Wọn ti n fi orukọ mi lu jibiti kaakiri o, Ọmọworaarẹ pariwo

Spread the love

Sẹnetọ to n ṣoju awọn eeyan iha Ila-Oorun Ọṣun nile igbimọ aṣofin agba orilẹ-ede yii, Babajide Omoworaarẹ, ti pariwo sita pe awọn gbaju-ẹ kan ti n fi orukọ oun lu jibiti kaakiri ori ẹrọ ayelujara.
Ninu ọrọ ti akọwe iroyin Ọmọworaarẹ, Tunde Dairo, ba ALAROYE sọ, o ni ṣe lawọn oniṣẹ ibi naa ṣi itakun feesibuuku kan lorukọ Sẹnetọ Ọmọworaarẹ, eleyii ti wọn n lo lati fi lu awọn araalu atawọn ololufẹ ọkunrin aṣofin yii ni jibiti.
Dairo ni oriṣiiriṣii iṣẹ ijọba apapọ ni wọn n polowo sibẹ, wọn yoo si sọ pe ẹnikẹni to ba nifẹẹ si awọn iṣẹ naa gbọdọ san iye owo kan pataki gẹgẹ bii owo idupẹ lati fi imoore wọn han.
Yatọ si eleyii, o ni wọn n lo itakun naa lati fi pa oniruuru irọ nipa Ọmọworaarẹ fun awọn eeyan Ifẹ/Ijeṣa to n ṣoju nile igbimọ aṣofin agba, bẹẹ ni wọn tun n sọrọ nipa ijọba lai ṣe pe ẹnikẹni ran wọn niṣẹ.
O sọ siwaju pe Sẹnetọ Ọmọworaarẹ ko tete gbọ si wahala tawọn eeyan ọhun n fi orukọ rẹ da silẹ kaakiri, afigba ti awọn araalu bẹrẹ si i pe akiyesi rẹ si iṣẹ ọwọ awọn ẹni ibi yii.
Dairo waa ke si awọn araalu lati ṣọra, ki wọn ma ṣe da iṣẹ kankan pọ pẹlu awọn amookunṣika naa nitori Ọmọworaarẹ ko mọ wọn ri, bẹẹ ni wọn ko ṣiṣẹ fun un rara.
O ni awọn ti fi ọrọ naa to awọn agbofinro leti, bẹẹ si ni gbogbo ẹka to yẹ ko ṣiṣẹ naa ti bẹrẹ iṣẹ, pẹlu idaniloju pe laipẹ yii lọwọ yoo tẹ awọn eeyan naa, ti wọn yoo si fi oju wina ofin.

(28)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.