Wọn ti da Ẹkun ti wọn pe ni baba isalẹ awọn ajinigbe l’Akurẹ pada sọgba ẹwọn

Spread the love

Adajọ ile-ẹjọ Majisreeti kan to wa l’Oke-Ẹda, l’Akurẹ, ti ni ki wọn ṣi fi Kayọde Ajayi, ẹni ti ọpọ eeyan mọ si Ẹkun pẹlu awọn ẹmẹwa rẹ meji mi-in, Olumide Falẹyẹ ati Bọla Ojo, pamọ sọgba ẹwọn lori ẹsun ijinigbe.

 

Falẹyẹ ati Bọla to jẹ iyawo Ẹkun lọwọ kọkọ tẹ ni nnkan bii aago mẹsan-an aarọ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja lọhun-un, lasiko ti wọn n gbiyanju ati ji ọmọbinrin kan, Ayọmide Ogunsuyi, gbe.

 

Lasiko ti wọn n fọrọ wa awọn tọwọ tẹ naa lẹnu wo ni teṣan ni wọn jẹwọ, ti wọn si darukọ Ẹkun gẹgẹ bii ẹni to ran wọn niṣẹ.

 

Aarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja yii lawọn afurasi mẹtẹẹta ọhun foju balẹ-ẹjọ, ẹẹmeji ọtọọtọ ni wọn si pe wọn wa siwaju lati waa jẹjọ lọjọ naa.

 

Ẹsun mẹta to duro lori igbimọ-pọ ji ni gbe, ijinigbe  ati ṣiṣẹ iranwọ fun awọn ajinigbe lo wa ninu iwe ẹsun akọkọ.

 

Wọn fẹsun kan Ẹkun atawọn meji yooku pe wọn ji ẹni ọdun metalelogun naa gbe lagbegbe Isinkan, l’Akurẹ, laaarọ ọjọ naa, ti wọn si fi dandan le e fun un lati sanwo itanran ki wọn too tu u silẹ.

 

Ẹsun akọkọ ti wọn fi kan wọn ni Agbefọba Uloh Goodluck sọ pe o tako abala ofin okoolelẹẹdẹgbẹta-o-din-mẹrin (516) ninu iwe ofin ipinlẹ Ondo, tọdun 2006.

 

Ẹsun keji ati ẹkẹta ni Uloh tun juwe bii eyi to lodi labẹ abala ofin kẹta ati ikarun-un ninu akanṣe iwe ofin ipinlẹ Ondo tọdun 2010, eyi to tako ijinigbe.

 

Ẹbẹ mi-in to tun fi siwaju ile-ẹjọ ni pe ki adajọ paṣẹ ki awọn afurasi ọhun ṣi wa ninu ọgba ẹwọn Olokuta  titi imọran yoo fi wa lati ọdọ ajọ to n gba adajọ nimọran.

 

Morakinyọ Ogele to jẹ agbẹjọro awọn olujẹjọ tako ẹbẹ ti Uloh fi siwaju adajọ pẹlu bo ṣe fẹsun kan awọn ọlọpaa pe aago mẹwaa alẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ni wọn ṣẹṣẹ waa fun oun niwee ipẹjọ, dipo aarin aago mẹjọ aarọ si mẹfa alẹ ti ofin sọ.

 

Ogele ni ki adajọ da ẹbẹ agbefọba naa nu, ko si paṣẹ fun un pe ko lọọ tun iwe ipẹjọ mi-in, eyi to gbọdọ tẹ oun lọwọ laarin akoko ti ofin fọwọ si ṣe.

 

Bakan naa ni amofin ọhun tun rọ adajọ pe ko paṣẹ fawọn ọlọpaa lati gbe Ẹkun pada sileewosan awọn ọlọpaa, nibi to wa tẹlẹ ki wọn too gbe e wa sile-ẹjọ, dipo ọgba ẹwọn ti agbefọba fẹ ki wọn gbe e lọ.

 

Adajọ C. Adeyanju fagi le ẹbẹ ti agbefọba fi siwaju ile-ẹjọ, o ni awọn ọlọpaa kọ lati tẹle ohun ti ofin sọ lori ọna ti wọn gba fun agbẹjọro awọn olujẹjọ niwee ipẹjọ.

 

Leyin eyi lo paṣẹ pe ki wọn ṣi lọ fi awọn olujẹjọ naa pamọ sọgba ẹwọn Olokuta titi di ọjọ kẹrinla, oṣu ta a wa yii, o ni awọn alaṣẹ ọgba ẹwọn ko figba kan sọ pe awọn ko ni i le tọju Ẹkun to ba wa lọdọ awọn.

 

 

 

(0)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.