Wọn kan fẹẹ mu nnkan le funra wọn naa ni

Spread the love

Awọn ti wọn n ṣe akoso ẹgbẹ APC ti sọ pe miliọnu marundinlọgọta Naira (N55m) ni ẹni to ba fẹẹ du ipo aarẹ lorukọ ẹgbẹ wọn yoo ra fọọmu. Bo ba ra fọọmu, to si san owo rẹ, bo ba wọle, deede, bi ko ba si wọle, owo to san naa ti parẹ niyẹn. Ni ọdun 2014, miliọnu mẹtadinlọgbọn (N27m) ni wọn ta fọọmu naa. Ohun ti eleyii tumọ si ni pe owo ti wọn fẹẹ ta fọọmu lọdun yii ju ilọpo meji iye ti wọn ta a ni 2014 lọ. O daju pe awọn naa mọ bayii pe ilu le, nnkan ti lọ soke, iye ta a n ra ọja lọdun mẹrin tẹlẹ kọ la n ra a bayii, sibẹ, owo oṣu ko le, ko si si ọna abayọ fun mẹkunnu, bi ẹnikẹni ba si sọrọ kan, wọn aa ni ki wọn maa fori ti i ni, awọn kọ lawọn ba ilu yii jẹ, Jonathan ni. Tabi ki wọn ni Ọbasanjọ. Ṣugbọn iyẹn gan-an kọ lọrọ owo ti wọn fẹẹ ta fọọmu yii o. Awọn ti wọn gbe iru owo yii kalẹ mọ pe ọna lati le awọn eeyan sa kuro nidii eto naa ni, wọn ko fẹ ẹni ti yoo ba Buhari du ipo aarẹ. Bi ẹnikan ba fi gbogbo ijọ aye rẹ ṣe iṣẹ tiṣa, tabi ṣe iṣẹ ijọba, ti ko si mu ikan mọkan, to si gbọ gbogbo bukaata to yẹ ko gbọ, iru ẹni bẹẹ ko ni i ri iye owo ti wọn fẹẹ gba yii, koda, ko ni laakaye, ọgbọn ori, ati iriri to le fi ṣejọba Naijiria ko dara. Ati pe kin ni ẹgbẹ oṣelu gidi yoo gba iru owo bayii lọwọ awọn eeyan si. Bi ẹnikan ba gbe owo naa kalẹ, to ni oun yoo du ipo naa, to si n pariwo, awọn EFCC yoo bẹrẹ si i wadii rẹ, wọn yoo ni ibo lo ti rowo to to bẹẹ. Ṣugbọn ko sẹni ti yoo beere lọwọ Buhari, nitori ọkan ninu awọn ole ati ọlọṣa oloṣelu to n tẹle e kiri ni yoo dide ti yoo ni oun san owo fọọmu naa, ko si sẹni ti yoo beere iru iṣẹ to n ṣe. Itumọ gbogbo eleyii naa ni pe awọn ti wọn n ṣejọba yii ko ni i ṣeto idibo to lalaafia tabi ti ko ni ojuṣaaju ninu, wọn yoo ṣe gbogbo ẹ lati ri i pe Buhari wọle naa ni. Ko sohun to buru ninu ki Buhari wọle, ohun to buru ni ki wọn ma ṣeto idibo naa lọna ẹtọ ati ododo. Bi wọn ba ti ṣe e bo ti yẹ ki wọn ṣe e, bi Buhari ba pada wa, ko ṣe kinni kan. Ṣugbọn ẹ ṣeto idibo yii daadaa, nitori oni kọ, nitori ọjọ mi-in, ati nitori ohun ti yoo tidi ẹ yọ bi ẹ ba ṣojooro ni. Ẹni to ba leti, ko gbọ o.

(20)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.