Wọn ka Ṣeyi mọ ibi to ti n fipa ba ọmọdekunrin lopọ l’Ekoo

Spread the love

Kootu majisreeti kan to wa niluu Ikẹja ti paṣẹ pe ki derẹba, ẹni ọdun mejilelogoji kan, Ṣeyi Olowokere, ṣi wa latimọle ọgba ẹwọn to wa ni Kirikiri. Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe o fipa ki ‘kinni’ abẹ rẹ bọ ọmọ ọdun mejila kan niho idi.

Afurasi ọdaran naa, ẹni to n gbe laduugbo Masha Kilo, Surulere, nipinlẹ Eko, ni wọn fẹsun hihuwa idojutini (sodomy) kan.

Agbefọba to n rojọ tako o niwaju adajọ, Ezekiel Ayọrinde, sọ fun ile-ẹjọ pe ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹta, ni afurasi naa huwa yii nile rẹ. Wọn ni niṣe lo ri ‘kinni’ abẹ rẹ mọ ọmọ yii niho idi. Ẹsun yii lo si sọ Ṣeyi dero ẹwọn.

 

(92)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.