Wolii Wale Ọlagunju (Ijọ Divine Seed of God Chapel Ministries, Sasa, Ibadan)

Spread the love

-Ọlọrun fi han mi pe ọpọlọpọ awọn iranṣẹ Ọlọrun ti yapa kuro ni ilana ti a fi pe wọn fun iṣẹ iranṣẹ, wọn ti gbe owo si ipo to yẹ ki wọn fi Ọlọrun si. Ọlọrun sọ pe awọn ileejọsin ni Naijiria ti di ibujokoo fun iwa ibajẹ loniran-n-ran.

-Nitori idi eyi, Ọlọrun sọ pe oun maa yọ si awọn ijọ bẹẹ láì-rò-tì.

 

-Ki gbogbo ọmọ Naijiria kun fun adura fun Buhari nitori aisan ojiji to le la iku lọ.

 

-Ọlọrun sọ pe idojuti ni Buhari jẹ, oun si ti wa ẹlomin-in rọpo rẹ ninu ọkan oun.

 

-Ọlọrun yoo fi han Buhari pe oun ti pada lẹyin rẹ, apẹẹrẹ ti Ọlọrun si maa fi han an ni pe awọn ọmọ iya ẹ l’Oke Ọya yoo maa bi patako ipolongo rẹ wo lulẹ lọdọ wọn lọhun-un.

 

-Ọlọrun sọ pe oun ki i ṣiṣẹ oun ni ibamu pẹlu ero ọkan ọmọ eniyan bi ko ṣe nipa aṣẹ ọrọ Oun funra oun. Bo ti wu ki eeyan jẹ ẹlẹṣẹ to, ko si ẹni ti Oun ko le lo lati mu erongba oun ṣẹ lawujọ awọn eniyan. Ni bayii, ọna to ja si ori itẹ ijọba Naijiria ni Aso Rock ti ṣi silẹ fun Atiku bayii, nitori Ọlọrun ti pinnu lati fi Atiku ẹlẹṣẹ rọpo Buhari.

 

-Awọn ọmọlẹyin Atiku ni lati fi ọjọ kan silẹ fun aawẹ ati adura lati ṣẹgun ojooro ibo naa.

 

-Ipinlẹ mẹẹẹdọgbọn (25), ni Atiku yoo ti ni ibo to pọ daadaa ju awọn oludije yooku fun ipo aarẹ lọ.

 

-Ki Atiku kun fun adura lati re ogun aisan danu, ki iru ohun to ṣẹlẹ si Baṣọrun M.K.O. Abiọla ma si ṣẹlẹ si i.

 

-Ki Tinubu beere fun oju rere Ọlọrun, bi bẹẹ kọ, ẹgbẹ oṣelu PDP yoo gba ipinlẹ Eko ninu idibo aarẹ ọdun yii.

 

-Sanwoolu, oludije fun ipo gomina ipinlẹ Eko labẹ ẹgbẹ oṣelu APC naa yoo pada koju iṣoro ẹ nigbẹyin.

 

-A fi han mi pe ki awọn eeyan ma ṣe gbara le Atiku paapaa ju, nitori oun kọ ni Mose naa ti yoo ko awọn ọmọ Naijiria kuro lati oko ẹru de ilẹ ileri, Ọlọrun kan fẹẹ lo o lati ṣatunṣe si awọn aiṣedeede kan ti ijọba Buhari ti ṣe lasan ni.

 

-Ki ẹgbẹ oṣelu PDP ṣe pẹlẹpẹlẹ, bi bẹẹ kọ, wọn maa ko sinu pampẹ ti ẹgbẹ APC ti dẹ silẹ de wọn.

 

-Naijiria yoo fọ si wẹwẹ laipẹ, lasiko ti Ọlọrun funra rẹ ti kọ silẹ.

 

-A fi han mi pe ẹnikẹni to ba ti ṣe aarẹ ologun sẹyin ko tun ni i de ipo aarẹ nilẹ yii mọ.

 

-Ki awọn ọmọ orileede yii kun fun adura, ki eto idibo yii ma jẹ eyi ti yoo kun fun idarudapọ to buru julọ ninu itan orileede yii.

 

-Igbiyanju lati yi ibo ọdun yii yoo la wahala lọ, yoo si da Naijiria pada si iru rukerudo to ṣẹlẹ lasiko ijọba Aarẹ Ologun Sani Abacha.

 

-Awọn ẹgbẹ oṣelu to wa lori ijọba atawọn alatako yoo mu ọrọ idibo ọdun yii bii bo-o-ba-a-o-pa-a.

-Gẹgẹ bii asọtẹlẹ mi lọdun 2016, iṣẹ iyanu Ọlọrun to lagbara nikan lo maa jẹ ki Bukọla Saraki pari saa rẹ gẹgẹ bii aarẹ ileegbimọ aṣofin agba. Ki oun atawọn alatilẹyin rẹ si kun fun adura ki Saraki ma ṣe rogun awọn agbanipa.

 

-Ti oludije fun ipo gomina ni ipinlẹ Ekiti ati Ọṣun lorukọ ẹgbẹ oṣelu PDP ba le wa oju rere Ọlọrun daadaa, Ọlọrun maa tu aṣiri awọn aiṣedeede to wa ninu idibo gomina ipinlẹ wọn, a o si gba iṣakoso naa le wọn lọwọ.

 

-Ki awọn oṣere ni Naijiria kun fun adura nitori ajalu ojiji.

 

-Gẹgẹ bi Ọlọrun ṣe fi han mi pe Buhari lo maa wọle idibo aarẹ̣ lọdun 2015, a ti tun fi han mi pe Buhari kọ ni wọn yoo bura fun gẹgẹ bii aarẹ tuntun lorileede yii lọjọ kọkandinlọgbọn (29), oṣu karun-un, ọdun 2019 yii. Ọlọrun gbe Buhari sipo yẹn lasiko to wu u, O si ti yọ ọ nipo naa bayii.

 

-Ọkan ninu awọn eeyan ti a n wo gẹgẹ bii igi nla maa wo lulẹ.

 

-Ki awọn eeyan kun fun adura gidigidi fun Babangida ati Ọbasanjọ.

 

 

 

(11)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.