Won ti gbe Damilola to gun oko re pa lo si Panti

Spread the love

Latari bi iyawo ile kan, Damilola Ayeni, se tun gun oko re, Olumide Ayeni lobe pa ni ojo Abameta, Satide ose to koja, komisanna olopaa nipinle Eko, …. ti gba awon toko-tiyawo nimoran lati maa fi suuru yanju aawo to ba wa laarin ara won ti ko fi ni i di wahala, leyii to maa wa ja si pe won n seku pa ara won.

O soro yii latari wahala to sele laarin awon toko-tiawo naa, leyii to mu ki obinrin naa fibinu gun oko re lobe, to si yori si iku fun un,

Gege bi ALAROYE se gbo, ni Satide ose to koja ni isele naa sele nile won to wa ni Opopona Bamigbose, ni Lagos Island.

Esun agbere ni won ni Damilola fi kan oko re, eyi lo si faja laarin won ti obinirn naa fi yo obe, to si gun oko re pa. Baba oko iyawo, Ogbeni Sunday Ayeni lo loo foro naa to aown olopaa leti gege bi alukoro olopaa nipinle Eko, … se so.

Baba naa salaye fawon agbofinro pe ‘’Osibitu ijoba, Island Maternity to wa ni Island ni mo ti n sise ode, omo mi naa si n sise ni eka ti won ti n po oogun to wa nibe. Ni nnkan bii odun meji seyin ni won segbeyawo, sugbon latigba ti won ti fe ara won naa ni aarin won ko ti toro, to je ija lonii, wahala lola ni won maa n ba ara won fa.

‘’Bo tile je pe omo meji ni won ti bi funra won, eleyii ko dawo wahala ti won n bara won fa duro, gbogbo igba ni omo mi si maa wa n fi ejo re sun. Mo ti pe omo mi, iyen Olumide pe ki o fi obinirn naasile ki kaluku won maa lo lotooto. Awon eeyan ni won tun da mi lekun pe ko ye ki n se bee, won ni ko ye ki n maa ba omo mi ko iyawo, ki n ma da si aarin won, ki n fi aown mejeeji sile ki won jo maa yanju aawo to ba wa laarin won. Eyi ni mo fi moju kuro ti mi o da si aarin won mo.

‘’Lojo Eti, Furaidee to koja, leyin ti emi pelu Olumide kuro lenu ise lo lo si ibi apeje kan. O pe iyawo re lori foonu lati so fun un pe oun n lo si ode yii, awon mejeeji si jo soro.

‘’Mo gbo pe nigba to dele pada lale ojo yii, iyawo re ti duro de e lenu ona, ko si je ko wole to fi n fesun kan an pe odo obinrin kan lo lo. Damilola so pe oun gbo ohun obinrin labele lasiko ti oko oun n ba oun soro. Bi won se bere ija niyen,ki aown eeyan si too mo ohun to n sele, nise lo mu obe to gun oko re pa. Ki i se pe won woya ija, omo mi ko ba a ja to fi gun un pa’’

Baba Ayeni to wa lati ipinle Ondo yii so pe ki ijoba gba oun, ki won ma je ki iyawo re fiya yii je oun gbe.

Sugbon oto ni akosile ti Damilola se lodo awon olopaa leyin ti won mu un de tesan won ni Lion Building. Ohun ti omobinrin eni odun metalelogun naa ko sile ni pe oun fi obe naa gba ara oun sile nigba ti oko oun n lu oun ni ko ma baa lu oun pa.

O ni oko oun lo pe oun nirole ojo naa, sugbon oun ko si nibi ti foonu oun wa, eyi ti ko fun oun lanfaani lati gbe ipe naa. Nigba ti oko oun ti ode to lo de ni nnkan bii aago kan oru lo beere pe ibo ni oun wa nigba ti oun n pe oun ti oun ko fi gbe ipe naa. Damilola ni bi Olumide se fi esun agbere kan oun niyen, bee lo fee gun oun lobe, eyi lo mu ki oun naa mu obe ni kisini ti oun fi gun un lobe ni aya lati fi daabo bo ara oun.

Oju es tisele naa sele ni won ti sare gbe omokunrin eni odun merindinlogoji ohun lo sileewosan ijoba to wa ni Island, sugbon ko pe sigba naa lo jade laye.

Eka to n ri si iwa odaran nipinle Eko to wa ni Panti ni won taari obinrin naa lo fun itesiwaju ninu iwadii awon olopaa, bee ni won ni Iya Damilola ti ko aown omo mejeeji ti won bi lo sodo. Omo osu meta pere ni okan ninu won.

Alukoro ileese olopaa nipinle Eko, CSP Chike Otti fidi isele naa mule. Bee ni Komisanna olopaa gba awon toko-tiyawo nimoran lati maa na suuru si ede aiyede to ba wa laarin won ti oro naa ko fi ni i maa ja si pe won n lu ara won tabi gun ara won pa.

(49)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.