Wọn gbe ibujoko igbẹjọ esi idibo gomina Ọṣun lọ s’Abuja …lẹgbẹ oṣelu PDP ba ni ọgbọn jibiti ni

Spread the love

Ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP), nipinlẹ Ọṣun, ti ke si ajọ to n ri si ọrọ awọn adajọ lorilẹ-ede yii, National Judicial Council (NJC), lati tete ṣewadii ni kikun lori idi ti wọn fi gbe ibujokoo ile-ẹjọ to n gbọ ẹsun to ṣuyọ lẹyin idibo gomina ipinlẹ Ọṣun to waye laipe yii kuro niluu Oṣogbo lọ siluu Abuja.
Ninu atẹjade kan ti alaga ẹgbẹ naa l’Ọṣun, Ọnọrebu Sọji Adagunodo, fi sita lo ti ni igbesẹ yii ti fi han kedere pe jibiti kan wa ninu awọn ẹgbẹ oṣelu APC ti wọn fẹẹ ṣe lori igbẹjọ naa.
A oo ranti pe ko ti i ju wakati mẹrinlelogun lọ ti oludije funpo gomina ninu idibo naa, Sẹnetọ Ademọla Adeleke, gbe iwe oniruuru ẹsun lori ọrọ idibo naa lọ siwaju awọn adajọ ti wọn kọkọ yan lati gbọ ẹjọ yii ti lẹta fi wa lati ọdọ aarẹ ile-ẹjọ ko-tẹ-mil-ọrun pe kawọn igbimọ olujẹjọ naa ṣiwọ lori ẹ, ti wọn si tun yan awọ igbimọ olugbẹjọ mi-in.
Nigba ti wọn si ti gbe awọn igbimọ olugbẹjọ mi-in kalẹ lawọn olupẹjọ ti n fẹsun kan awọn olujẹjọ, iyẹn oludije latinu ẹgbẹ APC, Alhaji Gboyega Oyetọla ati ẹgbẹ APC, pe ṣe ni wọn n mọ-ọn-mọ wọ ẹjọ nilẹ, ki wọn baa le fi asiko ile-ẹjọ ṣofo.
Ṣugbọn sadeede ni lẹta kan jade lati ọdọ akọwe igbimọ olugbẹjọ naa lọsan-an ọjọ Satide to kọja pe wọn ti gbe ibujokoo igbimọ naa kuro ninu ọgba ile-ẹjọ giga ilu Oṣogbo to wa tẹlẹ lọ si olu ilu ilẹ yii l’Abuja, lai sọ idi kankan ti wọn fi gbe igbesẹ naa.
Adagunodo ni idi ti ọrọ naa ko fi ba awọn nijafu ni pe awọn lookọlookọ kan ninu ẹgbẹ oṣelu APC ti n leri-leka kaakiri lati nnkan bii ọsẹ mẹta sẹyin pe ilu Abuja ni ẹjọ naa n lọ, ṣugbọn ẹgbẹ PDP ro pe ẹka eto idajọ ko ni i gbabọde debii pe ẹgbẹ oṣelu kan ni yoo maa dari ẹ ṣibaṣibo.
O ni titi di asiko ti a n ko iroyin yii jọ, ẹnikẹni ko kọ lẹta tabi ranṣẹ si ẹgbẹ PDP lati fi to wọn leti pe ibukojoo naa ti kuro l’Oṣogbo lọ si Abuja, bẹẹ ni ko sẹni to ba awọn agbẹjọro ẹgbẹ naa ṣepade lori ẹ rara.
Ti iru igbesẹ bayii ba fẹẹ waye, gẹgẹ bi Adagunodo ṣe ṣalaye, ami gbọdọ wa pe boya awọn kan n da awọn igbimọ naa laamu, tabi pe ko si aabo fun ẹmi ati dukia wọn niluu Oṣogbo ti wọn ti n gbọ ẹjọ naa tẹlẹ, ṣugbọn ko si nnkan to jọ bẹẹ rara. O ni wọn ṣe eleyii lati le jẹ kijọba apapọ ti APC n dari lanfaani lati tọwọ bọ ẹjọ naa, ki wọn si yi idajọ po.
Adagunodo waa ke si ajọ NJC lati tete gbe igbesẹ lori ọrọ naa nitori ile-ẹjọ ni ireti ikẹyin ti awọn araalu ni, ati pe oju gbogbo lo wa lara ẹka eto idajọ lori ọrọ idibo gomina to waye loṣu kẹsan-an, ọdun yii, ọhun nitori yoo ni ipa lori idibo apapọ to n bọ lọdun 2019.

(17)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.