Wọn ti mu Da-Silva, ogbologboo oniṣowo to n ra foonu tawọn ole ba fibọn gba l’Ekoo

Spread the love

Adefunkẹ Adebiyi

Oṣu kẹta ree tawọn ọlọpaa ti n wa Yusuph Da-Silva nipinlẹ Eko, nitori ogbologboo ni ninu awọn to n ra foonu tawọn ole ba fibọn gba.

Ati foonu ẹni ti wọn pa, ati tawọn ti wọn ṣe leṣe ki wọn too gba a ni Da-Silva n ra, Computer Vilage, n’Ikẹja, lo si n ta wọn si pẹlu awọn ilu oke.

Bi wọn ba n pe ‘Big boy’, iyẹn ọkunrin to ti rọwọ mu nidii iṣẹ to yan laayo, Da-Silva ni wọn ba wi. Nitori o ti di agba ọjẹ ninu foonu ole rira ati tita debii pe awọn adigujale gan-an maa n tọju ẹ fun un pe oun lawọn yoo ta a fun ni. To ba si ti de ni yoo sọ ẹru kalẹ, ni yoo ra awọn foonu olowo nla lowo isọnu lọwọ awọn to fibọn gba wọn, yoo si lọọ ta a fawọn ti wọn ti n duro de oun naa. O kere tan, foonu ọgbọn(30) lo ni oun maa n ta lọsẹ kan, ẹgbẹrun mẹẹẹdọgbọn si ọgbọn Naira lo ni oun maa n ri lọsẹ kan nigba toun ba ta foonu olowo iyebiye naa ni pọọntọ tan.

Yatọ si Computer Village ti Da-silva ti gbajumọ bii iṣana ẹlẹẹta, bẹẹ naa lo tun lẹnu n’Ifakọ Ijaye, nibi ti wọn lo n gbe. Awọn ole  agbebọn to n ba ṣọrẹ ti jẹ kawọn eeyan maa bẹru ẹ, bi wọn si ṣẹ mọ pe ọwọ rẹ ko mọ to, awọn araadugbo ẹ loju ọna reluwee, n’Iju, ko to bẹẹ lati lọọ fẹjọ rẹ sun ni teṣan, nitori wọn ni ti Da–Silva ti wọn tun n pe ni Da-Gold ba fi le mọ, ti ẹni naa ba a niyẹn. Iyẹn ni gbogbo wọn ṣe gba kamu, ti awọn ọlọpaa ko si tete ri i mu.

Bi ọkunrin ti ko ju ọdun mejidinlogbọn lọ yii ba ra foonu ole tan l’Ekoo, o maa n ta awọn mi-in si Kwara, Oṣogbo ati Ọyọ, ki wọn ma baa le wadii wọn sitosi rara.

Awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti mu un ri lori awọn iwakiwa yii, bo ti kuro nibẹ naa lo tun tẹsiwaju. Nigba to kuro nipinlẹ Ogun lo tun sa wa s’Ekoo, niṣe lo si n sa kiri to n fokunkun boju ṣiṣẹ pẹlu awọn eeyan ẹ to pe orukọ wọn ni Abiọdun Tajudeen (Shalori), Drey ati Moshood Akinwande (Ọrọbọ). Ọkada lawọn iyẹn maa gun ti wọn yoo fi da awọn eeyan lọna, ti wọn aa gba foonu wọn.

Awọn mi-in ti wọn jọ n dowo-pọ tun ni AY atawọn ikọ ẹ, awọn kan si tun wa ti wọn n pe ni Idaso Boys, gbogbo wọn ni wọn n fibọn gba foonu ni Fagba, Iju Ishaga, Oke Aro ati agbegbe Ifakọ.

Nigba to n ṣalaye idi to fi di ẹrujẹjẹ saduugbo ati ẹni to n raja ole, Da-Silva loun ti mọ nipa foonu tipẹ, oun maa n ba awọn eeyan tun un ṣe. Nigba ti iyẹn ko mowo gidi wọle loun bẹrẹ si i ra eyi tawọn bọisi ba mu wa si Computer Village.

O ni, ‘ki i ṣe pe mo n jale bẹẹ yẹn naa, nitori mi o ki i tẹlẹ wọn lọọ gba foonu lọwọ ẹnikẹni, ti wọn ba mu un de naa ni mo maa n ra a lọwọ wọn.

‘Mo mọ pe wọn n ja a gba tabi ki wọn fipa gba a lọwọ awọn to ni in ni, ṣugbọn mi o ki i tẹlẹ wọn lọ. Igba to di pe foonu ti mo n tunṣe ko pe mọ, ti mo tun ṣe ‘Yahoo’ ti ko wọọki ni mo bẹrẹ si i ra foonu tawọn bọisi ba ji wa fun mi’

Awọn RRS lo ṣẹṣẹ ri Da-Gold mu l’Ọjọruu to kọja yii, nibi idigunjale kan ti wọn ti fibọn gba foonu, kọmputa alaagbeka atawọn nnkan mi-in n’Ifakọ-Ijaye.

Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Eko, DSP Bala Elkana, lawọn ti fa a fawọn SARS, ki wọn maa fọrọ wa a lẹnu wo lọ titi ti yoo fi de ibi ti yoo ti gbadajọ.

(2)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.