Wọn ṣi n wa Biffo, kooṣi Katsina United ti wọn ji gbe

Spread the love

Titi di asiko ta a pari akojọpọ iroyin yii, inu ibẹru ni ẹbi ati ara Abdullahi Biffo to jẹ kooṣi Katsina United wa pẹlu bi awọn ajinigbe ko ṣe ba awọn eeyan rẹ sọrọ mọ lẹyin ti wọn gbowo.

Iwadii fi han pe ni nnkan bii ọsẹ mẹji sẹyin lawọn ajinigbe kan gbe Biffo lọ, nigba ti wọn si kan si mọlẹbi rẹ ni wọn wa miliọnu mẹẹẹdogun fawọn eeyan ọhun, ṣugbọn wọn ko gburoo wọn mọ.

Lẹyin ọjọ mejila ti wọn ti gbe ọkunrin naa lawọn oniroyin gan-an too gbọ, bẹẹ lawọn eeyan n pariwo pe kijọba ati kilọọbu rẹ tete wa a ri ki nnkan mi-in too ṣẹlẹ.

Lara awọn to kegbajare ni Kabiru Dogo to jẹ kooṣi Sunshine Stars ati Imama Amapakabo toun jẹ igbakeji kooṣi Super Eagles. Wọn rawọ ẹbẹ si awọn alaṣẹ ere bọọlu, ijọba atawọn to le ran mọlẹbi ọkunrin naa lọwọ lati gbe igbesẹ ni kia.

Ọmọ ipinlẹ Kwara ni Biffo, o si ti ṣe kooṣi ni Niger Tornadoes ati Abia Warriors tẹlẹ.

 

 

 

 

 

 

(9)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.