Wọn ti ko awọn to maa n fi hama jale ninu goosilo l’Ekoo lọ si kootu

Spread the love

Awọn afurasi to maa n jale ninu gosiloo meji kan, Akpan Samuel ati Ani Chukwuma, ni ọwọ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti tẹ bayii, wọn ni awọn ni wọn maa n ṣọṣẹ loju ọna Lekki si Ẹpẹ, niluu naa.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Chike Oti, lo sọ eleyii di mimọ lọjọ Aiku, Sannde, ijẹta, ninu atẹjade to fi ṣọwọ si awọn oniroyin.
Oti sọ pe awọn afurasi naa kundun ki wọn maa ji dukia awọn eeyan to wa ninu gosiloo, ọjọ si ti pẹ ti awọn agbofinro ti n dọdẹ wọn.
Gẹgẹ bo ṣe ṣalaye, ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to kọja, ni aṣiri awọn afurasi naa tu, nigba ti awọn ọlọpaa n ṣiṣẹ wọn lọwọ lagbegbe naa. O ni ikọ ti CSP Issa Abdulamajid ti i ṣe ọga ọlọpaa teṣan Marọkọ ko sodi lo mu awọn afurasi yii.
O ni Samuel ati ekeji rẹ ti jẹwọ pe loootọ lawọn huwa ọdaran naa, ati pe ọna ti awọn maa n gba fi ṣiṣẹ ni pe awọn maa n gun ori biriiji Maruwa, to wa lọna Lekki si Ẹpẹ lọ, nibẹ lawọn si ti maa n ṣọ ẹni ti awọn ba fẹẹ ja lole.
Afurasi naa ni awọn maa n yọ ẹru ninu ọkọ yoowu ko jẹ, bẹẹ awakọ to ba kọ lati yi gilaasi rẹ walẹ fun awọn lẹyin ti awọn ba ni ko ṣe bẹẹ ni awọn maa n fi hama fọ gilaasi ọkọ rẹ, ti awọn aa si mu ohun ti awọn ba fẹẹ mu.
Oti ni awọn ti wọ awọn afurasi yii lọ si kootu Majisreeti to wa ni Igboṣere, iyẹn l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja, adajọ si ti paṣẹ ki awọn fi wọn pamọ si ọgba ẹwọn Ikoyi, niluu naa.

(19)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.