Wọn n tan Saraki, oun naa n tan abẹla

Spread the love

Awọn kan ti bẹrẹ si i tan olori ile-igbimọ aṣofin agba, Bukọla Saraki. Boya oun naa si n tan ara rẹ ni o, ko si ẹni to ti i le sọ.  Ọkunrin naa kede lọsẹ to kọja pe oun naa yoo du ipo aarẹ Naijiria, pe oun ro pe oun ni agbara ati imọ lati le ṣe olori ilẹ yii, oun yoo si yi nnkan pada kia. Nibi ti wọn ti n tan Saraki niyẹn, ti oun naa si ti bẹrẹ si i tan abẹla, ibi ti yoo fi ina abẹla riran de, oun naa lo le sọ. Aṣiṣe kan wa ti Saraki n ṣe, iru aṣiṣe naa si lawọn eeyan ti wọn n ti i bayii n ṣe. Aṣiṣe naa ni pe Saraki yii ro  pe nitori toun lawọn eeyan ṣe n pariwo, o ro pe nitori toun ni wọn ṣe n bu Adams Oshiomhole ati awọn ti wọn n leri pe wọn fẹẹ yọ ọ nile-igbimọ aṣofin. Nibi ti aṣiṣe rẹ wa niyẹn. Gbogbo ariwo ti ọpọlọpọ araalu, awọn onilaakaye ati awọn ọjọgbọn n pa lori ohun to n ṣẹlẹ nile-igbimọ aṣofin, ki i ṣe nitori Saraki. Nitori tirẹ kọ rara. Ohun ti ọpọlọpọ wa ṣe n pariwo ni pe nigba ti wọn ba ba ile-igbimọ aṣofin jẹ, ti Saraki ba lọ, ti Buhari naa ṣejọba rẹ tan to lọ, yoo ṣoro lati tun ile-igbimọ aṣofin naa ṣe pada, iru awọn iwa were ti ijọba to si wa lori oye yii n hu naa ni ẹlomiiran yoo fẹẹ maa hu, eleyii yoo si sọ wa di ẹni yẹyẹ loju gbogbo aye ni. Yatọ si ti pe a oo jẹ ẹni yẹyẹ, eto ijọba oloṣelu, ijọba awa-ara-wa ti wọn n pe ni dẹmokiresi ko ni i fẹsẹ mulẹ ni Naijiria tiwa, kaka bẹẹ, yoo maa bajẹ si i ni. Ki eleyii ma ṣẹlẹ lo jẹ ka maa pariwo pe Buhari ko le paṣẹ ki wọn yọ olori ile-igbimọ aṣofin, bẹẹ ni ko le ṣe ko ma gbọrọ si wọn lẹnu, nitori ohun ti ofin Naijiria sọ niyẹn, ẹni to ba si n ṣejọba ti ko tẹle ofin ti wọn fi yan an, ọta ilu ni, gbogbo onilaakaye lo gbọdọ lodi si i, nitori iru ẹni bẹẹ yoo pada ba ilu tabi orilẹ-ede to ba ti n ṣejọba jẹ ni. Ohun to jẹ kawọn eeyan maa pariwo Buhari, Oshiomhole ati ijọba APC ree, ti wọn si n sọ pe ki wọn fi ile-igbimọ aṣofin lọrun silẹ. Eleyii ko kan Saraki rara, ko tiẹ fibi kankan kan an, ija ti araalu n ja ki i ṣe nitori tiẹ, nitori ile-igbimọ aṣofin ni. Ṣugbọn oun ti ro pe nitori toun ni, o ro pe okiki ati irawọ oun lo bẹrẹ si i tan bẹẹ, ati pe aye n gba toun. Eyi lo ṣe ro pe oun le di aarẹ Naijiria, to si fẹẹ du ipo naa. Ẹni to ba fori jona yoo gboorun ara rẹ, nigba ti Saraki ba bẹrẹ si i beere iku to pa baba rẹ nigba ti ọwọ rẹ ko tẹ eeku ida, afaimọ ko ma ṣe iku to pa baba rẹ lo n beere nni. Ko sẹni ti yoo sọ pe kawọn eeyan dibo fun Saraki tabi ti yoo ni oun ni ko ṣe aarẹ, nigba ti wọn ba ranti bo ṣe ṣe owo Kwara si, ati awọn ile to fowo ijọba ra, ti wọn si ranti  pe laye rẹ, ko ṣiṣẹ kankan yanju ri afi oṣelu yii naa, to si jẹ ninu awọn to lowo ju ni Naijiria lo wa. Ko si ẹni ti yoo dibo fun ẹni ti wọn mọ pe yoo ji owo awọn ko ni. Ki Saraki jokoo jẹẹ, bi wọn ba n tan an, koun naa ma tan ara rẹ o.

 

(58)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.