Wọn ka ibọn mọ awọn ọmọ keekeeke lọwọ l’Ekoo

Spread the love

Kọmisanna ọlọpaa ni ipinlẹ Eko, Imohimi Edgal, ti gba awọn obi nimọran lati ri i pe wọn n mojuto awọn ọmọ wọn, ki wọn si mọ iru awọn ọrẹ ti wọn ba n ba a rin. Ọsẹ to kọja ni ọga ọlọpaa gba awọn eeyan nimọran yii lasiko ti wọn n ṣafihan awọn ọmọde kan ti ọjọ ori wọn ṣi wa labẹ ọdun mọkandinlogun fun iwa ọdaran l’Ekoo.

Awọn afurasi naa ni Taoheed, Matthew, Kudus ati Farouk ti a forukọ idile bo wọn laṣiiri. Wọn ni ṣe ni awọn ọmọde yii n lọọ digunjale, nigba ti wọn si n bọ ni ọwọ awọn ọmọ ẹgbẹ Oodua People’s Congress (OPC), tẹ wọn. Adugbo Itirẹ, ati Ijeshatẹdo ni awọn ọmọde yii ti maa n ṣọṣẹ.

Bo tilẹ jẹ pe kọmisanna ọlọpaa sọ pe awọn ọmọde yii jiyan pe awọn ki i ṣe adigunjale, pe ọdun kan ti wọn ṣe ti wọn n pe ni ayẹyẹ Ikọtun lawọn ti n bọ, ṣugbọn wọn jẹwọ pe ẹru ole wa ninu ẹru ti wọn ba lọwọ awọn naa.

Lara awọn nnkan ti wọn ka mọ wọn lọwọ ni ibọn iṣere ọmọde kan, oriṣiiriṣii foonu, ibọn ilewọ kan atawọn nnkan mi-in.

Edgal ti ni laipẹ lawọn yoo wọ wọn lọ si kootu, nibi ti wọn yoo ti sọ ohun ti wọn mọ nipa ẹsun ti wọn fi kan wọn niwaju adajọ.

(34)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.