Wọn mu Idris atawọn ẹgbẹ rẹ fesun idigunjale n’Ifọn

Spread the love

Ọwọ awọn ọlọpaa ipinlẹ Ondo, ti tẹ Ahmed Idris atawọn mẹta mi-in: Sunday Alamboso, Moses Igenegba ati Yakubu Ibrahim, ti wọn fura si gẹgẹ bii adigunjale to n yọ awọn eeyan ilu Ifọn lẹnu.

Nigba to n fidi iṣẹle ọhun mulẹ, Alukoro ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Fẹmi Joseph, sọ pe Idris, to jẹ ọkan ninu awọn adigunjale naa ni ọwọ awọn kọkọ tẹ, oun lo si mu awọn lọ si ibi ti awọn yooku rẹ wa.

Idris to jẹ ọmọ ilu Ajaokuta, nipinlẹ Kogi, ni wọn lo fẹsẹ ara rẹ rin lọọ ba awọn ṣọja kan to wa lagbegbe Ifọn, nijọba ibilẹ Ọsẹ, nipinlẹ Ondo, ni nnkan bii aago mẹta aabọ ọsan ọjọ kẹfa, oṣu to kọja, to si jẹwọ fun wọn pe adigunjale loun, ati pe ọjọ ti pẹ ti oun ati awọn ẹgbẹ oun ti wa lẹnu iṣẹ naa.

Awọn ṣọja naa ko fakoko ṣofo ti wọn fi fa alejo wọn pataki yii le awọn ọlọpaa lọwọ fun iwadii lori alaye to ṣe fun wọn naa.

Nigba ti awọn ọlọpaa n fọrọ wa a lẹnu wo, Idris sọ pe iya oun ti kilọ foun lọpọ igba lati ma jale mọ, ṣugbọn awọn ẹgbẹ oun yooku ko yọnda oun. O ni ṣe ni wọn n halẹ mọ oun pe awọn yoo pa oun ti oun ba fi le ni oun ko ṣe ẹgbẹ mọ. Idunkooko mọ ẹmi ẹni yii ni Idris loun fi lọọ fi ọrọ naa to awọn ṣọja yii leti, ki awọn ọrẹ oun atijọ yii ma baa pa oun. Nigba ti wọn beere orukọ awọn ọrẹ rẹ yii, o ni Sunday, Moses ati Micheal lorukọ wọn.

Lasiko ti awọn ọlọpaa n wa awọn meji to darukọ yii ni ọwọ wọn tun tẹ Yakubu Ibrahim. Yakubu ni wọn sọ pe o n di awọn agbofinro lọwọ lasiko ti wọn n ṣewadii awọn afurasi ti Idris darukọ yii. Ṣa, iwadii ṣi n lọ lọwọ lati ri awọn afurasi yooku mu.

Alukoro fun awọn ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Fẹmi Joseph, ti ni gbogbo awọn afurasi yii ni yoo foju bale-ẹjọ ni kete ti iwadii ba ti pari lori ẹsun ti wọn fi kan wọn.

(7)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.