Won ni Busayo fi oko pa akekoo marun-un l’Ede ti muti yo ni

Spread the love

Ipele to kẹyin ni ẹka awọn ti wọn n kọle (building department) nileewe gbogboniṣe tijọba apapọ to wa niluu Ẹdẹ la gbọ pe Busayọ Ọlọrunfẹmi, ẹni ti inagijẹ rẹ n jẹ Ẹja wa, ṣugbọn gbogbo awọn akẹkọọ ni wọn mọ oun pẹlu awọn ọrẹ rẹ gẹgẹ bii ọmọ yahoo-yahoo.

Ibi faaji la gbọ pe oun atawọn ọrẹ rẹ ti n bọ ni nnkan bi aago marun-un irọlẹ ọjọ̣ kẹtadinlọgbọn, oṣu to kọja yii, o  si bọ si asiko ti awọn akẹkọọ ti wọn n gbero lati darapọ mọ ileewe Poli Ẹdẹ pari idanwo Post UTME wọn ni South Campus ileewe naa.

Ere asapajude ti a gbọ pe ọrẹ Busayọ to wa mọto Toyota Camry dudu to ni nọmba AAA 463 DV, ba debi tawọn ọmọ naa ti n fẹsẹ rin lọ lagbegbe Oloki, niluu Ẹdẹ, lo fa wahala naa, o kọkọ kọlu ọmọbinrin ẹni ọdun mejidinlogun kan torukọ rẹ n jẹ Islamat Bello, iyẹn si ku loju ẹsẹ.

Ibẹru ohun tawọn eeyan agbegbe naa le ṣe fun wọn ni wọn ko ṣe duro, ṣugbọn ṣe ni wọn tun n fi mọto ọhun kọlu awọn akẹkọọ si i, ko si too di pe awọn eeyan mọ nnkan to n ṣẹlẹ, marun-un ninu awọn ọmọ naa ti jade laye, awọn mi-in si farapa.

Sibẹ, a gbọ pe Busayọ atawọn ọrẹ rẹ ti wọn jọ wa ninu mọto ko duro titi ti wọn fi sọ ori mọto naa mọ opo-ina kan, bayii ni wọn ko le lọ mọ. Awọn akẹkọọ yii sa jade ninu mọto, wọn si juba ehoro, ṣugbọn ọwọ tẹ Busayọ, ibẹ lawọn tọọgi si sọ ọ lokuta pa si.

Gẹgẹ bi akẹkọọ kan to n gbe lagbegbe tiṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ, ṣugbọn to ni ka forukọ bo oun laṣiiri ṣe sọ fun Alaroye, o lo ku ọjọ mẹta ti Busayọ yoo ṣe aṣeyọri lẹnu ẹkọ rẹ niṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.

O ni ọti amuju ti awọn akẹkọọ ọhun mu lo da wahala naa silẹ, nitori ṣe ni gbogbo ara Busayọ n run fun ọti, bẹẹ ni oorun ọti kun inu mọto naa lasiko tiṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ.

Gẹgẹ bo ṣe wi, “Gbogbo awọn eeyan ni wọn maa n sọ pe Ẹja atawọn ọrẹ rẹ n ṣe yahoo-yahoo latari igbe aye ti wọn maa n gbe ninu ileewe wa, imura wọn ati iwa wọn fi han pe iṣẹ bẹẹ wa lọwọ wọn. Mo fura pe ṣe ni wọn ri owo kan lọjọ naa ti wọn fi lọọ ṣe faaji funra wọn.

“Inu ibẹrubojo ni gbogbo wa wa bayii nitori ṣe lawọn tọọgi ti inu n bi naa n wa awa akẹkọọ kaakiri, awọn ọmọ ọlọmọ ti wọn ṣẹṣẹ fẹẹ wọle sọdọ wa ti wọn kan da ẹmi wọn legbodo lo dun mi ju.”

(37)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.