Wọn ṣi ileewe Ileṣa Grammar School pada, ṣugbọn NCNC ati AG lawọn o ni i sun, afi ti awọn ba le Akintọla lọ

Spread the love

Awọn onilu ni ilẹ Yoruba, nnkan ni wọn, paapaa awọn ti wọn maa n lu iyaalu. Ohun to mu wọn yatọ si awọn onilu to ku ni owe ti wọn maa n fi ilu wọn pa, owe ti yoo maa dun ketekete leti bii ẹni pe ọrọ ẹnu ni. Nigba ti wọn ba n fi orin wọn ṣe faaji lọ, wọn yoo maa fi ilu wọn powe nigba mi-in bayii pe: Ko ni i mọyi to daa, ko ni i mọyi to daa, bobinrin o dan-le ọkọ meji wo, ko ni i mọyi to daa. Itumọ ọrọ naa ni pe bi obinrin ko ba ti i kuro ni ile ọkọ kan bọ si ile ọkọ miiran, ko ni i mọ eyi to dara ninu awọn ọkọ. Bi ọrọ ti ri fun ẹgbẹ oṣelu NCNC ni ilẹ Yoruba ninu oṣu kẹrin, ọdun 1964, niyi, iyẹn nigba ti Oloye Ladoke Akintọla da jinnijinni bo wọn, to ko ṣibaṣibo ba wọn. Igba naa ni wọn yi ohun pada, ti wọn n kọrin mi-in: orin Ọbafẹmi Awolọwọ ni wọn si n kọ lẹnu tantan. Awọn Yoruba ọmọ ẹgbẹ naa ni Awolọwọ lawọn fẹẹ ri.

Ohun ti ọrọ naa ṣe ya awọn eeyan lẹnu ni pe ko ti i ju ọdun meji lọ, koda ko ti i pe ọdun meji rara nigba ti awọn eeyan naa sopanpa, awọn ọmọ Yoruba ti wọn wa ninu ẹgbẹ NCNC, ti Rẹmi Fani-Kayọde ṣe olori wọn, ti wọn ni bi awọn Hausa ti wọn n ṣejọba Naijiria ba le pa Awolọwọ ki wọn pa a, ohun toju ẹ wa loju ẹ ri, igberaga ati ọgbọn agbọnju lo n pa a ku lọ. Loootọ ni awọn ọmọ Ibo ti wọn jẹ olori ẹgbẹ naa wa, ṣugbọn awọn Yoruba ti wọn wa ninu ẹgbẹ yii ni wọn gbe ọrọ naa lọọ ba wọn, Michael Okpara si ba wọn ṣepade, o si beere lọwọ wọn pe kin ni wọn fẹ ki NCNC, ẹgbẹ wọn ṣe fun wọn. Wọn ni awọn ti ro o daadaa, ọrọ ija to wa ni Western Region yii, ki awọn ma tẹle Awolọwọ lọ o, Ladoke Akintọla ni ki awọn tẹle, nitori oun ni aṣaaju daadaa to le ṣe ohun ti awọn ba fẹ fawọn. N ni Okpara ba faṣẹ si i.

Aṣẹ to pa lọjọ naa lo jẹ ki awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin gbogbo ti wọn jẹ NCNC tẹle Akintọla, ti wọn si fi ibo wọn gbe e wọle gẹgẹ bii Prẹmia. Bẹẹ, bo ba jẹ wọn ko ṣe bẹẹ ni, Dauda Adegbenro ni iba di Prẹmia yii, nigba to jẹ oun ni aṣaaju awọn AG nile igbimọ, ẹgbẹ Action Group yii lo si ni ọmọ ile igbimọ aṣofin to pọ julọ nigba naa. Amọ nigba ti ẹgbẹ NCNC ti ba Akintọla lọ n’Ibadan, ibi ti wọn ti fi ẹyin ẹgbẹ AG janlẹ niyẹn. Ni Akintọla ba di Prẹmia. Nigba ti wọn waa pa ẹran nla naa tan ni ija ba de lori bi wọn yoo ti pin ẹran ọhun, ni Akintọla ba jẹwọ fun wọn pe oun gbọn ju wọn lọ, o si ṣe e ṣe e titi to fi sọ ẹgbẹ NCNC di korofo ni West, nitori o da ẹgbẹ oṣelu tirẹ silẹ, NNDP, Ẹgbẹ Dẹmọ, o si ko ọpọlọpọ awọn ọmọ NCNC ibẹ lọ. Awọn eeyan naa kuro ninu NCNC, wọn ba Ẹgbẹ Dẹmọ lọ.

Iyẹn lo fa orin tuntun ti awọn NCNC bẹrẹ si i kọ nigba ti Akintọla fọwọ mejeeji ti wọn jade bii iyawo to lowo lọwọ ju ọkọ rẹ lọ, to loun ko fẹ wọn mọ. Igba naa ni awọn Yoruba NCNC ranti Awolọwọ, wọn ni awọn gbọdọ yọ ọ jade lẹwọn kia. Wọn ni igba tirẹ tu awọn lara ju asiko Akintọla yii lọ. Ọkan pataki ninu awọn ọmọ ẹgbẹ NCNC ni Richard Akinyẹmi, ọmọ ile igbimọ aṣofin West ni pẹlu, gbogbo ohun to si ṣẹlẹ ko ṣe ẹyin rẹ rara, koda, o fi ọwọ ati ẹsẹ si i, oun ati awọn aṣaaju to ku nigba naa. Minisita ni labẹ Akintọla nigba ti nnkan dara, ṣugbọn nigba ti ija de, Akinyẹmi binu fi ipo rẹ silẹ, o ni oun ko le tori pe oun yoo jẹ ẹran ki oun maa pe maaluu ni bọọda, ohun ti ko daa ko daa. Lati igba to ti waa kuro loun naa ti di ọta Akintọla, o koriira Akintọla bi Akintọla naa ti koriira rẹ, o ni ọdalẹ l’Akintọla, ki i ṣe ẹni ti eeyan i ji ri.

Oun lo kede ni ọjọ keje, ọṣu kẹrin, ọdun 1964, pe wọn ti pade o, gbogbo apapọ awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin Western Region ti awọn jẹ ọmọ NCNC, awọn ti pade, awọn ọmọ igbimọ naa ni wọn si ran oun jade lati waa sọ ohun ti awọn sọ nibi ipade awọn. Kin ni wọn si sọ? Wọn ni igbimọ ọmọ ẹgbẹ NCNC nile igbimọ aṣofin Western Region ti fi ohun ṣọkan pe ki ijọba Tafawa Balewa ṣepade, ki wọn si yọ Oloye Ọbafẹmi Awolọwọ kuro lẹwọn, ki wọn fori ohun yoowu ti i baa ṣe ji i, ki wọn jẹ ko maa pada bọ ni West, ko waa ba wọn tun Western Region ṣe, ko si le ṣiṣẹ idagbasoke fun Naijiria lapapọ. Akinyẹmi ni ọrọ ti oun sọ yii, ki i ṣe oun loun n da sọ ọ, oun ati gbogbo awọn ọmọ NCNC ti wọn jẹ aṣofin ni, ohun ti awọn si pinnu le lori naa ni pe ki ijọba apapọ fi Awolọwọ silẹ, awọn fẹẹ maa ri i nigboro, eyi to ṣe ninu ahamọ to.

Nigba naa ni Akinyẹmi waa tẹ siwaju. O ni, “Ko sẹni ti ko mọ pe Western Region ti wógbá, o bajẹ kọja atunṣe. Ẹni kan ṣoṣo naa to si le tun un ji pada, ẹni to le tun Western Region kọ, ẹni kan naa ti gbogbo awọn eeyan Western Region gba gẹgẹ bii aṣaaju wọn, iyẹn naa si ni Oloye Ọbafẹmi Awolọwọ. Bi awọn eeyan kan ba fẹ, wọn le maa tan ara wọn jẹ o, ṣugbọn gbogbo eeyan pata ni wọn mọ pe ẹgbẹ meji naa lo wa ni West, ẹgbẹ Action gropup (AG) Ẹgbẹ Ọlọpẹ ati ẹgbẹ NCNC, Ẹgbẹ Alakukọ. Ni West, ẹni ti ko ba ṣe AG yoo ṣe NCNC, ẹni ti ko ba ṣe Ọlọpẹ yoo ṣe Alakukọ, ko ju bẹẹ lọ. Bi awọn kan ba waa de lojiji ti wọn n pariwo pe awọn le yi kinni naa pada, wọn n tan ara wọn jẹ lasan ni. Iyẹn lo ṣe jẹ awọn ẹgbẹ mejeeji gbọdọ parapọ bayii, ki wọn ṣe iṣẹ idagbasoke West, ki wọn le ji i pada, Awolọwọ lo si le ṣaaju wa.”

Bo ba jẹ Akinyẹmi nikan lo sọrọ naa ni, awọn eeyan le ro pe ọrọ oṣelu lasan ni, ṣugbọn nigba to jẹ gbogbo ọmọ NCNC nile igbimọ lo sọ ọ, to si jẹ niṣe ni wọn pe ipade awọn oniroyin lati fi sọrọ naa, ti ọpọ awọn aṣofin yii si wa nibẹ, awọn ti wọn gbọ ọ, ti wọn si ri i, mọ pe ọrọ naa ki i ṣe ọrọ Akinyẹmi nikan, paapaa nigba to tun mu ẹnu ba ọrọ awọn ọba ilẹ Yoruba. Akinyẹmi ni awọn ọmọ igbimọ naa ti sọrọ, awọn sọrọ lori awọn ọba ilẹ Yoruba gbogbo. O ni ohun ti awọn pinnu naa ni lati kilọ fun awọn ọba Yoruba, pe bi wọn ti n tẹle Akintọla lẹyin ṣoo ṣoo yii, ki i ṣe ohun ti yoo mu ifọkanbalẹ wa fun wọn lọjọ iwaju o, yoo kan sọ wọn di ẹni yẹyẹ loju awọn eeyan wọn ni. Akinyẹmi ni awọn aṣofin NCNC n kilọ fawọn ọba yii nitori awọn mọ pe ọba ki i ṣe oṣelu, ọba yoowu to ba n ṣe oṣelu yoo fi ara ẹ wọlẹ gbẹyin ni.

Ki lo fa iru ọrọ yii? Ohun to fa a ni pe awọn ọba kan ko ara wọn jọ, wọn ni awọn ni ọba West, wọn si lọọ ba Tafawa Balewa, wọn ni awọn fẹẹ ri i. Ni iyẹn ba fi ọpọlọpọ awọn ohun to n ṣe silẹ, o si ni oun yoo ri wọn. Nigba ti awọn ọba Yoruba naa si ri Balewa, wọn sọrọ fun un. Ọrọ ti wọn sọ fun un jẹ ọrọ ti awọn Fani-Kayọde ti n pariwo lori tẹlifiṣan ati sinu beba, ohun ti wọn si n wi ni pe awọn minisita kan n fiya jẹ awọn ọmọ Yoruba nidii iṣẹ ijọba apapọ, ipo to tọ si wọn, wọn ki i gbe e fun wọn. Balewa beere ẹri, o si jọ pe ẹri gidi kan ko ti ọwọ awọn eeyan naa jade, ahesọ ni wọn gboju le. Ipade naa ko so eso rere kan, bii igba tawọn ọba naa fi akoko ara wọn ṣofo ni, nitori ko jọ pe awọn mi-in ninu wọn mọ idi ti awọn fi lọ. Bawo lawọn ọba Yoruba yoo ṣe lọọ fi ara wọn wọlẹ to bayii, ohun tawọn mi-in n sọ niyẹn.

Igba ti Akinyẹmi ṣẹṣẹ n sọrọ lawọn eeyan too mọ bi ọrọ ipade awọn ọba pẹlu Balewa naa ti jẹ. O ni Akintọla, Fani-Kayọde ati awọn minisita meji kan ni wọn ṣe iṣẹ naa, gbogbo ohun ti awọn ọba naa si sọ nibi ti wọn lọ, awọn yii ni wọn kọ ọ le wọn lọwọ, ti wọn si pin ẹni ti yoo sọ ọrọ naa ati awọn ohun ti wọn yoo sọ.

Akinyẹmi ni iwe ni wọn kọ le wọn lọwọ, o si fi ẹda iwe naa han awọn oniroyin, pe iwe ti wọn ha le awọn ọba lọwọ niyi o, iwe naa si ni awọn ọba fi lọọ jẹ iṣẹ iwọsi bẹẹ lọdọ Balewa, nitori wọn kàn lọ ni, nigba ti wọn de ọhun ni wọn ṣẹṣẹ n kawe ti wọn fun wọn, ki i ṣe ọrọ ẹnu tiwọn ni wọn lọ sibẹ lati lọọ sọ. Iyẹn l’Akinyẹmi ṣe sọ pe nibi ipade awọn, ohun ti awọn fẹnu le lori naa ni pe ki awọn ọba sa ṣọ ara wọn gidi.

Akinyẹmi ni nibo lawọn ọba yii wa nigba ti ijọba Akintọla yọ olukọ agba Yunifasiti Ifẹ kan, Purofẹsọ O. Oyenuga, kuro lẹnu iṣẹ rẹ lojiji. O ni ṣebi awọn ọba yii gbọ pe wọn ti ileewe Ileṣa Grammar School pa lori ẹsun ti wọn ko ri ẹsẹ rẹ fi mulẹ rara. Ọkunrin oloṣelu yii ni o da oun loju pe awọn ọba yii mọ pe Oloye Akintọla ti gba oye ti Kọla Balogun jẹ ni ilu rẹ, Ọtan Ayegbaju, kuro lọwọ rẹ, o si ti fi iyẹn kẹwọ lati le e kuro ni ile igbimọ awọn lọbalọba, bẹẹ ko si ohun meji to fa a ju pe Kọla Balogun ko ba a ṣe ẹgbẹ Dẹmọ lọ. Akinyẹmi sọ nibi ipade iroyin naa pe awọn ọba yii ko le pe awọn ko gbọ ọrọ to ṣẹlẹ si ọkunrin kan ti wọn n pe ni I. Dina, oṣiṣẹ ijọba ti awọn Akintọla fa lulẹ lati ori ipo giga to wa, ti wọn si sọ ọ di ọmọọṣẹ, oun naa ko si ṣe kinni kan ju titori ọmọ ilu to jẹ lọ. Wọn yọ ọ loye rẹ nitori Akintọla koriira Ijẹbu.

Akinyẹmi ko ti i pari ọrọ rẹ pẹlu awọn ọba, o ni ohun ti awọn sọ nipade awọn pọ ju bẹẹ lọ. Ọkunrin naa ni bawọn ọba yii ko ba gbọ gbogbo eyi ti oun ka silẹ yii, wọn ko le sọ pe awọn ko gbọ ti Hubert Ogunde, oṣere ti Akintọla ni ki wọn fi ofin de pe ko gbọdọ ṣere nibikibi nilẹ Yoruba mọ. Akinyẹmi ni gbogbo awọn ọba yii ni wọn mọ Ogunde, ṣe tọọgi ni Ogunde ni abi oloṣelu, ki lo ṣe ti wọn yoo fi gba ọna jijẹ-mimu rẹ lọwọ rẹ, iṣẹ to n ṣe to fi n bọ iyawo ati awọn ọmọ. Ọkunrin ọmọ ile igbimọ aṣofin Western Region yii sọ pe kaka ti awọn ọba fi ba ọrọ ti ko kan wọn, ti wọn ko tilẹ mọ itumọ rẹ lọ si ọdọ Balewa, ṣebi eyi to n ṣẹlẹ nitosi wọn yii lo yẹ ki wọn mojuto, ki wọn ba Akintọla sọrọ idi to fi n ṣe ohun to n ṣe yii si awọn ọmọ Yoruba, nitori gbogbo ohun ti oun n sọ yii, awọn ọmọ Yoruba lo ṣẹlẹ si o.

Akinyẹmi ni, ni ti awọn o, ninu ẹgbẹ NCNC, ipo pataki lawọn to awọn ọba yii si, awọn si ti pinnu pe wọn yoo maa fun wọn ni ọwọ titi aye ni, ṣugbọn ẹbẹ lawọn n bẹ wọn, ki wọn ma jẹ ki awọn ti wọn ko fẹran wọn, to jẹ tara wọn nikan ni wọn mọ lo wọn lati fi wọn rugbo, lori ohun ti ko sọnu ti wọn n wa kiri. Boya nitori pe ipade awọn oniroyin ni Akinyẹmi ti sọ ọrọ naa ni o, tabi pe boya nitori pe o jẹ gbogbo awọn aṣofin NCNC lo sọ ọ, ọrọ naa jo awọn ọba yii lara, awọn mi-in si sọ pe awọn ko ni i ba Akintọla jẹ iru iṣẹ bẹẹ mọ. O kan jẹ pe aṣọ ko ba Ọmọyẹ mọ ni, Ọmọyẹ ti rin ihooho wọja, wọn ko si ba a mọ. Awọn Akintọla ati Fani-Kayọde tilẹ ti sọ fun wọn pada pe ki wọn ma da Akinyẹmi lohun o, jeyinjeyin lo n yọ ọ lẹnu, ko si mọ ohun to n sọ jade lẹnu rara.

Iyẹn ni wọn n sọ lọwọ ti awọn kan fi dide ni ilẹ Ibo lọhun-un, ti wọn ni ki gbogbo ọmọ Naijiria gbadura, ki wọn si gba aawẹ ọlọjọ mẹta nitori Ọbafẹmi Awolọwọ. Awọn Ẹgbẹ Ọmọ Oduduwa ni ilẹ Ibo yii ni wọn kọkọ gbe ọrọ naa jade bẹẹ, bi awọn si ti sọ ọ tan ni awọn eeyan pataki ni ilẹ Ibo naa ba wọn da si i, wọn ni awọn faramọ ọn, ki gbogbo ọmọ Naijiria gba aawẹ ọjọ mẹta nitori Awolọwọ, ko le jade ni ibi to wa ni alaafia, ko si maa ṣe iṣẹ idagbasoke ilu to n ṣe tẹlẹ lọ. Ọrọ naa bi awọn Akintọla ninu, koda, o bi ijọba apapọ naa ninu, bo si jẹ pe wọn ko kede iru ọrọ bẹẹ si gbangba, gbogbo ọna ni wọn n wa lati yiju awọn eeyan kuro nidii iru nnkan bẹẹ, wọn ni kin ni wọn fẹẹ fi aawẹ ṣe, nigba ti ki i ṣe pe nnkan kan ṣe Awolọwọ nibi to wa, ko ṣe àárẹ̀, ko si si laburu kan to ṣe e. Ṣugbọn awọn Akintọla lọrọ naa ka lara ju, nitori bi wọn ti fẹẹ pana orukọ Awolọwọ yii, bẹẹ ni orukọ naa n ba ibomiiran jade.

Eyi to tilẹ wa nilẹ ti wọn ko ti i ri ibi yanju ẹ ni ọrọ ti Ileṣa Grammar School, nitori kaka ki kinni naa mu oore wa, tabi ko mu awọn eeyan bẹru ijọba Akintọla, tabi ko mu ki wọn fẹran rẹ, ọta ati afojudi lo tubọ mu wa si i. Ohun to si fa a ko ju pe o ti han pe gbogbo ohun tawọn Akintọla sọ, gbogbo ohun ti wọn ni wọn ri, gbogbo awọn ti wọn darukọ nidii ọrọ yii, ofege lasan ni. Loootọ ni igbimọ ti wọn gbe dide yii lọ lati gbọ ẹjọ ẹnu awọn eeyan, ti wọn fẹẹ wadii ohun to ṣẹlẹ gan-an, ṣugbọn ohun tawọn igbimọ naa ro kọ ni wọn tọ wo. Rẹfurẹni Akinyẹmi ti wọn n pariwo orukọ ẹ pe oun lo da wahala silẹ gẹgẹ bii olukọ agba ko ti i de lati Eko, ko si nile ki wọn too ṣe ọdun ere idaraya ti wọn ṣe, ko si ti i pada de lati igba naa. Ko mọ bi ọrọ ti ṣẹlẹ, nitori ẹ, ko sẹni to le pe e pe ko waa rojọ kan. Ko si eyi to kan an ninu ọrọ naa rara.

Bẹẹ oun gangan lawọn Akintọla fẹẹ mu, wọn fẹẹ fi ọrọ naa kẹwọ ki wọn le ọga ileewe yii danu lẹnu iṣẹ ijọba, ki wọn ni ki Rẹfurẹni Akinyẹmi maa lọ sile nitori pe o hu awọn iwa kan ti ko dara. Ṣugbọn ofo, ọjọ keji ọja, lọrọ naa jẹ fun wọn, wọn ko ri Akinyẹmi Pirinsipa mu, ọrọ naa si di itiju, nitori aṣiri ti tu bayii pe olukọ agba naa ni wọn fẹẹ mu. Lọna keji, awọn ọmọleewe funra wọn wa siwaju igbimọ yii, awọn mẹjọ ni wọn si wa sibẹ, ẹri kan naa lo si tẹnu awọn mẹjẹẹjọ jade. Wọn ni awọn ri ọkunrin onirungbọn kan to ti wa niwaju ileewe wọn tipẹ, aṣọ buba ati ṣokoto lo wọ, awọn o si mọ ohun to n wa, igba ti rogbodiyan bẹrẹ lawọn ri i pe o wa lara awọn ti wọn n fa wahala nibẹ, nigba ti awọn si jade lati woran, awọn tun ri ọkunrin naa to wọ mọto kan to n lọ, awọn ko mọ orukọ rẹ, ṣugbọn awọn mọ pe o wa ninu awọn to fajangbọn naa.

Ijọba Akintọla ko fẹ ki ọrọ naa le ju bẹẹ lọ, ohun to si fa a niyi to jẹ pẹlu pe igbimọ naa n ṣe iwadii wọn lọwọ, ijọba fi itiju ṣi ileewe naa pada, wọn ni awọn ọmọ Ileṣa kan ni wọn waa bẹ awọn. Mọnde, ọjọ kẹfa,, oṣu kẹrin, ni wọn ti ileewe naa, Tọsidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu kẹrin, ni wọn ṣi i. Ṣugbọn ṣiṣi ti wọn ṣi ileewe naa ko da ohun to wa nilẹ tẹlẹ duro o, nitori niṣe lo da bii pe ija ṣẹṣẹ bẹrẹ laarin ẹgbẹ Dẹmọ ti i ṣe ẹgbẹ awọn Akintọla, ati Ẹgbẹ NCNC, pẹlu Ẹgbẹ Ọlọpẹ. Bi Dẹmọ ti n leri, bẹẹ ni NCNC n leri, ẹgbẹ AG ati NCNC si kọ̀, wọn ni awọn ko ni i sun, afi lọjọ ti Akintọla ba kuro lori aga ijọba.

(34)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.