Wọn fẹsun ifipabanilopọ kan Micheal, lo ba binu para ẹ l’Ekoo

Spread the love

Laduugbo Festac Town, niluu Eko, ni otẹẹli ti ọkunrin oniṣowo kan, Micheal Aṣiwaju, para rẹ si wa, o ni nitori ẹsun ifipa-ba-ni-lo-po ti wọn fi kan oun loun ṣe gbe majele jẹ.

Micheal, ẹni ti awọn tiẹ tun mọ si Mike Cash, lo da oogun apakokoro Sniper mu lasiko to wa ninu yara kan loteeli naa ni nnkan bii aago mejila aarọ ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ to lọ lọhun-un, iyẹn ọjọ kẹtala, oṣu yii.

Irọlẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ni Micheal gba yara si otẹẹli naa, nigba to si wa nibẹ lo fi ọrọ kan sita lori ikanni twitter rẹ, iyẹn Aṣiwaju_limited, pe oun yoo pa ara oun. Nnkan to fa igbesẹ ti ọkunrin yii gbe ko ṣẹyin bi obinrin kan ṣe sọ fun un lori ikanni twitter pe aṣiri bo ṣe fipa ba obinrin kan lo pọ ninu ọkọ ayọkẹlẹ rẹ ti tu si oun lọwọ, oun yoo si tu u sita fun gbogbo aye lati gbọ. Ko pẹ si asiko yii ni obinrin naa, ẹni ti orukọ to n lo lori ikanni twitter rẹ n jẹ @thatgoddess, fi awọn itakurọsọ ti Micheal ati obinrin kan jọ sọ lori foonu ranṣẹ si i, obinrin naa si sọ pe Micheal fipa ba oun lo pọ ninu oṣu karun-un, ọdun 2017. Ninu ọrọ naa ni obinrin to ni Aṣiwaju fipa ba oun lo pọ yii ti ṣalaye pe ṣe ni ọkunrin naa tan oun lọ si otẹẹli kan to wa laduugbo Festac, to si fipa ba oun lo pọ nibẹ. O fi kun un pe owo ati ẹbun ni Aṣiwaju fi tan oun de otẹẹli naa.

Ọmọbinrin naa ṣalaye ninu ọrọ to fi sori ẹrọ ayelujara pe oun pẹlu aburo Aṣiwaju ni awọn jọ wa ninu ọkọ, nigba ti awọn si de otẹẹli, niṣe ni aburo ọkunrin naa gbe ọkọ ayọkẹlẹ Aṣiwaju jade, o si fi awọn mejeeji nikan silẹ lotẹẹli yii. O ni lẹyin eyi ni ọkunrin naa sọ pe koun wọ inu yara kan lotẹẹli naa lọ, ko si pẹ rara to fi pada waa ba oun ninu yara toun wa, o si tilẹkun pa. O ni niṣe ni Mike bẹrẹ si i fọwọ tẹ oun lara, o si sọ foun pe oun ti di ọrẹbinrin oun, o si daju pe oun aa ba oun lo pọ lọjọ naa. Lasiko ọhun lo ni awọn mejeeji jọ bẹrẹ si ni i ja.

Ṣugbọn, lọjọ Abamẹta, Satide, to lọ lọhun-un ni Aṣiwaju fesi si awọn ẹsun ti ọmọbinrin yii fi kan an. O ni loootọ, ọrẹbinrin oun ni ọmọ naa i ṣe, ori ẹrọ ayelujara loun si ti pade wọn. O ṣalaye pe oun ni awọn ọmọbinrin naa lọwọ pupọ, koda, oun ti na owo to to ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta Naira (500,000.00), fun awọn meji ri ni ile igbafẹ (club).

Okunrin yii ni loootọ loun ba awọn ọmọ naa sun, ṣugbọn ki i ṣe pe oun fipa ba wọn lo pọ gẹgẹ bi wọn ṣe n sọ kiri, ati pe latọdun 2017 ni iṣẹlẹ ti wọn n ro mọ oun lẹsẹ naa ti ṣẹlẹ. O fi kun un pe ọkan ninu awọn ti oun n ba ṣowo tẹlẹ torukọ rẹ n jẹ Blessing lo wa nidii ibanilorukọjẹ ti wọn n ṣe fun oun naa, bẹẹ lo ni ọmọbinrin to pe ara rẹ ni goddess yii ati Blessing ni ki wọn mu lẹyin toun ba ku tan, nitori wọn kan mọ-ọn-mọ fẹẹ ba orukọ oun jẹ ni.

Ọmọkunrin naa sọ pe ibanilorukọjẹ ti wọn ṣe foun yii loo gbẹmi lẹnu mama oun, ṣugbọn awọn to n ba oun lorukọ jẹ kiri yii ko ri i ro rara nigba toun sọ fun wọn, niṣe ni wọn tẹpẹlẹ mọ iwa ti wọn n hu.

Aṣiwaju ni awọn ọmọbinrin ti wọn ba orukọ oun jẹ yii naa ti gbagbe pe awọn ni fọto ihooho ti wọn ya lọdọ oun, ko si pẹ rara to fi fi awọn fọto ihooho awọn ọmọbinrin meji ọtọọtọ ṣori ikanni naa, to si tun fi fọnran fidio ibalopo ti oun pẹlu ọmọbinrin kan jọ ni sita.

Ọkunrin naa sọ pe nitori ibanilorukọjẹ ti awọn eeyan naa ṣe foun ti da itiju nla soun lara loun fi gbẹmi ara oun. O ṣalaye siwaju pe ọmọ kan ṣoṣo toun bi ko le toṣi laye, nitori oun ti ṣiṣẹ owo silẹ fun un rẹpẹtẹ to maa to o jẹ.

No nnkan bii aago mejila ọsan ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ to lọ lọhun-un ni awọn ọlọpaa ri oku rẹ gẹgẹ bi Alukoro wọn nipinlẹ Eko, Chike Oti, ṣe sọ ọ di mimọ. O ṣalaye pe awọn ọlọpaa ri igo Sniper meji ninu yara naa. Agbofinro yii ni awọn ti bẹrẹ iwadii, awọn si ti ṣayẹwo si oku naa, eyi to fi han pe ko si oju apa kankan lara rẹ.

 

(1)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.