Wọn dana sun Aanuoluwa n’Ileṣa, wọn lo maa n mu ‘kinni’ awọn ọkunrin

Spread the love

Ẹni ọdun mejilelogun kan, Aanuoluwa, ni awọn ara Ileṣa dana sun niwaju ile-ifowopamọ Union Bank, to wa ni gbagede Ileṣa, lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ to kọja. Eyi waye lẹyin ti arakunrin kan, Ademọla Adekọla, fẹsun kan an pe o ti mu nnkan ọmọkunrin oun lọ.

Gẹgẹ ba a ti gbọ, bii were ni Aanuoluwa ṣe n rin kiri niwaju ileewe onimọ-ẹrọ ijọba apapọ to wa lopopona Ileṣa si Ijẹbu-Jẹṣa, lowurọ ọjọ naa ko too lọ siwaju ile-ifowopamọ Union Bank, to ti mu nnkan ọmọkunrin Ademọla yii. Nigba ti iyẹn si ṣakiyesi pe nnkan kuro lara oun lo figbe ta, ti awọn eeyan si pe le e lori.

Ko too di pe awọn araalu dana sun ọmọbinrin naa, akọroyin Alaroye fi ọrọ wa a lẹnu wo, o si jẹwọ pe loootọ ni oun maa n gba nnkan ọmọkunrin, awọn to fi n ṣoogun owo si loun n ta a fun. O ni iyẹn nikan kọ, pata awọn obinrin naa wa ninu awọn nnkan toun fi n ṣowo, bẹẹ loun maa n mu awọtẹlẹ awọn ọkunrin naa, awọn ti wọn yoo fi ṣowo loun n ta wọn fun lowo gọbọi.

Gbogbo bi awọn eeyan ṣe fẹẹ lu u lobinrin naa n kilọ fun wọn pe ọkunrin yoowu to ba ṣiwọ lu oun, nnkan ọmọkunrin rẹ yoo ra mọ ọn labẹ ni. O jọ pe eyi lo bi awọn to wa nibẹ ninu ti wọn ṣe fi okuta fọ ọ lori, ti wọn si dana sun un. Gbogbo bi wọn ṣe n dana sun un yii ni awọn ṣọja ati ọlọpaa to n ṣọ banki Union Bank ati WEMA to wa ni gbagede naa ṣe bii ẹni ti ko ri wọn.

Igbagbọ ọpọ eeyan to gbọ iroyin naa ni pe o yẹ ki awọn agbofinro daabo bo ọmọbinrin naa, ki wọn le mu un lọ si agọ ọlọpaa to ba sun mọ itosi nibẹ, ko si le jiya to tọ si i labẹ ofin. Ṣugbọn ọga ọlọpaa kan to ni ka forukọ bo oun laṣiiri ni ko si nnkan to kan awọn agbofinro to n ṣọ banki mejeeji yii nibi iṣẹlẹ to waye naa, o ni iṣẹ wọn ni lati ṣọ banki mejeeji to wa ni adugbo naa, wọn ko si gbọdọ fi ibẹ silẹ fun idi kankan. Bẹẹ lo ni ẹni kan ko fi ọrọ naa to awọn ọlọpaa leti, tori idi eyi, awọn ko le sọ pe awọn mọ nipa rẹ.

Ọpọ ero lo n waa wo eeru ọmọbinrin naa niwaju ile-ifowopamọ ti wọn ti jo o, titi di asiko ti a si n ko iroyin yii jọ, ibi ti wọn gbe ajoku ọmọbinrin naa lọ ko han si ẹnikẹni.

(20)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.