Wọn fẹẹ ko ba mi ni o, emi o pe Adeleke lẹjọ kankan o- Shuaibu

Spread the love

Ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Oṣun ti wọn sọ pe o pe Sẹnetọ Ademọla Adeleke lẹjọ lori ọrọ iwe-ẹriỌgbẹni Ajayi Shuaib, ti sọ pe irọ to jinna soootọ lọrọ naa, ati pe ṣe ni wọn kan fẹẹ fi ọrọ naa ba oun lorukọ jẹ.

 

Ọkunrin naa niroyin gbe lọsẹ to kọja pe o gbe iwe ipẹjọ kan lọ sileẹjọ giga ti ijọba apapọ to wa niluu Oṣogbo, nibi to ti sọ pe Adeleke to jẹ oludije funpo gomina ipinlẹ Ọṣun labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP lọdun to kọja ko kunju ouwọn lati du ipo naa.

 

Ṣugbọn nigba ti ọkunrin naa n ba Alaroye sọrọ, o ni ọrẹ oun kan to jẹ oṣiṣẹ Sifuu-Difẹnsi, Bukọla Adewale, lo wa si ile oun niluu Agbeye, lọjọ karun-un, oṣu karun-un, ọdun yii, ṣugbọn ko ba oun nile.

 

Gẹgẹ bi Shuaib ṣe sọ, ‘Iyawo mi lo ba nile, o pe mi lori foonu pe nipa ọrọ iṣẹ ti mo n wa ni o, ati pe oun ti ba mi ri iṣẹ kan, ohun ti mo nilo ni fọto mi pelebe kan ati kaadi ọmọ ẹgbẹ PDP mi, mo si sọ funyawo mi pe ko ba mi fun un.

 

“Nigba to di ọjọ kẹwaa, oṣu yii, Adewale pe pe ki n waa pade oun l’Oṣogbo, nitori awọn ti wọn fẹẹ ba mi ṣe ọrọ iṣẹ yẹn wa loju-ọna Gbọngan/Abere, niluu Oṣogbo. Nigba ti awa mejeeji debẹ, mo ba ẹnikan ti wọn n pe ni Lọya Ọyagbile, o beere pe ṣe Adewale ti ba mi sọ nipa ọrọ iṣẹ naa, mo si sọ pe bẹẹ ni.

 

“Ọyagbile sọ pe mo nilo lati bu ọwọ lu awọn iwe kan, idunnu pe wọn ba mi riṣẹ ko jẹ ki n ka nnkan to wa ninu iwe ti wọn ko fun mi ti mo fi buwọ lu u, bẹẹ ni wọn gba fọto pelebe mi silẹ.

 

“Ijọloju lo waa jẹ fun mi nigba ti mo gbọ pe mo pe Sẹnetọ Ademọla Adeleke lẹjọ. Mi o figba kankan gbero iru ẹ latigba ti mo ti di ọmọ ẹgbẹ PDP, mi o si ba ẹnikẹni sọ iru ẹ ri. Mo ti ṣetan lati gbe ẹjọ naa de ibi to lapẹrẹ tori ibanilorukọ jẹ patapata ni.

 

“Nibi ti ẹ ti maa mọ pe ọgbọnkọgbọn ni wọn n da ni pe Wọọdu 6, Agbeye, nijọba ibilẹ Odo-Ọtin,ni mo ti wa, ki i ṣe Wọọdu 5 ti wọn sọ pe mo kọ sinu iwe ipẹjọ”.

 

Ninu ọrọ tirẹ, adari awọn agbẹjọro to n ṣoju fun Ademọla nile-ẹjọ rọ awọn agbofinro lati ṣewadii bi iwe ipẹjọ naa ṣe jẹ ati ipa ti Adewale ko ninu ẹ. O ni iṣẹ ti ko ṣee da duro ni Ademọla Adeleke, ati pe laipẹ yii ni ile-ẹjọ yoo kede rẹ gẹgẹ bii gomina.

@@@@@@@@

 


Settings
Alaroye Alaroye

alaroye.alaroye@yahoo.com

(28)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.