi ti ẹnikan ko lero pe ipinlẹ naa yoo de laelae, ati oriṣiiriṣii awọn ọrọ dindinrin bẹẹ. Bi eeyan ko ba mọ iwa awọn oloṣelu daadaa, niṣe ni yoo bẹrẹ si i ṣepe fun iru awọn eeyan yii, ti yoo ni ta lo ran wọn ni iṣẹ buruku ti wọn n jẹ kiri. Ṣugbọn nigba ti eeyan ba mọ wọn, ti ẹ ba lọọ wadii ọrọ yii wo daadaa, ẹ o ri i pe wọn ko ni i gbe iru iwe bẹẹ jade bi ẹni ti wọn n sọrọ rẹ yii ko ba mọ, nigba mi-in, ẹni ti wọn n sọrọ rẹ paapaa ni yoo ṣeto naa pe ki wọn polowo oun, ki oun le ri nnkan gba nibi kan. Nibẹ lawọn ti wọn ko mọ idi abajọ yoo ti bẹrẹ kotokoto, ti wọn yoo maa ṣe aṣetunṣe alaye, nitori tọrọ-kọbọ ati igo bia bii meloo ti wọn ba ti ra fun wọn. Arẹgbẹṣọla ti loun fẹẹ sinmi, ẹ jẹ o sinmi o. Bo ba si jẹ loootọ lo jẹ ẹnjinnia to moye, ko da iṣẹ injinnia silẹ, ko gba ọpọlọpọ awọn eeyan siṣẹ naa, ko si fi ọna han awọn ẹgbẹ ẹ pe beeyan ba ṣe gomina tan, ki i ṣe ko tun maa le iṣẹ ijọba kiri, ko kọkọ funra ẹ ni isinmi ọlọjọ gbọgbọrọ. Abi ki l’Arẹgbẹ funra ẹ ri siru imọran banta-banta ta a foun yii!

 

 

 

Ọkan lara awọn oṣiṣẹ ijọba to ba akọroyin wa sọrọ ṣugbọn ta a forukọ bo laṣiiri sọ pe o jẹ ohun iyalẹnu pe nigba ti idibo ku oṣu meji nijọba n sare ati maa san owo ti wọn jẹ oṣiṣẹ. O ni bi igba ti wọn ba n fi aye awọn oṣiṣẹ ṣe oṣelu ni ọrọ naa ri.

 

 

 

(11)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.