Wọn ka Lon mọ ibi to ti fẹẹ fipa ṣe kinni fun Iya Wolii l’Akurẹ

Spread the love

Ọkunrin ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn kan, ni Lon Gbab Bogeuen, lọwọ ti tẹ nibi to ti n gbiyanju ati fipa ba wolii obinrin kan, Mercy Adebusuyi lo pọ l’Akurẹ, ni nnkan bii aago mẹsan-an alẹ ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu to kọja, lagbegbe Agbogbo, loju ọna marosẹ Akurẹ si Ọwọ.

 

Wolii Adebusuyi sọ pe ẹnikan to waa ki oun nile loun sin jade lalẹ ọjọ naa. Nigba to n pada bọ lẹnikan deedee ra a mu lati ẹyin, to si fọwọ di i lẹnu ko ma baa pariwo, ẹni ọhun yọ ọbẹ si i, to si ti i gbọn-ọn gbọn-ọn lọ sẹyin ṣọọbu kekere kan to wa lẹgbẹẹ oju ọna marosẹ ọhun, nibi to ti fipa ja gbogbo aṣọ ati awọtẹlẹ to wọ sọrun.

 

O ni lẹyin ti afurasi naa ti bọ gbogbo aṣọ ara oun tan, o da omi abẹ rẹ soun lara, bẹẹ lo tun yọ ada soun, to si fipa gba ẹẹdẹgbẹrin Naira to wa lọwọ oun.

 

Iya wolii ni ọkunrin yii kilọ foun nigba to ṣetan to fẹẹ maa lọ pe oun ko gbọdọ pariwo tabi dide kuro loju kan toun jokoo si titi ti oun yoo fi rin jinna.

 

Lẹyin to lọ tan ni Iya wolii lọ si tesan lati fi iṣẹlẹ ọhun to awọn ọlọpaa leti, wọn ko si ti i ba iwadii wọn jinna tọwo fi tẹ Lon ati ọrẹ rẹ kan to n jẹ Daniel John.

 

Ninu ọrọ ti Lon ba wa sọ, o jẹwọ pe loootọ loun fẹẹ fipa ṣe kinni fun ojiṣẹ Ọlọrun naa lalẹ ọjọ yii.

 

O ni ibi toun ti n ṣisẹ ọlọdẹ loun ti n bọ toun fi pade rẹ lọna, loju ẹsẹ lo ni ẹmi kan wọnu oun, toun si fa a lọ sẹyin ọkan ninu awọn ṣọọbu to wa lagbegbe naa nibi toun ti fipa bọ gbogbo aṣọ rẹ.

 

O ni nibi toun ti n gbiyanju ati gba ẹyin wọle si obinrin naa lara lẹyin to ti jọwọ ara rẹ ti ko si ba oun janpata mọ loun ṣakiyesi pe oun n damira, ara oun si walẹ wọọ lojiji.

 

Igba Naira to fun John ti wọn jọ n gbe ninu owo to fipa gba lọwọ obinrin to fẹẹ fipa ba lo pọ naa lo ṣokunfa bi wọn ṣe mu un pẹlu ọrẹ rẹ.

 

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Fẹmi Joseph, ni o di dandan ki awọn mejeeji foju bale-ẹjọ ni kete tawọn ba ti pari iwadii lori ẹsun ti wọn fi kan wọn.

 

 

(1)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.