Wọn ni awọn ọba alaye ni Amosun tun fẹẹ lo lati gbe Akinlade wọle bayii o

Spread the love

Pẹlu bo ṣe jẹ pe gbogbo ipa ni Gomina ipinlẹ Ogun, Ibikunle Amosun, n sa pe Adekunle Akinlade loun yoo gbe ijọba oun fun lọdun to n bọ, to si loun ko faramọ Dapọ Abiọdun ti ẹgbẹ APC gbe ipo naa fun, ikọ to n polongo fun Dapọ naa ko dakẹ, ohun ti wọn n wi lọwọ bayii ni pe Amosun tun ti lọọ so ọrọ naa mọ awọn ọba alaye lẹsẹ, o si ti ni ki wọn lọọ ba Buhari sọrọ nitori Akinlade.
Adari ipolongo ibo fun Dapọ Abiọdun, Ọgbẹni Emmanul Ojo lo fi atẹjade kan sita lọjọ Satide to kọja yii, nibi to ti fidi ẹ mulẹ pe olobo ti ta awọn pe Gomina Ibikunle Amosun ti yan awọn ọba ipinlẹ Ogun meji kan lati lọọ ba Buhari sọrọ l’Abuja, ki wọn yi aarẹ lọkan pada, ki ohun to jẹ ti Dapọ le bọ sọwọ Akinlade.
Olori ẹgbẹ DACO, iyẹn Dapo Abiodun Campaign Organisation naa tẹ siwaju pe awọn ọba meji tawọn gbọ pe gomina lọọ sopanpa pẹlu lati ba Buhari sọrọ ni Alake tilẹ Ẹgba, Ọba Adedọtun Arẹmu Gbadebọ, ati Olu Ilaro, Ọba Kẹhinde Gbadewọle Olugbenle. O ni awọn ọba naa ti wa niluu Eko lasiko toun n kọ atẹjade yii, nibi ti wọn yoo gba tẹkọ leti lọ siluu Abuja lati ba Aarẹ Muhammadu Buhari sọ ọ pe ko fọwọ si Akinlade, ko si kọyin si Dapọ Abiọdun ti igbimọ amuṣẹṣe fọwọ si.
Bi ko ba si nnkan mi-in nibẹ, awọn ikọ ipolongo Dapọ Abiọdun n beere pe ki lo de ti ọrọ ọga awọn fi n ko aisun ba Amosun bayii. To jẹ ko le gbele, ko le gbeta mọ, nitori ki Akinlade le gba ẹtọ to jẹ ti Dapọ mọ ọn lọwọ.
Bakan naa ni wọn sọ pe nnkan ibanujẹ ti yoo ko abuku ba itẹ ori ade ni to ba fi le jẹ loootọ ni awọn ọba yii fẹẹ da Amosun lohun. Atẹjade naa rọ awọn ladelade nilẹ Yoruba abi nibikibi pe ki wọn ma ṣe lọwọ si yiyi irọ pada si otitọ bi gomina ṣe n fẹ. Bẹẹ lo wa nibẹ pe niwọn igba ti Buhari naa ki i ti i ṣe alagabagebe, o daju pe ko ni i ṣe ohun ti Amosun n fẹ.
Ohun ti wọn fi pari atẹjade ọhun ni pe ki gbogbo eeyan pata, atawọn ọmọ ipinlẹ Ogun dakun fi asiko silẹ lati ṣewadii ohun to de ti Amosun fi taku pe afi Akinlade, wọn ni nnkan mi-in wa ninu ọrọ yii to kọja oṣẹlu lasan.

(4)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.