Wọn gbe ohun ti Lai Muhammed mọ-ọn jẹ de

Spread the love

Ni ti Minisita to n ri si eto iroyin ati ikede, Alaaji Lai Muhammed, bii igba ti wọn gbe ohun to mọ-ọn jẹ de ni, nitori nigba to ba di ka gbe irọ kalẹ, ka fi aṣọ alarabara yi i titi ti yoo fi da bii ootọ loju awọn ti wọn ba n wo o lọọọkan, boya lẹnikan tun wa to mọ iṣẹ naa ju minisita yii lọ. Ohun to si mu ki awọn eeyan rẹ fẹran rẹ ni pe ki i jẹ ki ọrọ balẹ ti yoo fi han an, oun lo si kọkọ sọko ọrọ buruku sawọn PDP nigba ti wọn yan Atiku, o ni Atiku ti wọn mu yii, ọba awọn ole ni, PDP tun fẹẹ da Naijiria pada si aye owo kikojẹ ni, asiko ti wọn yoo si ta Naijiria gan-an ree. O ni awọn ọmọ Naijiria ti gbọn, bi wọn ba ri Atiku, wọn yoo re e danu bii ata ori irẹsi ni, nitori wọn mọ pe ko loore kan lọwọ lati igba to ti n da si ọrọ ijọba Naijiria, ọna ti yoo fi pa wọn lara nikan lo n wa. Iru ọrọ yii lati ẹnu Bọọda Lai ko daa, niṣe lo n fi oun naa han bii onirọ, ẹlẹtan, alabosi, ati eeyan ti ko ṣee gbarale rara. Idi ni pe nigba ti Atiku kọkọ fẹẹ du ipo aarẹ ni 2007, to da ẹgbẹ AC silẹ, ti awọn Aṣiwaju Tinubu naa darapọ mọ ọn, Bọọda Lai ni alukoro fun ẹgbẹ naa, niṣe lo si jade pẹlu gbogbo agbara ati ọgbọn ori, to bẹrẹ si i pariwo Atiku yii, to ni ko sẹni to fẹran Naijiria to o, ati pe nitori pe o kọ ko jẹ ki Ọbasanjọ ko owo jẹ ni Ọbasanjọ ṣe n ba a ja. Ọkunrin naa ni Atiku ko ko owo jẹ, iṣẹ ilu lo dojukọ, eeyan daadaa ti gbogbo ilu, gbogbo ọmọ Naijiria pata gbọdọ dibo fun ni. Ọkunrin yii naa lo waa n pariwo pe ole l’Atiku loni-in yii o, pe o kowo jẹ nigba to n ṣejọba. Ewo la waa fẹẹ gbagbọ bayii o, ọrọ bii meji-mẹta lo ti jade lẹnu Bọọda Lai. Iru awọn eeyan wo lawọn oloṣelu yii na? O ga o.

(19)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.