Wọn ṣa alagba ijọ Sẹlẹ pa niluu Eko

Spread the love

Lọwọlọwọ bayii, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ṣi n ṣewadii ohun to le fa ki awọn agbanipa kan lọọ ka alagba ijọ Sẹlẹ, Ẹnfanjẹliisi Peter Kọlawọle Gandaho, mọle, ki wọn si gbẹmi rẹ.

Iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ to lọ lọhun-un, laduugbo Ajah, niluu Eko.

Kọlawọle ni alagba ijọ Sẹlẹ Ileri Ayọ, to wa ni Eti-Ọsa. Niṣe ni wọn ni awọn agbebọn naa ṣadeede ya wọ ile rẹ laaarọ ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ to lọ lọhun-un, ni nnkan bii aago mẹrin aarọ, ti wọn si pa a.

Nigba ti awọn ọmọ ijọ ko ri Oluṣọ ko jade waa ṣe isin fun wọn ni wọn lọ sile rẹ, ṣugbọn oku rẹ ni wọn ba.

Gẹgẹ bi iwadii ileeṣẹ ọlọpaa ṣe sọ, wọn ni o ṣee ṣe ko jẹ pe baba naa ti ṣẹ awọn kan ninu iwaasu rẹ, ṣugbọn wọn ko ti i fidi ohun to le mu ki wọn ṣa a pa mulẹ.

Gandaho ni alaga awọn igbimọ ajinhinrere, Area B, niluu Eko ko too di pe o ku.

Mọṣuari ni oku rẹ ṣi wa, awọn ọlọpaa ṣi n tẹsiwaju lori iwadii wọn.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, Chike Oti, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, Gẹgẹ bo ṣe ṣalaye, o ni ọwọ awọn ọlọpaa ti tẹ afurasi meji lori iṣẹlẹ yii, wọn si ti ko wọn lọ si ẹka to n ṣewadii iwa ọdaran ni Panti, Yaba, fun iwadii to peye.

Oti sọ pe ni nnkan bii aago mẹrin idaji ọjọ keji, oṣu yii, niṣẹlẹ naa ṣẹlẹ. O ni nigba ti iroyin tẹ ileeṣẹ ọlọpaa lọwọ, awọn ọlọpaa teṣan Ajah lọ si ibi iṣẹlẹ naa, ọwọ si tẹ awọn afurasi meji. O ni awọn gbe Oluṣọ naa lọ si ọsibitu, ṣugbọn ibẹ lo pada ku si.

 

(3)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.