Wọn ti sinku Iya Fẹla o, ṣugbọn Fẹla loun yoo fi posi iya oun ta Ọbasanjọ lọrẹ

Spread the love

Awọn ara Abẹokuta ti wọn ba ti gbọn daadaa ko ni i gbagbe ọjọ naa, nitori ọjọ nla kan ni. Ọjọ karun-un, oṣu karun-un, ọdun 1978, ọjọ Furaidee, ọjọ Ẹti, lọjọ naa bọ si, lọjọ ti wọn sinku Iya Fẹla nigboro ilu Abẹokuta. Ọrọ to ba ṣoju ilu ki i fi ara pamọ, nitori ohun to ṣoju ilu ki i fi ara sin. Awọn eeyan ti mọ pe wọn yoo sinku Arabinrin Funmilayọ Ransome Kuti lọjọ naa, awọn ara Eko naa ti mọ pe lọjọ naa ni wọn n gbe oku Iya Fẹla lọ si Abẹokuta, nitori bẹẹ lo si ṣe jẹ ati ijọba ati awọn araalu ni wọn mura silẹ fun ọjọ nla yii, paapaa julọ awọn ti wọn fẹẹ wo ara ti Fẹla yoo da. Wọn fẹẹ mọ bi yoo ti ṣe posi iya rẹ to gbe sile wọn tijọba ti gba lẹyin tawọn ṣọja dana sun un, wọn n reti pe boya posi naa ni yoo sin lọjọ naa ni abi oku iya rẹ, abi yoo tun pada waa sin posi ọhun si ibi ti ijọba ti gba lọwọ wọn ni. Ko sẹni to mọ ohun ti yoo ṣe o.
Ṣe ojumọ kan, ara kan lọrọ Fẹla, ko si si ara ti ko le da, iyẹn naa ni gbogbo aye ṣe n reti ohun ti yoo ṣe. Ariwo to si n pa lati ọjọ yii naa ni pe ijọba lo pa iya oun, Ọbasanjọ lo pa iya oun, ọrọ naa ko si ni i lọ bẹẹ afi ti oun ba gbẹsan, ti oun ba fi han wọn pe ojulowo ajẹ ni iya oun, ki i ṣe ẹni ti awọn kan yoo pa bẹẹ lai ni i lẹyin. Ohun tawọn eeyan ṣe n bẹru ree, ko kuku sẹni to mọ ara ti yoo da, wọn si mọ pe ko si ọran ti Fẹla da lọdọ ọlọpaa ati ijọba ti ko ni i kaju ẹ, wọn ti jọ da ara wọn mọ, onibaara ara wọn ni wọn n ṣe. Ṣugbọn araalu ti ko ba ṣọra rẹ, to ba fori ko ija awọn mejeeji, iyẹn ija ijọba ati Fẹla, oun ni yoo jẹ eyi to pọ ninu rẹ, nitori oun ni ijọba yoo fi ikanra mọ, bi wọn ba si gba a mu, wọn ko ni i fi i silẹ bọrọ. N ni kaluku ṣe n yẹra.
Amọ Fẹla ko waa fa ijangbọn kan lọjọ naa o, o ni ọjọ ẹyẹ iya oun ni. Koda, gbogbo awọn ọmọ amugbo to le fa wahala lo kilọ fun, o ni ki wọn ba gbogbo awọn ọmọọta paapaa sọrọ, ko sẹni kan to gbọdọ fa wahala, oun ko fẹẹ gbọ orin ọtẹ tabi orin owe, ki kaluku ṣe bii ọmọ olokuu, ki wọn gbe jẹẹ, nitori oku iya oun ni wọn n ṣe. Ṣe bi gbogbo aye yipada, bayii-ni-n-o-ṣe-nnkan-mi ki i yipada, bo ba si ṣe wu ni la a ṣoku iya ẹni. Fẹla ni oun ko fẹ wahala lọjọ oku iya oun, ko si sẹni to fa wahala nibẹ, wọọrọwọ ni ohun gbogbo lọ. Ko si le ṣe ko ma ri bẹẹ, nitori bi eeyan ba pe ibi isinku naa ni awujọ awọn eeyan nla nla agbaye, onitọhun ko jẹ ayo pa. Ṣe tawọn ọlọla ati olowo lati orilẹ-ede Naijiria nibi leeyan fẹẹ wi ni, abi ti awọn eeyan jankan-jankan ti wọn wa lati ilu ọba, lati ilu oyinbo kaakiri leeyan yoo sọ ni. Ero naa pọ ju.
Aarọ lawọn mọto ti gbera, mọto ti wọn fi n gbe oku ati awọn mọto mi-in loriṣiiriṣii, wọn tẹle oku Iya Fẹla, lati Eko ti wọn ti gbe e, wọn n lọ jẹẹjẹ si ọna Abẹokuta. Ko waa si ibi ti wọn gba kọja ti awọn eeyan ki i juwọ si oku rẹ, bi awọn mi-in ti n sọ pe o digba ni awọn mi-in n fọwọ gbo oju wọn lati fihan pe wọn n sunkun, iyẹn awọn obinrin ti wọn mọ ọn, wọn mọ pe olugbeja awọn lo n lọ nni, nitori nigba ti obinrin naa wa ninu agbara rẹ, ija to fi gbogbo aye rẹ ja naa ni pe ki awọn ọmọ Naijiria ni ominira lati ṣe ohun ti wọn ba fẹ, bẹẹ lo si n sọ pe ko si ohun ti ọkunrin da ti obinrin paapaa ko le da, bi a ba ti fun wọn ni ẹkọ to peye. Ohun to fa ipinnu ati ipolongo rẹ yii ko ju pe ni asiko tiwọn, ko si ọmọbinrin ti wọn n fẹ ko lọ sileewe, bẹẹ ni obinrin ki i sọrọ lawujọ, obinrin ko si le ṣe ohun to ba wu u, eewọ ni. Ṣugbọn Iya Fẹla kọ gbogbo iyẹn.
Nigba ti mọto to gbe oku rẹ yoo fi wọ igboro Abẹokuta, awọn obinrin gbogbo ti to sọna de e, awọn ti wọn ti lọọ duro de e lati Eko, awọn ti wọn wa lati Ibadan, ati awọn ti wọn wa lati ilẹ Hausa ati nilẹ Ibo kaakiri. Gbogbo ọja to wa ni Abẹokuta patapata ni awọn ọlọja ti pa, wọn ni ko si ẹni ti yoo na ọja kan lọjọ naa, ẹni ti ko ba ti ra ohun to fẹẹ ra ko too di ọjọ yii, yoo sun lebi ni, obinrin kan ko si de ọja taja, tabi de ọja raja, nitori iya wọn lo n lọ sile ikẹyin yẹn. Bi awọn mọto to gbe oku rẹ si ti n wọlu ni ariwo awọn obinrin naa bẹrẹ, ariwo ti wọn n pa ni, “Bẹẹrẹ! Bẹẹrẹ! Bẹẹrẹ!” ṣe orukọ ti wọn n pe ọmọbinrin naa niyẹn. Bo tilẹ jẹ pe ọmọbinrin ti wọn ba kọkọ bi ni wọn n pe ni bẹẹrẹ, idi ti wọn ṣe n pe oun ni bẹẹrẹ yatọ diẹ.
Abẹokuta Grammar School, ni ilu Abẹokuta, nibẹ ni obinrin yii ati ọkọ rẹ lọ. Nigba ti ileewe naa kọkọ bẹrẹ ni 1908, awọn ọkunrin nikan lo wa fun, ṣugbọn igba ti wọn n kọ orukọ awọn ọkunrin yii, orukọ ẹni akọkọ ti wọn kọkọ kọ ni Israel Oludọtun Ransome Kuti, oun ni nọmba waanu (Number one) ninu iwe orukọ wọn. Nidii eyi, kia lawọn ọmọọleewe naa yi orukọ rẹ pada, wọn ko si pe e ni Israel tabi Dọtun mọ, wọn sọ ọ di Daodu, iyẹn orukọ akọbi ọmọkunrin, eyi tumọ si pe oun ni akọbi ọmọkunrin Abẹokuta Grammar School. Nigba to tun waa ya ti ileewe naa ni awọn yoo maa gba awọn ọmọ obinrin sibẹ ni 1914, Funmilayọ Thomas (orukọ Iya Fẹla tẹlẹ niyi ko too wọ ile ọkọ) naa tun jẹ orukọ akọkọ ti wọn kọ ninu orukọ awọn ọmọbinrin ti wọn gba ni ileewe naa, iyẹn ni wọn ṣe sọ oun naa di Bẹẹrẹ, orukọ akọbi ọmọbinrin.
Ni gbogbo igba ti Funmilayọ fi wa n ṣe oṣelu ati ajijagbara rẹ kaakiri, orukọ ti wọn n pe e ni ileewe yii, iyẹn Bẹẹrẹ, naa lo pada mọ ọn lori, “Bẹẹrẹ, Bẹẹrẹ” ni wọn maa n pariwo nibi gbogbo ti wọn ba ti ri i, agaga lasiko ti ija ṣẹlẹ ni Abẹokuta lasiko Ọba Ademọla, ti orukọ obinrin naa si kari gbogbo agbaye bii ẹni to ba ọba ilu rẹ fa wahala, ti ọba naa si sa kuro niluu fun igba pipẹ. Iyẹn ni ko ṣe ya awọn ti wọn mọ itumọ orukọ yii lẹnu nigba ti wọn gbe oku obinrin naa wọ Abẹokuta, ti awọn ọlọja obinrin, awọn oṣiṣẹ ijọba lobinrin, awọn tiṣa to ti fẹyinti, ati awọn tiṣa to n ṣiṣẹ lọwọlọwọ bẹrẹ si i pariwo “Bẹẹrẹ! Bẹẹrẹ!” bi wọn ti n gbe oku rẹ wọ ilu Ẹgba lọ. Yatọ si awọn ẹgbẹ ọlọja ti wọn ba ara wọn sọrọ, ẹgbẹ olukọ naa jade, nitori ṣaaṣa awọn tiṣa lọkunrin lobinrin lo wa ni Abẹokuta ati agbegbe Ijẹbu ti ko gba abẹ Iya Fẹla kọja.
Ninu awọn tiṣa ti a n wi yii ti di ọga agba ni ileewe gbogbo, awọn yii si ko awọn ọmọọleewe wọn jade lati waa ṣe ẹyẹ ikẹyin fun olori awọn tiṣa ti wọn mọ, wọn ni ki wọn waa bu ọla fun Iya Fẹla, obinrin bii ọkunrin. Awọn mi-in gan-an wa lawujọ, awọn ti wọn ti di ọba, awọn ti wọn ti di ijoye, ati awọn ti wọn ti di oniṣowo nla to je ileewe Iya Fẹla ni wọn lọ, gbogbo awọn yii ni wọn wa, awọn ti wọn ko si le wa ranṣẹ wa, wọn ni awọn gbọdọ ṣe ẹyẹ ikẹyin fun tiṣa awọn. Ohun to mu ki ero pọ rẹpẹtẹ ree, ero naa si kọja afẹnusọ. Lati Ita-Ọṣin lawọn ero naa ti n rọ lọ, wọn si ba oku rẹ de itosi ile wọn ni Iṣabọ, iyẹn ibi ti wọn tẹ oku naa si ni Ransome Kuti Memorial Grammar School, lọna Kutọ. L’Abẹokuta nibẹ. Ibi ni oku naa wa tawọn eeyan n waa wo o, ti awọn olorin ati elere gbogbo si ṣere yika ileewe naa.
Ni bii aago mẹwaa ni wọn gbe oku naa kuro lọ si St John’s Anglican Church to wa ni Igbein, ṣọọṣi ti oun ati ọkọ rẹ n lọ nigba aye wọn ni. Ni ṣọọṣi yii ni wọn ti ṣe isin ikẹyin fun un, ẹni to si waasu nijọ naa, ọrẹ oun ati ọkọ rẹ ni, iyẹn Seith I. Kale, ṣe tiṣa loun naa ko too gba iṣẹ Oluwa, wọn si jọ n ja fun ẹtọ gbogbo awọn tiṣa nigba naa ni. Ọkunrin naa lo waasu, o si royin ẹni ti wọn n pe ni Funmilayọ Kuti, ọpọ awọn ti wọn wa nibẹ ni wọn n ṣomi loju, nitori ko tun sẹni to le mọ itan awọn eeyan naa to bi baba oniwaasu naa ti sọ ọ. Boji nibẹ naa ni wọn sin oku rẹ si lẹgbẹẹ ọkọ rẹ, saare igbalode ti wọn si ti gbẹ silẹ lọjọ to pẹ foun ati ọkọ rẹ naa ni wọn sin in si, ọpọ eeyan lo si royin rẹ lẹgbẹẹ saree rẹ nibẹ, wọn ni ko si meji iru rẹ, yoo si ṣoro ki wọn too ri ẹni to tun da bii Iya Fẹla. O fẹrẹ jẹ ọjọ naa lawọn eeyan ri odikeji Fẹla.
Ẹni to fẹran iya rẹ ni, nitori bẹẹ, jẹẹ lo n ṣe kiri, ko si ṣe laulau, tabi huwa ọmọ elere, tabi ko ba ẹni kan pariwo. Bi wọn ti n gbe iya rẹ si koto bẹẹ lo n miri, o si ya a lẹnu pe obinrin naa le ku bẹẹ, o ṣee ṣe ko ti ro pe iya oun ko ni i ku ni, tabi pe bi yoo tilẹ ku, yoo to bii ọmọ ọgọrun-un ọdun ko too lọ. Ṣugbọn iya rẹ ko pe ọmọ ọgọrun-un ọdun, koda ko pe ọgọrin, iyẹn si n dun un lọtọ, o si fẹrẹ maa ja omi loju. Nigba ti wọn sin oku naa tan, ti wọn si ṣe ẹyẹ ikẹyin, kaluku gba ile rẹ lọ. Ohun ti ọpọ eeyan ro ni pe ko tun si wahala ti wọn yoo ṣe lori ọrọ yii mọ, ati ile ti ijọba ti gba o, ati iku Iya Fẹla, wọn ti ro pe ko tun si ohun ti yoo ṣẹlẹ, tabi pe Fẹla yoo tun maa ba ijọba fa ijangbọn kankan. Ṣugbọn Fẹla mọ pe inu iya oun ko dun si Ọbasanjọ, nitori bii ọmọ lo jẹ si i, Ibogun ti wọn bi Ọbasanjọ si nitosi Ifọ, oko Thomas, Baba Funmilayọ yii ni.
Bo ba jẹ nibi ti nnkan ti daa ti ko si ija ni, tẹgbọn-taburo lawọn Ọbasanjọ ati Fẹla yoo maa ṣe, nitori ọmọ abule kan naa ni wọn iba jẹ. Ṣugbọn ọrọ ijọba ti pin wọn niya, iyẹn lo si fẹẹ jẹ ki inu bi Fẹla nigba ti Ọbasanjọ kọwe to n sọ pe obinrin nla kan ni iya rẹ, koda, o fẹrẹ le maa ṣepe fun olori ijọba ṣọja naa ki awọn eeyan too sọ pe ko ma ṣe bẹẹ, ko ṣa maa woran ni. Amọ lẹyin ti wọn ti sinku yii tan, Fẹla ṣi n leri, o ni oun yoo jẹwọ fun Ọbasanjọ pe akọni to ju ṣọja lọ loun, ati pe ki ṣọja too de ni iya oun ti n jagun, ologun si loun naa ti oun jẹ ọmọ rẹ, ẹnikẹni to ba si foju di oun yoo ri ija jagunjagun. O ni Ọbasanjọ ti fori ja ile agbọn, yoo si ri i pe agbọn yoo ta oun laipẹ rara. Awọn eeyan mọ pe Fẹla ki i leri lasan, ṣugbọn wọn ko mọ ohun ti yoo ṣe gan-an, wọn ṣa ti sinku, oku si ti wọlẹ, Ọbasanjọ naa ti n mura ati lọ. Kin ni Fẹla yoo tun ṣe.
Ni gbogbo asiko yii, posi ti Fẹla gbe si ori ile wọn ti wọn dana sun wa nibẹ o, ko gbe e kuro, o ni wọn yoo maa fi ranti iya oun ni. O ni iya oun lo ni ile, oun lo ni ilẹ to wa lori rẹ, oun ti oun jẹ ọmọ rẹ kan ya diẹ lara ibẹ lati fi kọle toun ni. Nigba to si ti jẹ oun lo ni ilẹ rẹ, oun naa lo nile, ko sẹni ti yoo gbe posi rẹ kuro lori ẹ, ibẹ ni posi naa yoo wa titi, ti oun yoo maa fi ranti iya oun. Ijọba Ọbasanjọ paapaa ko ni awọn gbọ, wọn ko da Fẹla lohun gbogbo bo ti n pariwo to. Bẹẹ ni wọn ko da ile rẹ pada fun un o, wọn ni ijọba ti gbẹsẹ le e, ko si si pe ẹnikẹni yoo tun lo ile naa mọ, o ti di ti ijọba. Amọ Fẹla ni ihalẹ lasan ni, ko sẹni ti yoo de ori ilẹ naa, nibẹ ni posi iya oun yoo maa gbe, ile rẹ niyẹn, oun lo ni in, bi oun ti oun jẹ ọmọ rẹ ko ba si le lo ibẹ, iya naa funra rẹ yoo maa lo nnkan rẹ ninu posi yii, ẹni ba fẹẹ gba ibẹ lọwọ rẹ nikan ni yoo ri ija oku ọrun. Lọrọ kan, posi Iya Fẹla wa nile ẹ lojule kẹrinla, Agege Motor Road, Mọṣalaṣi Idi-Oro.
Ohun to waa ṣẹlẹ ni pe ijọba ko wi fẹni kan, o si ti to bii oṣu mẹfa sẹyin ti wọn ti sin oku Iya Fẹla, lojiji lawọn oṣiṣẹ ijọba gbe katapila lọ sibẹ, awọn ṣọja si tẹle wọn, ni wọn ba fọ ile naa tuu tuu, wọn wo o ti ko ku sibi kan. Nibi ti wọn ti n wo gbogbo ile naa, ti wọn fẹẹ sọ ọ di ilẹẹlẹ lasan, posi Iya Fẹla to wa nibẹ farapa, nitori wọn re e lulẹ, katapila lo si fa ẹgbẹ kan posi ọhun ya. Ninu oṣu kẹwaa ni wọn tu ile naa kalẹ, Fẹla ko si si nile, o ti lọ si idalẹ kan ni. Boya awọn ologun ati awọn eeyan ijọba funra wọn ti ṣọ ọ daadaa ni o, ko sẹni to mọ, ṣugbọn wọn ṣaa ri i pe ko si ọkunrin olorin naa nile nigba ti wọn fi lọ sibẹ, ọna rẹ ti jin si Naijiria, o ti ba iṣẹ aje rẹ lọ. Awọn eeyan ni bo ba jẹ o wa nile ni, ọrọ naa le tun di ija tuntun, o le di wahala ko ni oun ko ni i gba, ki ija tun bẹrẹ laarin oun ati awọn ṣọja, ṣugbọn ko si nile.
Bi awọn eeyan ti wi, bẹẹ lọrọ naa ri, nitori nigba ti Fẹla de, o pariwo, o si binu gidigidi pe wọn ti wo ile naa palẹ, wọn si ti ba posi ti oun fi n ṣe iranti iya oun jẹ. Bẹẹ ni ki i ṣe ori ilẹ onilẹ loun gbe posi iya naa si, lori ilẹ rẹ to fi owo ara rẹ ra nigba to wa laye ni, ki lo waa de ti ijọba tabi ṣọja kan yoo debẹ lẹyin oun, nigba ti oun ti sọ fun wọn ni aimọye igba pe ofin ti wọn ṣe ti wọn ni awọn fi gba ile oun yẹn ko kan oun, ko de ọdọ toun rara. Ṣugbọn ko sohun ti Fẹla yoo ṣe mọ, o kan n leri lasan ni, ijọba kuku ti wo ile rẹ, wọn ti wo o, wọn si ti gba ilẹ naa, wọn ti gba a, wọn ti kọ ọ sibẹ pe ile naa jẹ ti ijọba ipinlẹ Eko, ki ẹnikẹni ma debẹ, ẹni to ba debẹ, awọn yoo ba a ṣẹjọ. Ijọba lo ṣa si ni gbogbo ilu, ẹni ti wọn ba gba ohun-ini ẹ, yoo fara mọ ọn ni, nitori bi tọhun lọ sile-ẹjọ kan, yoo jẹbi bọ nibẹ ni.
Amọ ni ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kọkanla, 1978, Fẹla ko awọn ọmọbinrin rẹ, iyẹn awọn iyawo rẹ, ati gbogbo awọn ọmọ elere rẹ, wọn gbera, o di ile wọn atijọ yii, nibi ti katapila ti wo gbogbo ibẹ tuu tuu bayii, ti posi iya rẹ to gbe sibẹ si n jorigbo nilẹ, to jẹ kidaa patako nikan. Nigba ti Fẹla de ilẹ naa, o ni ki wọn ba oun gbe posi iya oun, n lawọn iyawo ati awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ ati awọn ọrẹ rẹ to ba a lọ ba bẹrẹ si i gbe posi naa bii ẹni pe oku ṣi wa nibẹ, oun lo si ṣaaju wọn. Niṣe lo n binu, to si n fibinu sọrọ. O ni ki wọn wo aye Ọbasanjọ lode o, ẹni to kọwe sile awọn, to n ki iya oun ni mẹsan-an mẹwaa, to ni ko si iru obinrin bẹẹ laye mọ, pe ki wọn waa wo ohun to ṣe si posi to duro fun iranti ẹ, o ni gbogbo awọn eeyan naa yoo ri wayi pe Ọbasanjọ ti wọn n wi yii ki i ṣe eeyan gidi kan. Ọbasanjọ lo bu titi ti wọn fi gbe posi naa lọ.
Awọn oniroyin sare bi i leere ibi to n gbe posi naa lọ bayii, Fẹla ni, “A n gbe posi iya wa lọ, a n lọọ tọju ẹ titi ti a oo fi mọ ohun ti a oo ṣe fun ijọba yii. Ṣugbọn gbogbo ẹni to ba leti kẹ ẹ gbọ, ẹ sọ fun Ọbasanjọ pe ọrọ to wa nilẹ yii ko ti i tan o, ija naa n lọ siwaju si i ni, nitori ijọba ẹ lo ni posi yii, a n lọọ ṣeto lori ẹ lọwọ ni. Nigba ti a ba mọ ohun ti a fẹẹ fi posi iya wa ṣe, gbogbo yin lẹ maa gbọ!” Bẹẹ ni wọn gbe posi naa, o di ibi kan ti Fẹla ti gba ni Ikẹja, ori pulọọti kan to sare ṣe ibi kekere kan ti wọn n gbe si, iyẹn si wa ni ojule kin-in-ni, Atinukẹ Ọlabanji, ni Ikẹja. Ibẹ ni wọn gbe posi Iya Fẹla lọ. Ati pe loootọ loootọ, ọrọ naa ko tan sibẹ o jare. ‘O tun ku’ ni ibọn n ro ni.

(52)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.