Wọn ko idaamu ba alaga ijọba ibilẹ nitori Dapọ Abiọdun

Spread the love

 

 

 

 

 

 

Ọlọrun lo mọ ohun ti yoo gbẹyin ariwo iyọnipo ti wọn ni wọn fẹẹ yọ Alaga ijọba ibilẹ Idagbasoke Ifẹsowapọ, ni Ogun Water Side, iyẹn Ọnarebu Fẹmi Ọnakọya, nitori Dapọ Abiọdun ti wọn lo n polongo ibo fun.

Wẹrẹ bayii lọrọ naa jade lọjọ Aje ọsẹ to kọja yii, ti wọn ni awọn kansẹlọ kan kora wọn jọ. Awọn kansẹlọ marun-un ti wọn wa labẹ iṣakoso Alaga Ọnakọya, wọn ni awọn yoo yọ ọ nipo alaga, nitori bo ṣe n kopa ninu ipolongo ibo ti Dapọ Abiọdun, ondije dupo lẹgbẹ APC nipinlẹ Ogun n ṣe.

Ohun ti wọn ni awọn to fẹẹ yọ ọ naa sọ ni pe ẹgbẹ APM, ti ọga awọn, Gomina Ibikunle Amosun, fara mọ lo yẹ ki alaga yii maa tẹle, ki i ṣe pe ko maa ba ẹgbẹ alatako ṣe.

Yatọ si Ọnakọya ti wọn ni wọn ko idaamu ba yii, ẹni keji ti iyọnipo naa tun kan ni igbakeji ẹ, Alaaji Tajudeen Otuyiga, pẹlu awọn mẹta mi-in.

Ohun ti a tilẹ kọkọ gbọ ni pe wọn ti yọ wọn nipo, ṣugbọn nigba to ya niroyin tun jade pe igbesẹ yiyọ naa ṣi n lọ lọwọ ni, nitori ipade ti n waye ni Ogun Water Side, bẹẹ lo si n lọ niluu Abẹokuta naa.

Wọn ni awọn alagbara lẹgbẹ APM, eyi to jẹ Gomina Amosun ni olori wọn, ṣugbọn to jẹ awọn eeyan kan lo fi n boju, ni wọn wa nidii iyọnipo to fẹẹ waye naa.

Lati ọjọ Mọnde naa ni atako ti n wa kaakiri pe iyọnipo naa ko gbọdọ ṣẹlẹ, nitori irẹnijẹ ni yoo jẹ beeyan ko ba le tẹle ẹni to wu u ninu oṣelu mọ.

A gbọ pe Ọnakọya ti wọn fẹẹ yọ nipo paapaa ti sọ pe igbesẹ iyọnipo naa ko tọna. O ni nitori oun ko ba awọn to darapọ mọ APM ṣe ni wọn ṣe ṣiju le oun, oun ko si le ba ẹgbẹ naa ṣe rara, APC toun wa naa loun yoo maa ṣe lọ.

Bakan naa ni ẹgbẹ APC nipinlẹ Ogun bẹnu atẹ lu iyọnipo  ọhun.

 

 

 

 

(8)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.