Wọn kan fẹẹ da kun iṣoro wa ni o

Spread the love

Ariwo ti ijọba yii n pa bayii ni pe awọn fẹẹ ko awọn ṣọja wa soju ọna ki wọn le maa ṣọ ọna wa gbogbo ni ilẹ Yoruba ati ilẹ Ibo. Ẹ jẹ ki ọrọ naa ye yin o, wọn ko sọ pe awọn fẹẹ ko awọn ṣọja wa lati waa wọ inu igbo lọ ki wọn si le awọn onijamba yii jinna o, wọn ni awọn fẹẹ ko awọn ṣọja wa ti wọn yoo maa wa loju titi kaakiri ilẹ Yoruba, ti wọn yoo le mọ igba ti awọn Fulani onimaaluu yii ba fẹẹ ṣe iṣẹ wọn. Bi ijọba ti ko ba loootọ ba fẹẹ ṣe kinni kan, bi wọn ti n maa n da oju eto ru ree. Wọn yoo gbe eto naa kalẹ bii ẹni pe ohun ti araalu n beere fun ni wọn n mu bọ, amọ eto naa ki i ṣe eyi ti araalu fẹ, ohun ti yoo pada pa wọn lara ni. Iru ẹ ni eyi ti Igbakeji Aarẹ wa, Yẹmi Ọṣinbajo, ati awọn kan n gbe kiri bayii. Ohun ti wọn n wi ni pe awọn ti n ṣeto bi awọn ṣọja yoo ṣe maa ṣọ oju ọna wa gbogbo. Bẹẹ ki i ṣe iyẹn ni ohun ti awọn eeyan n beere fun. Ohun ti wọn n beere fun ni awọn ṣọja ti wọn yoo ko kalẹ, ti wọn yoo mura ogun, ti wọn yoo si wọ inu awọn igbo yii lọ. Ọpọlọpọ awọn Fulani ajinigbe yii ni awọn araalu mọ ibi ti wọn n gbe, awọn ọdẹ ti ri pupọ ninu wọn, wọn mọ awọn inu igbo ti wọn wa, bi awọn ṣọja ba si ṣetan lati wa wọn lọ, awọn araalu yii yoo ran wọn lọwọ lati fi ibẹ han wọn. Bi awọn ṣọja ba mura ogun wọn, ti wọn wọ inu igbo naa lati apa ọna Ikire, ti wọn wọ ọ de Kogi, wọn yoo le awọn ajinigbe yii danu, eyi ti wọn ba si pade lọna, wọn yoo jọ dana ibọn funra wọn. Awọn Fulani to n jiiyan gbe ki i duro loju titi, koda wọn ki i rin titi kan. Inu igbo ni wọn n gbe, inu igbo naa ni wọn si ti n jade, bi wọn ba si ti ji ẹni ti wọn fẹẹ ji gbe gbe tan, inu igbo naa ni wọn yoo gbe e wọ, ti wọn yoo si maa rin kaakiri igbo titi de ibi ti wọn fi ṣe ibudo wọn. Bi awọn ṣọja ba waa duro loju titi ti wọn n reti awọn Fulani ajinigbe nibẹ, wọn yoo kan wa nibẹ ti wọn ko ni i ri ẹnikan ni, nitori awọn Fulani ki i rin ni titi, awọn araalu lo n gba titi kọja, awọn Fulani to n daamu wọn n bẹ soju ọna lojiji ni, wọn o si ni i bẹ soju ọna nitosi ibi ti awọn ṣọja yii ba wa, anfaani wo waa ni ṣọja kiko soju ọna yoo ṣe fun wa. Nitosi Akurẹ, nibi ti awọn ajinigbe yii ti kọkọ n ṣoro ju, awọn ṣọja kan wa ti wọn ko jinna sibẹ, kin ni wọn ri ṣe fun wọn. Wọn ko le ri nnkan kan ṣe fun wọn nitori ki i ṣe itosi ibudo awọn Fulani yii ni wọn ti n waa ji awọn eeyan gbe, ọna wọn jin sibẹ, ti wọn ba si ti ṣe aburu wọn tan, wọn n lọ niyẹn. Iyẹn lo ṣe jẹ ki i ṣe awọn ṣọja ti wọn yoo waa maa yọ awọn araalu lẹnu la n wi, ti wọn yoo waa maa daamu wọn, ti wọn yoo maa le wọn kiri, ti wọn yoo tun sọ ara wọn di ṣẹrubawọn, ti wọn yoo maa gba owo lọwọ awọn araalu ti wọn n tọ ori titi wọn kiri jẹẹjẹ, ti wọn yoo maa da awọn eeyan duro, ti wọn yoo ni wọn ri awọn fin, pe ki wọn maa fo soke, ki wọn maa faya fa, ati bẹẹ bẹẹ lọ. Ko sẹni ti ko mọ awọn agbofinro Naijiria, anfaani lati daamu awọn araalu, lati gba owo lọwọ wọn lawọn ṣọja ti wọn ba ko si titi yii yoo sọ kinni ọhun da, bẹẹ ni iṣoro to n koju wa ko ni i tori ẹ lọ sibi kan. Awa ko fẹ ṣọja loju ọna wa, inu igbo ni ki wọn lọ lati koju awọn Fulani, nitori jagunjagun lo le koju jagunjagun.

(35)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.