Wọn dana sun Ṣọla niluu Lanlatẹ, wọn ni adigunjale ni

Spread the love

Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kọkandinlogun, oṣu to kọja, ni awọn afurasi tọọgi kan niluu Lanlatẹ dana sun Oluṣọla Diẹkọla, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn, wọn ni adigunjale ni.
Inu igbo kan ni wọn sun ọmọkunrin yii si. Ẹnikan tiṣẹlẹ naa ṣoju rẹ ṣalaye fun wa pe iṣẹ fọga ni Ṣọla n ṣe, bẹẹ naa lo si tun maa n fi ọkada rẹ gbero. Ilu Maya ni a gbọ pe o gbe awọn ero meji kan lọ lati ilu Eruwa, ṣugbọn nigba to fẹẹ de ilu Maya naa lo ri awọn ọlọpaa loju ọna to lọ siluu Abẹokuta, lẹsẹkesẹ lo si sọ awọn ero rẹ kalẹ, to si yi ori ọkada rẹ pada.
Iwa ti Ṣọla hu yii lo fu awọn ọlọpaa naa lara, idi rẹ si niyi ti wọn fi ni ki awọn eeyan ba awọn le ọkunrin naa lọ.
Adugbo Orita ni ọwọ awọn eeyan ti pada tẹ ẹ, wọn si lu u bii ejo aijẹ titi ti ẹmi fi bọ lara rẹ, nibẹ naa ni wọn si dana sun un si.
Iroyin yii lo kan baba ọmọ naa, Ọgbẹni Oluwọle Diẹkọla, lara, agba ara ni baba naa si fi de ibi iṣẹlẹ yii.
Baba oloogbe naa sọ pe ọmọ oun ki i ṣe ole. Ọkunrin to n gbe adugbo Oniyọ, Ankọ, Eruwa, yii sọ fun wa pe laaarọ ọjọ naa ni Ṣọla ti kọkọ gbe ọmọ rẹ lọ sileewe, ko too waa gbe ero nigba to n bọ, nibẹ lo si ti kagbako iku ojiji.
Abilekọ Funkẹ Diẹkọla ti i ṣe aya oloogbe naa sọ pe ko si ootọ ninu ọrọ ti wọn n sọ kiri pe ole ni ọkọ oun. Obinrin naa waa rọ awọn ọlọpaa ati ijọba lati tete ṣawari awọn to wa nidii ọrọ naa, ki wọn si fi iya to tọ jẹ wọn.

(40)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.