Wọn tẹẹyan pa lasiko abẹwo Atiku si Ọwa Ijẹṣa

Spread the love

Bo tilẹ jẹ pe ọpọ eeyan lo mọ pe ko le ṣe ki idarudapọ ma waye lọjọ Mọnde ti oludije sipo aarẹ Naijiria lorukọ ẹgbẹ PDP, Atiku Abubakar, atiyawo ẹ to jẹ ọmọ Ileṣa, Titi Atiku, lọọ ṣe abẹwo si Ọwa Ọbọkun Ileṣa, Ọba Gabriel Aromọlaran, sibẹ, iku ọdọmọkunrin kan ti awọn eeyan tẹ pa mọ aafin ọba naa ko ṣai ya ọpọ eeyan lẹnu.

Ninu iwadii Alaroye, ohun ti a ri gbọ ni pe awọn ọdọmọkunrin kan ni wọn fi apo ṣakaṣaka ko ẹgbẹrun Naira wa lasiko ti ọkunrin oniṣowo ati iyawo rẹ yii waa ṣabẹwo si ọba ilu iṣẹmbaye yii, ti wọn si n pin in fawọn eeyan to waa ki oloṣelu yii ati iyawo rẹ. Nibi ti awọn eeyan ti n ṣe girigiri lati gba ẹgberun kan Naira yii ni wọn ti ti ọkunrin yii ṣubu, ti awọn eeyan si tẹ ẹ mọlẹ pa mọbẹ.

Ṣaaju ọjọ yii, iyẹn lọjọ Satide, ni Ọba Aromọlaran ti ba awọn ọdọ adugbo naa sọrọ nibi ayẹyẹ ‘Uyi Arere’ pe ki wọn ma lọwọ si iwa madaru kankan lati da oju eto idibo aarẹ to n bọ lọna yii ru, ki wọn dibo yan ẹni ti wọn gbagbọ pe yoo mu igbega wọ ipinlẹ wọn ni. Bẹẹ ni Ọba Gabriel ṣeleri pe ki ọdun yii too kolẹ, ileewe yunifasiti yoo ti balẹ si ilu Ileṣa.

 

(1)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.