Won lu Isiaka, ogboloogbo ọmọ ẹgbẹ okunkun pa l’Ondo

Spread the love

Lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja,  ni wọn pa afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun kan, Adelẹyẹ Isiaka, ẹni ti inagijẹ rẹ n jẹ Aje, laduugbo Lover Boy, to wa lopopona Ondo si Akurẹ.

Ẹni ọdun mọkandinlọgbọn ọhun ni wọn ni oun naa ti pa ọpọlọpọ eeyan, bẹẹ ki i ṣe ajoji fun awọn ọlọpaa, ọpọlọpọ igba ni wọn ti gbe e, ti wọn tun fi i silẹ.

Nnkan bii aago meje alẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja ni wọn ni Isiaka lọ si adugbo kan to ti maa n ta igbo, eyi to wa lẹgbẹẹ  gareeji ti wọn ti maa n wọ ọkọ Akurẹ. Ile ọti kan wa lẹgbẹẹ gareeji yii ti ọmọkunrin ti wọn pe ni olori ọmọ ẹgbẹ okunkun Eiye yii ti maa n jaye pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ yooku.

Lọjọ Furaidee ni wọn ni ọkan ninu awọn ọmọ rẹ ṣadeede yinbọn soke nibi to ti n muti lọwọ, eyi to mu ki awọn ti wọn jọ n muti sa asala fun ẹmi wọn.

Lẹyin bii iṣẹju mẹta ni awọn gende mẹrin kan ṣadeede sọkalẹ lori ọkada, ti wọn si bẹrẹ si i yinbọn soke si ibi ti Isiaka jokoo si. Iyalẹnu lo jẹ fun wọn pe gbogbo ibọn ti wọn yin si i ko ran an, niṣe lo n ta a danu.

Lẹyin to ri i pe awọn to n yinbọn naa ko dawọ duro lo fo dide lori ijokoo, to si sare si oju titi, nibi to ti n wa ọkada ti yoo gun, ṣugbọn ko ri. Awọn to n le e bọ ko dẹyin lẹyin rẹ, nitori ṣe ni wọn ko kumọ ati ponpo dani nigba ti wọn ri i pe ibọn ko wọle si i lara, ẹsẹkẹsẹ ni wọn si bẹrẹ si i ko o bo o lẹyin tọwọ wọn tẹ ẹ tan.

Ori lilu yii ni ẹmi Isiaka bọ si, koda, wọn fọ ọmọkunrin yii lori. Lẹyin eyi ni awọn eeyan wọnyi ta le ọkada wọn, ti wọn si tun bẹrẹ si i yinbọn soke bi wọn ṣe n lọ. O fẹrẹ to ogun iṣẹju lẹyin iṣẹlẹ naa ki awọn eeyan too le jade sita waa wo oku rẹ.

Ọgbọn iṣẹju lẹyin ti iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ ni awọn ọlọpaa de waa gbe oku Isiaka, mọṣuari ijọba to wa niluu Ondo ni wọn si gbe e lọ.

Ọga ọlọpaa kan to wa laduugbo Yaba, niluu Ondo, to ni ka forukọ bo oun laṣiiri sọ fun ALAROYE pe iku Isiaka da bii ẹni pe awọn eeyan naa waa gbẹsan ni. O ni ọmọkunrin yii ni yoo jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun kẹfa ti wọn aa pa laarin ọsẹ meji loṣu yii nikan. Ọkunrin naa sọ fun wa pe awọn ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa, ati pe gbogbo awọn to ba jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun niluu naa lawọn maa gbe, ti awọn aa si foju wọn ba ile-ẹjọ laipẹ rara.

 

 

(5)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.