Wọn fi iya ọna meji jẹ Omiṣore

Spread the love

Iroyin to n ja kiri ilu bayii ni pe Iyiọla Omiṣore ti i ṣe oloṣelu Ọṣun ko ni i le lọ si Amẹrika lasiko yii bo ba fẹẹ lọ. Wọn ti fi sese se e mọle. Ki lo ṣẹlẹ, wọn ni orukọ rẹ wa ninu orukọ awọn ti ijọba Amẹrika gbegi le fisa ti wọn ba ti ni tẹlẹ, ti wọn si ni awọn ko ni i fun wọn ni tuntun lati wọ orilẹ-ede awọn, nitori iwa ti wọn hu ni asiko ibo to lọ. Nigba ti wọn ti le kangi mọ ẹni to ṣeto ibo naa funra rẹ nimu, oṣiṣẹ INEC to yi gbogbo ọrọ pada, wọn ni ko sẹni ti kinni naa tun kan ju Omiṣore ti wọn lo orukọ rẹ lati fi da gbogbo ipinnu awọn ara Ọṣun ru lọ. Nitori bẹẹ, wọn ni okunrin naa ko ni i le de Amẹrika fun igba pipẹ, wọn tiẹ ni wọn ko fẹẹ ri i. Ohun ti iba si bo o laṣiiri ni ki wọn fi i ṣe minisita nitori lara ohun to jẹ ko ṣe bo ti ṣe niyẹn, ara awọn ileri tawọn ti wọn tan an pa ṣe fun un niyẹn pe bo ba ti wọn lẹyin, yoo ṣe minisita. Ṣugbọn awọn ti wọn ṣeleri fun un naa ni wọn gba ipo ti wọn fẹẹ fun un lọhun-un, ni kurakuta ba pin, n niya ọna meji ba jẹ Iyiọla Omiṣore. Gbogbo ere to sa, gbogbo ọna to gba lasiko ibo naa, gbogbo ẹ lo ja si pabo, to ja si korofo fun un. Ko sohun meji to jẹ ki laalaa rẹ ja sasan lori ọrọ idibo yii ju pe ko ṣe ohun to ṣe nitori awọn araalu lọ, o ṣe e nitori ijẹkujẹ tawọn oloṣelu n jẹ kiri, nitori ifẹ ipo, ifẹ owo ati awọn ohun mi-in gbogbo. Bi eeyan ba fi ootọ inu ṣiṣẹ fun araalu, yoo jere rẹ bo ba ya, araalu ko si ni i gbagbe oore to ṣe fun wọn. Ṣugbọn awọn ti wọn ba n fi orukọ araalu jẹun lasan, ti wọn lo awọn eeyan lati fi wọn gba ipo, lati fi wọn gba owo, ati bẹẹ bẹẹ lọ, awọn araalu paapaa da wọn mọ, wọn ko si ni i ṣe apọnle kan fun wọn. Koda bi wọn ṣubu bayii, ẹrin ni wọn yoo maa fi wọn rin. Ibo Ọṣun ti waye o ti lọ, ṣugbọn awọn eeyan yii yoo maa ranti ohun ti wọn ṣe. Awọn ti wọn dibo fun ẹgbẹ oṣelu APC, ọmọ ipinlẹ Ọṣun ni wọn, awọn ti wọn dibo fun PDP ọmọ ipinlẹ Ọṣun ni wọn, bi ibo ẹni kan ba waa pọ ju ti ẹni kan lọ, ki i ṣe dandan lati ṣojooro tabi da oju ibo naa ru, ka sọ pe a fẹẹ fipa gbajọba lọwọ awọn to wọle tabi ka maa gbe oriṣiiriṣii ọrọ kiri. Awọn araalu lo dibo, ọmọ ipinlẹ kan naa si ni gbogbo wọn o, ko si ajọji nibẹ, ẹni ti wọn ba dibo fun, koda ko je alakiisa ni, afi ka jẹ ko ṣejọba. Iyẹn lo n jẹ pe a ko yi ero awọn araalu pada, ipinnu ti araalu ba si ṣe, a ko da a ru. Ẹni ti yoo gbajọba ko ni i ku sibẹ, bo ba lo ọdun mẹrin ti ko ṣe e daadaa, awọn araalu yoo dibo fun ẹlomi-in to ba tẹ wọn lọrun. Ojooro ati eru ti awọn oloṣelu ilẹ wa n lọwọ si ni ko dara, nitori ki i tun nnkan ṣe, bẹẹ ni ko mu ilọsiwaju ba wa, o n sọ wa di ẹni yẹyẹ laarin awọn orilẹ-ede agbaye ni. Iyẹn l’Amẹrika ṣe binu sawọn eeyan bii Omiṣore, o si daa bi wọn ṣe da seria fun un.

(0)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.