Wọn ni nitori wahala to ṣẹlẹ nibi ipolongo ẹgbẹ APC ni wọn fi gbe ọga ọlọpaa Eko kuro

Spread the love

Irọlẹ ijẹta, Sannde, ni iroyin naa jade pe ileeṣẹ ọlọpaa ti gbe Kọmisanna ọlọpaa nipinlẹ Eko, Imohimi Edgal, kuro, wọn si ti fi Kayọde Ẹgbẹtokun rọpo rẹ, gẹgẹ bi ẹni ti yoo fidi-hẹ ipo naa fungba diẹ.

Olu-ileeṣẹ ọlọpaa to wa niluu Abuja, iyẹn lẹka to n ri si ado oloro ni wọn gbe Edgal lọ.

Bo tilẹ jẹ pe Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Chike Oti, ko ti i fi atẹjade sita lori eyi, ṣugbọn awọn eeyan kan ti n sọ pe nitori wahala to ṣẹlẹ nibi ipolongo idibo ẹgbẹ oṣelu APC lọsẹ to kọja, nibi ti wọn ti gun Musiliu Akinsanya, ẹni ti wọn tun n pe ni MC Oluọmọ, lọbẹ, lo fa wahala si Edgal lọrun. Ṣe lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ to kọja ni awọn kan da ipolongo ibo ẹgbẹ oṣelu APC ti wọn ṣe Sky Power Ground, Ikẹja, niluu Eko ru, ti awọn oniroyin kan naa si fara gbọbẹ.

Niṣe ni iro ibọn n dun lakọlakọ lọjọ naa lasiko ti Gomina Akinwumi Ambọde n sọrọ lọwọ, kọrọ kan ni awọn ẹṣọ alaabo si mu gomina naa gba jade nibi ifilọlẹ ọhun, pẹlu awọn eeyan pataki mi-in.

Lọwọlọwọ bayii, MC Oluọmọ n gba itọju lọwọ lọsibitu, ti ileeṣẹ ọlọpaa ninu atẹjade ti Alukoro wọn, Chike Oti, fi ṣọwọ si awọn oniroyin fidi ẹ mulẹ pe awọn n wa Mustapha Adekunle ti inagijẹ rẹ n jẹ Seigo, wọn loun lo da wahala naa silẹ.

 

 

(2)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.