Wọn ni Sardauna fẹẹ ko ibọn fun Akintọla, nija awọn oloṣelu West ba tun le koko si i

Spread the love

Ni Western Region, iyẹn ni ilẹ Yoruba, lati idaji ọdun 1964, ọrọ bii ogun bii ogun, ọrọ bii ija bii ija, ko tan nibẹ titi wọ ọdun 1966. Awọn oloṣelu lo n jagun naa, awọn ni wọn n ja ija naa, awọn ati awọn tọọgi wọn. Bi ẹgbẹ oṣelu ti oloṣelu kan ba wa ba ṣe lagbara to ni oun naa yoo fi lagbara to. Bi oloṣelu kan ba si ṣe lagbara to ni yoo fi ni tọọgi to nigba naa, eyi lo si ṣe jẹ pe awọn tọọgi to pọ julọ, awọn oloṣelu ẹgbẹ Dẹmọ lo ni wọn. Ko si ibi ti ọmọ ẹgbẹ Dẹmọ kan yoo ti pade ọmọ ẹgbẹ Ọlọpẹ, iyẹn Action Group, tabi ẹgbẹ NCNC, iyẹn ẹgbẹ Alakukọ ti wahala ko ni i ṣẹlẹ, wọn yoo maa ja ija naa bii ko ja si iku ni. Ada ki i wọn lọwọ wọn, bẹẹ ni aake ki i wọn lọwọ wọn, ọpọlọpọ wọn lo si gboju le oogun, oriṣiiriṣii awọn oogun buruku ni wọn si n ko kiri. Ẹni to ba pade ẹlomi-in ninu awọn tọọgi yii, bii ẹni to pade ẹbọra ni.

Ọrọ naa ti le debii pe apa awọn ọlọpaa ti wọn wa n’Ibadan ko ka a mọ, iyẹn nijọba apapọ si ṣe ko ọlọpaa irinwo wọ ilu naa lẹẹkan, wọn ni ki wọn lọọ kun awọn ti wọn wa nibẹ lọwọ. Awọn ọlọpaa yii ṣiṣẹ wọn bii iṣẹ nibẹrẹ, nitori lati ọdọ ijọba apapọ ni wọn ti wa, Tafawa Balewa ti i ṣe olori ijọba Naijiria si ti ni ki wọn ṣe iṣẹ wọn bii iṣẹ. Eleyii ko dun mọ Ladoke Akintọla ti i ṣe olori ijọba West ninu, ṣe oun ni olori ẹgbẹ Dẹmọ, o si mọ pe bi awọn tọọgi ẹgbẹ naa ba ti le ko ijaya ba awọn araalu to ni wọn yoo fi dibo fun ẹgbẹ awọn, ti wọn yoo si jinna si ẹgbẹ NCNC tabi AG. Awọn ọlọpaa ti wọn lo nigba naa, ọlọpaa ibilẹ ni wọn, aṣẹ ti ẹni to ba si wa ni ipo ba pa fun wọn ni wọn n tẹle, iṣẹ Akintọla atẹgbẹ Dẹmọ ni pupọ ninu wọn n ṣe. Iyẹn lo fa a to fi jẹ nibi yoowu ti ija ba ti ṣẹlẹ, yoo ṣoro ki tọọgi ẹgbẹ Dẹmọ too sun sẹẹli.

Ko pẹ rara ti ọrọ awọn tọọgi yii fi dija laarin awọn ọlọpaa tuntun yii ati awọn aṣaaju ẹgbẹ Dẹmọ, wọn ni wọn n fiya jẹ awọn ọmọ ẹgbẹ Dẹmọ, wọn si n gbe lẹyin awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu to ku. Wọn ni ijọba Balewa lo ran wọn lati waa fi iya jẹ awọn ọmọ ẹgbẹ awọn. Wọn ko pe wọn ni tọọgi ati onijangbọn, wọn ni ọmọ ẹgbẹ Dẹmọ ni wọn n ṣe. Ki lo si faja naa ni pe nigba ti awọn ọlọpaa ba ko awọn tọọgi yii, wọn maa n ri i pe awọn ọmọ ẹgbẹ Dẹmọ lo maa n pọ ju, awọn ni wọn maa n ṣaya gbangba, ti wọn maa n duro de ọlọpaa, wọn aa ni ko sohun tọlọpaa yoo ṣe fawọn. Bo ba jẹ awọn ọlọpaa ti atijọ ni, ko sohun ti wọn yoo fi wọn ṣe loootọ, ṣugbọn ti awọn ọlọpaa tuntun yii ko ri bẹẹ, nibi yoowu ti wọn ba ti ba tọọgi, boya ọmọ ẹgbẹ Dẹmọ ni tabi ọmọ ẹgbẹ oṣelu to ku, awọn n ko wọn lọ ni, itimọle si ni taara.

Lọjọ kan ni ija naa de gbangba. Laarin Richard Akinjide ati awọn ọlọpaa Ibadan ni. Ko si sohun to fa a ju pe awọn ọlọpaa naa mu awọn tọọgi ẹgbẹ Dẹmọ lọ. Nigba ti wọn mu wọn, wọn ti wọn mọle, Akinjide si sare lọ sibẹ lati gba beeli wọn, nitori bi wọn ti maa n ṣe ree ti wọn ba ti mu awọn tọọgi naa. Ṣugbọn awọn ọlọpaa ko fun wọn ni beeli, wọn ni wọn yoo de ile-ẹjọ dandan, nitori aṣẹ ti awọn gba ki awọn too wa s’Ibadan ree, ẹni ti wọn ba ti mu pe o n ṣe tọọgi, ki wọn mu un de ile-ẹjọ kẹlẹlẹ. Akinjide ni oun ko gba, ko si ohun to fi wọn han bii tọọgi, nitori ọmọ ẹgbẹ NNDP, ọmọ ẹgbẹ Dẹmọ, lasan ni wọn, wọn ko si ni ẹṣẹ meji ti wọn ṣẹ ju pe wọn n ṣe ẹgbẹ Dẹmọ lọ. Akinjide ni ko sofin kan to sọ pe ki eeyan ma ṣe ẹgbẹ oṣelu to wu u ni Naijiria tabi ni West, awọn ọlọpaa ko si le tori iyẹn mu un.

Awọn ọlọpaa ni Akinjide ko le tori iyẹn binu sawọn, tabi ko ba awọn ja, nitori iṣẹ tiwọn lawọn n ṣe. Wọn ni ki ọkunrin lọọya naa ma daamu ara rẹ rara, bo ba di ọjọ keji, ko pade awọn ni ile-ẹjọ. Wọn ni nile-ẹjọ ni ko ti ṣalaye ọrọ naa pe awọn ti awọn mu ki i ṣe tọọgi, ọmọ ẹgbẹ awọn ni wọn, bo ba ti sọ bẹẹ fadajọ, ti wọn si ni ki awọn eeyan naa maa lọ, ko si ohun ti ọlọpaa yoo ṣe. Wọn ni awọn lawọn mọ ohun ti awọn ri ti awọn fi sọ pe tọọgi lawọn eeyan naa, awọn ko si ṣetan lati fi ohun ti awọn ri naa han Akinjide, nigba ti awọn ba de kootu, awọn yoo ko awọn ẹri tawọn kalẹ ati idi ti awọn fi pe wọn ni tọọgi, ti oun naa ba si dọhun-un, ko ko awọn ẹri tirẹ naa kalẹ, adajọ ni yoo ba awọn da a. Wọn ni polis-teṣan kọ ni ile lọọya, wọn ni ile-ẹjọ ni, ki Akinjide pade awọn nibẹ. Ọrọ ti Akinjide gbọ ree to fi binu jade.

Lọjọ keji ni wọn pade nile-ẹjọ loootọ, awọn ọlọpaa si ko awọn mẹtala ti wọn mu naa lọ sibẹ, iwaju adajọ Oluyinka Odumosu ni, ile-ẹjọ Majisreeti to si ga ju niluu Ibadan ni wọn gbe ẹjọ naa lọ. Ki wọn too ko awọn ọdaran naa de ni Akinjide ti i ṣe lọọya wọn ti de, nigba ti wọn si ko wọn de lọkunrin lọọya ilu Ibadan naa ti pade wọn, to si ti fi wọn lọkan balẹ pe wọn yoo jade lọjọ naa, ki wọn ma da awọn ọlọpaa lohun jare. Nigba ti wọn ko wọn dewaju adajọ, Akinjide ko jẹ ki ọrọ naa balẹ to fi bẹrẹ alaye, o ni awọn ọmọ ẹgbẹ Dẹmọ ti wọn n ṣepade wọn jẹẹjẹ lawọn ọlọpaa lọọ ka mọ ibi kan, ti wọn si ko wọn, ti wọn wa n purọ mọ wọn pe wọn fẹẹ da ija silẹ ni. O ni awọn ti wọn ko yii ki i ṣe tọọgi, ọmọ ẹgbẹ lasan ni wọn, ko si si ohun to n bi awọn ti wọn ko wọn ninu ju pe wọn n binu ẹgbẹ Dẹmọ lọ.

Nigba naa lawọn ọlọpaa too sọ ohun ti wọn tori ẹ mu wọn, wọn ni tọọgi ni wọn, tọọgi gidi. Wọn ni nigba ti awọn mu awọn mẹtala naa, ko si ẹni ti ko ni ada lọwọ ninu wọn, awon mi-in si ni ada meji ti wọn tọju si abẹ aṣọ wọn, bẹẹ ni wọn to oogun buruku mọra. Wọn ni ibi ti awọn ti ba wọn ko dara, nitori wọn n mura ija lọwọ lawọn ko wọn, ko si si tabi-ṣugbọn nibẹ, aburu niwọn fẹẹ ṣe. Ki i ṣe pe awọn ọlọpaa deede sọ ọrọ naa lẹnu, nigba ti wọn si bẹrẹ si i ko awọn irinṣẹ eṣu ti wọn ba lọwọ awọn ọdaran naa jade, adajọ paapaa pariwo ni. Awọn eeyan naa ko sọ pe tọọgi lawọn, wọn ko si sọ pe awọn ki i ṣe tọọgi, wọn ni awọn ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan awọn ni. N l’Akinjide ba dide, o ni ẹsun naa ko fẹsẹ mulẹ, nitori o ṣee ṣe ko jẹ ada ti wọn ba lọwọ wọn ti wọn n sọ yii, wọn n lọ si oko wọn lẹyin ti wọn ba pari ipade ti wọn n ṣe ni.

O ni nitori bẹẹ, ko sohun ti adajọ yoo ṣe ju ko fawọn eeyan awọn silẹ lọ, ko jẹ ki oun gba beeli wọn, ki wọn le maa lọ sile, ọjọkọjọ ti wọn ba si fi igbẹjọ si, awọn yoo pada wa sile-ẹjọ lati sọ tẹnu awọn. Nigba naa ni ọlọpaa to ko wọn wa, iyẹn olupẹjọ fo dide, o ni ko ṣee ṣe, pe wọn o le gba beeli awọn eeyan naa, nitori bi wọn ba gba beeli wọn ti wọn tun bẹrẹ si i rin kaakiri igboro, ọran nla ni wọn yoo maa da, nitori o ti han pe tọọgi ti ko niṣẹ meji ni wọn, wọn yoo kan maa da wahala silẹ nigboro ni. Ọlọpaa olupẹjọ yii ni awọn oloṣelu lo n lo wọn, awọn ni wọn jẹ baba isalẹ fun wọn, o si daju pe ti wọn ba fi wọn silẹ, awọn oloṣelu yii yoo rin si ọrọ wọn, wọn yoo si ri i pe wọn ṣe ẹjọ naa raurau ni. O ni awọn mi-in le sa lọ patapata ninu wọn ti awọn ko ni i ri wọn mọ, ẹjọ naa yoo si daru ni.

Ọlọpaa yii ni ṣugbọn o, bi awọn eeyan naa ba wa nitimọle, awọn yoo maa ri wọn ni gbogbo igba ti awọn yoo fi ṣẹjọ naa tan, nigba ti adajọ ba si dajọ wọn, wọn yoo maa gba ile wọn lọ, tabi ki wọn ko wọn lọ si ibi ti adajọ ba ni ki wọn lọ. Nibi ti ija naa ti le ree, nitori niṣe ni Akinjide fo dide ni kootu, o ni ki wọn maa gbọ ohun ti ọlọpaa kekere yii n sọ. O ni ki ọlọpaa naa duro bẹẹ, ko dakẹ jẹẹ, o ni ko lọọ sọ fun ọga rẹ pe iṣẹ ti awọn ẹgbẹ alatako ran an to n jẹ yẹn, ẹtẹ ni yoo gbẹyin rẹ fun un. Akinjide ni ki ọkunrin ọlọpaa yii lọọ sọ fun awọn ọga to ran an niṣẹ pe ti wọn ba fẹẹ ṣe oṣelu, ki wọn lọọ bọ kaki ọrun wọn silẹ, ki wọn si jade waa ṣe oṣelu, ki awọn jọ maa ṣe e. Ṣugbọn ki wọn wa ninu iṣẹ ọlọpaa, ki wọn ko aṣọ ọlọpaa sọrun, ki wọn maa ṣiṣẹ fun ẹgbẹ alatako, iyẹn lawọn o ni i gba, ko ni i ṣee ṣe rara.

Ohun ti Akinjide n sọ ni pe awọn ẹgbẹ alatako ni wọn ran awọn eeyan naa niṣẹ ti wọn waa jẹ, awọn ni wọn n lo awọn ọlọpaa yii. Iyẹn ni pe ẹgbẹ Ọlọpẹ, AG ati ẹgbẹ NCNC lawọn ọlọpaa naa n ṣiṣẹ fun, wọn ko ṣiṣẹ fun ẹgbẹ Dẹmọ, wọn kan wa lati ba ẹgbẹ Dẹmọ jẹ ni. Iyẹn l’Adajọ Ọlayinka Odumosu ṣe da a lohun, o ni ki Ọgbẹni Akinjide ṣe suuru ko jẹ ki oun ba ọlọpaa naa sọrọ, ẹyin naa lo si kọju si ọlọpaa yii pe ko too sọrọ bẹẹ, ko kọkọ lọọ gba aṣẹ lọwọ olupẹjọ agba fun ijọba, ohun ti iyẹn ba sọ lawọn yoo tẹle. O ni bi olupẹjọ agba ba ni ki awọn ma gba beeli wọn, awọn ko ni i gba a, ṣugbọn ki i ṣe ki ọlọpaa to mu wọn naa lo maa sọ pe awọn ko gbọdọ gba beeli wọn. Ọna ti awọn Akinjide fẹẹ gba ree, wọn ti mọ pe bi ẹjọ naa ba ti kuro lọwọ ọlọpaa, to di ti ijọba West, ohun ti awọn ba fẹ ni ẹni naa yoo ṣe, nitori abẹ ijọba tiwọn lo ti n ṣiṣẹ.

****Wọn pada waa gba beeli awọn eeyan naa nitori oṣiṣẹ ijọba to n pe ẹjọ fun ijọba West sọ pe ki wọn gba beeli wọn, igba naa ni ija laarin awọn ọlọpaa tuntun yii ati Akinjide si gbona si i. Awọn oloṣelu West ko tete mọ ọna ti wọn yoo gba, nitori ko si ohun ti wọn yoo ṣe lai lo tọọgi, awọn tọọgi lo n ba wọn ja ija wọn, bi wọn ba si ti ja ija naa tan ni wọn yoo pada wa si ọdọ awọn ọlọpaa, ọlọpaa yoo si fi wọn silẹ nitori agbara to wa lọwọ wọn. Amọ o jọ pe nnkan naa fẹẹ yipada bayii, nitori awọn ọlọpaa tuntun ti Balewa ko ranṣẹ si wọn. Awọn ọlọpaa yii ko woju awọn ọga oloṣelu West ti wọn wa nijọba, wọn mọ pe ẹgbẹ Dẹmọ lo ni wahala to pọ julọ, awọn si ni agbara wa lọwọ wọn, iyẹn lo ṣe jẹ awọn lawọn ọlọpaa yii doju ija wọn kọ, awọn ni wọn ni wọn n daamu ju, awọn oloṣelu yii si n binu gidigidi.

Nigba naa ni Akintọla ba Sardauna sọrọ, o si sọ fun un pe awọn ọlọpaa ti Balewa ko wa si Ibadan ko jẹ ki awọn ọmọ ẹgbẹ awọn gbadun mọ, bi nnkan ba si n lọ bo ṣe n lọ yii, ibo ti wọn fẹẹ di ninu ọdun naa yoo ṣoro, nitori ẹgbẹ awọn ko ni i wọle. Sardauna ni ko si wahala, awọn n wa ọna ti awọn yoo fi yanju ọrọ naa, ati pe nigbẹyin, ẹgbẹ wọn naa ni yoo bori. Ohun ti awọn eeyan ko mọ nigba naa ni pe Sardauna ti lọ si Saudi Arabia, o si rin awọn irin kan ti awọn eeyan ti wọn wa nile ko mọ, afi nigba ti ẹronpileeni kan de lojiji, to si ko awọn ibọn ati awọn ohun ija oloro gidi wa. Ko sẹni to mọ igba ti ẹronpileeni naa de, ko si sẹni to mọ ẹni to gbe e wa. Bẹẹ Naijiria ko ti i tobi to bayii nigba naa, bi ẹronpileeni kan ba balẹ nilẹ yii ni ọdun 1964, ko si ibi to balẹ si ti awọn eeyan ko ni i sọ pe awọn ri ẹronpileeni tuntun.

Awọn eeyan ri ẹronpileeni naa ni Kaduna, ko si pẹ ti iroyin fi jade pe awọn ohun ija oloro ni ẹronpileeni naa ko wa, ọdọ Sardauna Ahmadu Bello lo si ko awọn ohun ija naa lọ. O da bii pe awọn eeyan ko gbọ iru rẹ ri ni. Idi ni pe ko si ẹni kan to gbọdọ ṣe iru rẹ, ko si ẹni to gbọdọ ko awọn ohun ija kankan wọlu, ko si olori ijọba ipinlẹ kan to gbọdọ ṣe bẹẹ labẹ ofin, afi ijọba apapọ nikan. Ohun to si jẹ ki ọrọ naa di ariwo niyẹn. Ọgbẹni R.B. Okafor to jẹ akọwe fun minisita eto idajọ lo kọkọ pariwo ọrọ naa sita, to ni awọn eeyan kan ko ohun ija oloro wọlu yii o, ati pe Kaduna ni wọn ko awọn ohun ija naa si, ẹni kan ko si mọ ibi to wọlẹ si o. Ọrọ naa lawọn oloṣelu gbọ, ti wọn ni Sardauna lo ko o wọlu, o fẹẹ ko o fun awọn tọọgi ẹgbẹ oṣelu tirẹ, iyẹn NPC, ki wọn le maa fi ṣejamba fawọn oloṣelu ti ko ba fẹ tirẹ nilẹ Hausa ni.

Awọn eeyan kan kọkọ n sọrọ, ohun ti wọn n wi ni pe Sardauna ko mọ kinni kan nipa rẹ, wọn ni loootọ lo lọ si Saudi Arabia, ki i ṣe lati ra awọn ohun ija oloro ni. Sardauna funra ẹ lo waa fi aṣiri ọrọ naa han, nitori o sọ fawọn oniroyin pe loootọ ni ẹronpileeni kan balẹ si Kaduna to ko awọn ohun ija oloro wọle, ṣugbọn oun ko mọ ibi ti ẹronpileeni naa ti n bọ, tabi ohun ija oloro to ko wọlu, oun ko si mọ ibi to ko kinni naa lọ. O ni nigba ti oun gbọ ọrọ ẹronpileeni naa, oun pe Balewa ti i ṣe olori ijọba, oun si sọ fun un pe ẹronpileeni kan de o, ohun ija oloro lo ko wa. Lẹyin naa, oun ko mọ ohun ti wọn tun ṣe si i. Awọn eeyan ko gba Sardauna gbọ, nitori wọn mọ pe ko sọ ootọ rara. Bawo ni ẹronpileeni yoo ṣe ko ohun ija oloro wọlu lati ilẹ Larubawa, nigba to jẹ oun naa ṣẹṣẹ ti ibẹ de ni, ti yoo waa sọ pe oun ko mọ bi awọn ibọn ati ọta ibọn naa ti ṣe jẹ.

Ṣugbọn sẹnkẹn ni inu awọn oloṣelu ilẹ Yoruba n dun si ọrọ yii, wọn ni ko si ohun kan ti Balewa le ṣe mọ, aṣẹ ti Sardauna ba pa fun un ni yoo tẹle, Akintọla si ni ọrẹ Sardauna, ohun ti Akintọla ba fẹ, Sardauna yoo ṣe e fun un. Awọn oloṣelu NCNC pariwo, wọn ni ohun ija oloro ti Sardauna ko wọlu yii, o ti ṣeleri rẹ fun Akintọla pe oun yoo ko pupọ fun un lati fi jagun oṣelu to ba ṣẹlẹ nilẹ Yoruba, iyẹn ni Akintọla si ṣe n ṣeleri pe bi awọn ọlọpaa ko ba le daabo bo awọn, awọn yoo daabo bo ara awọn. Ọrọ naa dija, koda o di awuyewuye nla, nitori Akintọla ko sọ pe irọ ni wọn pa mọ oun tabi ootọ, awọn eeyan kan mọ pe bo ti n lọ si Kaduna lo n bọ, to n paara ọdọ Sardauna bii ẹni to n lọ si oko etile.

Awọn oloṣelu AG ati NCNC ko si ro ọrọ naa lẹẹmeji ti wọn fi n pariwo pe Akintọla ti n lọọ gba ibọn ati ohun ija lọwọ Sardauna, o fẹẹ fi pa awọn ẹgbẹ alatako ti ko ba ṣe tirẹ ni o! Ko si pẹ loootọ ni ija bẹrẹ si i le ni West, ti ọrọ oṣelu wọn nibẹ si tun bẹyin yọ.

 

 

 

 

(13)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.