Wọn ni igbega ti Gomina Ahmed ṣe fawọn ọba Kwara lowo oselu ninu

Spread the love

Lẹyin ifidi-rẹmi ẹgbẹ PDP ninu atundi ibo, Gomina Abdulfatah Ahmed ti ṣe igbega fawọn ọba mẹtadinlogun lẹkun idibo Guusu Kwara si ipo ipele keji.

Ṣugbọn awọn kan ni oṣelu pọnbele ni gomina naa n dọgbọn ṣe. Idi ni pe lati ọdun 2014 nijọba rẹ ti kede pe oun ṣe igbega fawọn ọba alaye kan ni Guusu Kwara, ṣugbọn ẹnu lasan ni wọn fi sọ ọ, wọn ko mu un ṣẹ.

Ijọba ko gbe ọpa aṣẹ fun wọn debii pe o maa fun wọn ni iwe-ẹri iyansipo wọn latigba naa.

Ṣugbọn iyalẹnu lo waa jẹ pe lẹyin ọsẹ kan ti atundi ibo waye nijọba ibilẹ mẹrin ni Guusu Kwara, ti ẹgbẹ PDP si fidi-rẹmi nijọba sare bẹrẹ si i fun awọn ọba ni iwe-ẹri igbega lẹkun naa.

Ibeere tawọn eeyan n beere ni pe ki lo de to jẹ pe nigba to ku oṣu mẹfa ti ijọba Ahmed yoo kogba sile ni wọn ṣẹṣẹ sare ṣe igbega fawọn ọba.

Lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii nijọba fun awọn ọba mejilelọgbọn mi-in ti wọn wa nipele kẹrin tẹlẹ ni iwe iyansipo wọn.

Kọmiṣanna to n mojuto ijọba Ibilẹ, ọrọ Oye ati Idagbasoke awujọ, Alhaji Saidu Habeeb ke si awọn ọba naa lati dari awọn araalu wọn lati maa gbe ninu irẹpọ fun idagbasoke awujọ.

Onipẹẹ tilu Ipẹẹ, nijọba ibilẹ Ọyun, Ọba Mufutau Adebayọ Lawal, Titiloye III, to gbẹnusọ fawọn ọba mẹtadinlogun naa dupẹ lọwọ ijọba, o si ṣeleri pe awọn yoo maa ṣe atilẹyin fun eto ijọba ni gbogbo igba.

Lara awọn ọba to gba iwe iyansipo wọn ni: Onijagbo tilu Ijagbo, Ọba Salaudeen Ọlagunju Adeyẹye Fagbemi Obebe, Olukọtun tilu Ikọtun, Ọba AbdulRasaq Adebayọ, Olojoku ti Ojoku, Alaran tilu Arandun, Elesiẹ tilu Esiẹ ati Oludọfian ti Idọfian.

 

 

 

(18)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.