WỌN KO BA TINUBU POO

Spread the love

O daju pe awọn ohun to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ oṣelu APC lati bii ọjọ mẹta kan sẹyin bayii, iyanu gbaa ni yoo maa jẹ fun olori oloṣelu ilẹ Yoruba, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu. Bii ere bii ere, ẹgbẹ naa to jẹ oun lo mọ bi wọn ṣe da a silẹ, to si jẹ oun ni olori alagbara inu rẹ nigba kan ti n bọ kuro lọwọ rẹ. Lati Eko titi de ipinlẹ Ogun, titi to fi de ipinlẹ Ọyọ, Ondo ati Ekiti, ẹnu ọkunrin nla ti wọn n pe ni Jagaban naa ko fi bẹẹ tolẹ ninu ẹgbẹ yii mọ, gbogbo agbara to si sa, gbogbo kira-kita to ṣe paapaa, pabo lo jọ pe kinni naa bọ si. O jọ pe awọn ti wọn lodi si agbara rẹ ninu ẹgbẹ oṣelu APC yii, awọn alagbara ẹgbẹ naa mi-in ti wọn ti n wa ọna lati mu un, ti wọn fẹẹ gba ẹgbẹ naa kuro lọwọ rẹ nilẹ Yoruba, o jọ pe wọn ti ri i mu bayii o. Ko si si ọna meji ti wọn fi gba ri i mu, awọn ọmọlẹyin rẹ ni wọn ko ba a.

Image result for tinubu

Ibi meji naa ni agbara oṣelu ilẹ Yoruba pin si: Eko lo ṣaaju, nigba ti ipinlẹ Ọyọ tẹle e. Ẹni to ba ni Eko lọwọ lo ni agbara ju, nitori owo rẹpẹtẹ to wa l’Ekoo, ati awọn ero pupọ to n ti ilu naa jade lasiko ibo didi. Ṣugbọn Ibadan lawọn Yoruba ṣi gba gẹgẹ bii ibujokoo agbara oṣelu wọn, Ibadan ni hẹdikọta, awọn ipinnu nla nla ti wọn ba si fẹẹ ṣe to ba ti kan gbogbo Yoruba lapapọ, ibẹ ni wọn ti n ṣe e, nigba to jẹ ibẹ ni ile ijọba gbogbo ilẹ Yoruba lati ọjọ to pẹ wa. Bi ẹgbẹ oṣelu kan ba waa wa to jẹ ohun lo mu awọn ipinlẹ mejeeji yii, ẹgbẹ naa yoo maa yan fanda ni, nitori ko si ohun ti ẹnikẹni yoo le ṣe fun un ni ilẹ Yoruba, aṣẹ to ba si pa ni yoo mulẹ, ohun to ba fẹ ko ṣẹlẹ naa ni yoo maa ṣẹlẹ, ko sẹnikan ti yoo le di i lọwọ. Ẹni to ba si jẹ olori, tabi aṣiwaju iru ẹgbẹ oṣelu bẹẹ ni gbogbo aye yoo mọ ni baba.

Ninu gbogbo ipinlẹ to wa ni Naijiria, ko tun si ipinlẹ kan to le duro woju ijọba apapọ, tabi to le fẹsẹ mejeeji duro mọ bi ijọba apapọ ko ba fun un lowo loṣu kan, afi ipinlẹ Eko nikan. Owo to n wọle fun wọn l’Ekoo yii ju owo to n wọle fun ọpọlọpọ orilẹ-ede Afrika lọ, bi ojumọ si ti n mọ, bẹẹ lowo naa n pọ si i. Ko sohun ti wọn fẹẹ ṣe ti wọn ko le fowo ṣe, bi olori ijọba apapọ kan ba si binu si wọn, wọn le ma woju rẹ, ki wọn maa na owo tiwọn funra wọn lọ. Oloṣelu ti Eko ba waa wa lọwọ rẹ, oun lọga ọpọlọpọ oloṣelu Naijiria, nitori bo ti ni owo ni yoo ni agbara. Ohun ti Tinubu fi jẹ ọga ree, ọga tawọn ọmọ ẹyin rẹ n pe ni masita. Owo wa ti wọn yoo na ti ọrọ oṣelu ba jẹ mọ owo, agbara si wa ti yoo lo bi ọrọ oṣelu ba jẹ mọ ti agbara. Ohun ti wọn si lo ti wọn fi gbe Buhari wọle ni ọdun 2015 niyẹn, eyi lo ṣe jẹ oun ni gbogbo aye n kan saara si.

Awọn oloṣelu ti wọn wa ni Abuja ti waa gbọn, wọn ti mọ pe owo to ni ati agbara to lo fun awọn yii, bi agbara naa ba wa lọwọ rẹ, yoo lo o fun ẹlomi-in ni, o si le maa lo o lati halẹ mọ awọn. Eyi ni wọn ṣe mura lati gba agbara naa kuro lọwọ rẹ lati igba ti Buhari ti wọle, to jẹ gbogbo ọna ni wọn n wa, gbogbo eto ti wọn si n ṣe ni lati ri i pe ko jẹ kinni kan ninu ẹgbẹ ọhun, awọn ti wọn ba si le kọyin si i, tabi ti wọn duro niwaju ẹ ti wọn tako o, awọn yẹn ni wọn n di ọrẹ awọn ti wọn n ṣe ijọba apapọ kia. Ohun to fa ija oun ati olori ẹgbẹ naa, John Oyegun, niyẹn, oun Tinubu n lo agbara, Oyegun naa si n lo agbara tirẹ. Tinubu lo agbara tirẹ debii pe Oyegun ko le pada ṣe alaga ẹgbẹ naa lẹẹkeji bo ti fẹẹ ṣe e mọ, baba naa pada sọrẹnda ni. Ṣugbọn Oyegun yii ti waa ni ọrọ to wa nilẹ yii, itakun to ni ki erin ma wọdo ni, oun aterin lo n lọ.

 

Image result for buhari

Itumọ eyi ni pe ki oun Oyegun too lọ, oun yoo ri i pe oun gba agbara oṣelu ti Tinubu ni kuro lọwọ rẹ, eleyii si dun mọ Buhari ati awọn eeyan rẹ ninu pupọ, nitori awọn naa n bẹru ọkunrin Tinubu yii, wọn ko mọ ọna to le gba yọ si wọn. Ọna wo ni wọn fi le gba agbara lọwọ rẹ? Ko si ọna mi-in ti wọn fi le gba agbara kuro lọwọ rẹ ju ki wọn gba ẹgbẹ lọwọ rẹ lọ. Wọn fẹẹ gba ẹgbẹ APC lọwọ rẹ, paapaa ni ipinlẹ Eko ati Ọyọ. Wọn ti mọ pe ko lẹnu ninu APC Ogun: Ibikunle Amosun, ọrẹ awọn Buhari loun, ko si ka Tinubu si babara kankan mọ. Wọn ti gba Ondo, Rotimi Akeredolu to n ṣe gomina mọ pe awọn ọmọ Buhari lo gbe oun wọle, wọn si ti mura bayii lati gba Ekiti, nitori wọn ti ri i pe Ṣẹgun Oni ti Tinubu fẹ ko du ipo gomina kọ ni wọn fa kalẹ, Kayọde Fayẹmi, ọkan ninu awọn ti wọn fẹẹ foju Tinubu gbolẹ gan-an lo wọle.

 

Image result for muiz banireImage result for fouad oki

Eyi ni pe Eko ati Ibadan lo ku, Eko gan-an ni wọn si doju kọ ju, nitori ibẹ ni ile agbara Tinubu. Ohun ti wọn ṣe ni lati pin ẹgbẹ naa si meji nibẹ. Ere ni Tinubu pe ọrọ naa nigba tawọn ọmọlẹyin rẹ kan binu, ti wọn bẹrẹ si gbo o lẹnu. Oun naa ti ṣẹ awọn kan ninu wọn tẹlẹ lati igba ti ko ti jẹ ki Tunde Faṣọla to ṣe gomina Eko gbẹyin mu ẹni to wu u, iyẹn Sasore, to si fi tipa gbe Akinwumi Ambọde le wọn lori pe ẹni toun fẹ niyẹn, gbogbo wọn si gbọdọ tẹle e. Loootọ ni wọn tẹle e, ti wọn fi Ambọde ṣe gomina, ṣugbọn awọn ọmọ Tinubu yii ko gbagbe ọrọ naa, wọn ko si fi bo pe awọn ko gba ti ọga awọn yii mọ. Agaga nigba ti Tinubu ko tun fẹ kawọn yii ṣe minisita fun Buhari, to tun jẹ awọn mi-in lo fẹ, inu tubọ bi wọn si i. Ohun to si jẹ ki Muiz Banirẹ, ọkan ninu awọn ọmọlẹyin rẹ, yari pe eyi to jẹ gaba le awọn lori to niyẹn.

Kaka ki wọn tun mọ ọgbọn lati fi tu Banirẹ ninu, wọn n bu u ni, gẹgẹ bi wọn ti ṣe bu Faṣọla naa tẹlẹ. Bo ṣe di pe awọn ero n pọ lọdọ wọn niyẹn. Ọrọ naa ko tun jọ wọn loju, afi lasiko ti wọn fẹẹ di ibo abẹle lati yan awọn oloye ẹgbẹ ni agbegbe gbogbo. Awọn ọmọ ẹyin Tinubu ṣe tiwọn lọtọ, awọn ti wọn n binu si i naa si ṣe tiwọn. Ni wọn ba yan alaga meji fun ẹgbẹ. Awọn Tinubu yan Tunde Balogun, awọn ti wọn si kọyin si tiẹ ti wọn n ba ijọba apapọ ṣe yan Fuad Okiki. Bi ọrọ ba ti waa da bayii, igbimọ-apaṣẹ ẹgbẹ naa ti Oyegun n ṣe olori rẹ ni yoo dajọ, eyi ti wọn ba si fọwọ si ninu awọn mejeeji ni wọn yoo mu lati ṣe akoso ẹgbẹ ni ipinlẹ wọn. Bi wọn ko ba mu ẹgbẹ Tinubu, yoo ṣoro fun un lati fa gomina kalẹ, ẹgbẹ naa ti bọ lọwọ rẹ niyẹn. Ṣugbọn awọn ọmọlẹyin Tinubu ti ko ba a, ibi ti wọn si gba mu un ko daa.

Image result for oyegun

Nigba ti awọn fẹẹ yan awọn alakooso APC ni ipinlẹ naa, ijọba ibilẹ ogun ni wọn ti ṣe e, awọn Tinubu si ṣe tiwọn nijọba ibilẹ mẹtadinlọgọta (57). Ijọba ibilẹ mẹtadinlọgọta tawọn Tinubu yan yii lo n da wahala silẹ lati aye Ọbasanjọ, ti Ọbasanjọ ko fun wọn lowo l’Ekoo fungba pipẹ. Awọn to n ba Tinubu ja yii naa ni wọn mọ aṣiri yii, wọn mọ pe ijọba ibilẹ mẹtadinlọgọta ko si ninu ofin Naijiria, ogun pere ni ijọba ibilẹ to wa l’Ekoo ninu ofin. Awọn yii naa ni wọn sọ pe ohun ti Tinubu ṣe niyẹn, wọn si ni ko ba ofin mu. Nibẹ lawọn Oyegun ti jokoo, ti wọn ni ohun ti awọn Tinubu ṣe ko ba ofin mu, ṣugbọn awọn yoo mọ ọna lati fi eto oṣelu yanju ọrọ naa. Ko si ibi ti wọn yoo yanju rẹ si ju pe wọn yoo ni ko le ni alaga ẹgbẹ ati awọn oloye kan lọ, ninu awọn ti wọn jẹ ọmọ Buhari yii ni wọn yoo ti yan alaga, ẹgbẹ yoo si bọ lọwọ rẹ loju ẹsẹ.

Bi wọn ti ṣe ni Eko yii naa ni wọn ṣe ni Ibadan, bi Eko yoo ti bọ lọwọ Tinubu, bẹẹ naa ni Ibadan yoo bọ lọwọ rẹ, nitori Adebayọ Shittu ati awọn to tẹle e ni yoo gba ijọba APC lọwọ Ajimọbi. Bẹẹ ọrọ iba ti ma ri bayii bi ko jẹ awọn ọmọ ẹyin Tinubu tẹlẹ ti wọn tu aṣiri ọrọ, awọn gan-an ni wọn si ko wahala ba a. Awọn kan ti sọ pe Jagaban yoo bọ ninu ẹ ṣaa o, ọna ti yoo gba yọ ninu okun ti wọn ki bọ ọ lọrun yii lẹnikan o ti i le sọ.

 

(199)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.