Wọle Ṣoyinka sọrọ, o tun powe

Spread the love

Agbalagba n to sọrọ to n laagun, ẹkun lo n sun, nitori nibi ti ọrọ naa ka a lara de ni. Ọrọ Naijiria yii mu Ọjọgbọn Wọle Ṣoyinka laya, ọrọ naa si da bii pe o ti kọja ẹkun, ẹrin lo ku to fi n rin. Wọle Ṣoyinka loun ko ni i dibo fẹnikan, boya Buhari ni o, boya Atiku ni o, o ni oun ko ri ẹni ti yoo ṣe Naijiria loore kan ninu awọn mejeeji, oun ko ri ẹni ti ijọba rẹ yoo ko mẹkunnu yọ ninu ewu. Ṣoyinka ko fi igba kankan fẹran ẹgbẹ PDP, ko si fi bo pe ẹgbẹ awọn ole ni. Ṣugbọn o fẹran APC, lati aye awọn AC, titi di ACN lo ti fẹran wọn, pẹlu ironu pe ẹgbẹ naa yoo ṣe mẹkunnu loore. Ki i ṣe pe o gba nnkan kan lọwọ wọn lo ṣe fẹran wọn, ṣugbọn pe ẹgbẹ ti oun ro pe o le mu daadaa ba Naijiria ni. Ni ọdun mẹrin sẹyin, iyẹn nigba ti Buhari fẹẹ du ipo to wa loni-in yii, bi Ṣoyinka ko tilẹ sọrọ jade, o wa ninu awọn ti wọn ṣe atilẹyin fun un, o si daju pe Buhari ni yoo dibo rẹ fun, nitori ọkan ninu awọn to koriira ijọba Jonathan toju-timu ni. Fun Soyinka loni-in lati waa sọ pe oun ko ni i dibo, ọrọ naa tobi ju bo ti sọ ọ lọ. Bẹẹ o sọ bẹẹ, o wi bẹẹ, nibi ipade apero ti 2019 Citizen Forum, ti wọn ṣe l’Ekoo, l’Ọjọbọ, Alamisi, ọsẹ to kọja, o si tẹnu mọ ọn pe oun ko fẹ ki awọn eeyan ṣi oun gbọ, ohun ti oun sọ loun sọ, oun ko ni i dibo fun Buhari tabi Atiku, nitori oun ko le dibo fun APC tabi PDP, ẹgbẹ to yẹ ki gbogbo ilu kọ silẹ lawọn mejeeji. Itumọ eyi ni pe nnkan ko dara, kinni naa ko sunwọn lasiko awọn Buhari yii, ohun to n ṣẹlẹ nidii eto ọrọ-aje ko ṣee maa fẹnu sọ. Ẹni ti ẹ ba ri to ba ni nnkan oun rọgbọ, tabi pe bi nnkan oun ṣe wa lọdun 2016 lo wa daadaa lọdun yii, tọhun n mu nnkan mi-in mọ ọn ni, ka ṣiṣẹ diẹ, ka fi biribiri pupọ kun un ni. Ṣugbọn to ba jẹ ojulowo iṣẹ ẹda ni, gbogbo iṣẹ ni ifasẹyin ti ba, gbogbo ọlọja lo n kerora nitori awọn eeyan ko ra ọja wọn ni. Eyi fihan pe gbogbo ohun ti awọn eeyan reti pe Buhari yoo ṣe ni ko ṣe, ohun to jẹ ki iru awọn bii Ṣoyinka pada sẹyin ree, to fi di pe baba naa loun ko ni i dibo fẹnikan. Lati bii oṣu mẹta sẹyin bayii, ko si iṣẹ gidi kan ti ijọba n ṣe mọ, ọrọ oṣelu yii ati kampeeni ṣaa ni. Bẹẹ bi Naijiria yii yoo ba dara, afi kawọn aṣaaju wa ṣe daadaa. Eyi ni Buhari gbọdọ gbe yẹwo funra rẹ, ko mọ pe nigba ti oun fẹẹ wọle ni 2015, ki i ṣe pẹlu agidi, awọn araalu lo dibo foun. Ko ṣe daadaa kawọn araalu tun le dibo wọn fun un lasiko yii, nitori bi wọn ko ba dibo fun un to ba jẹ ojooro ati eru lo fi wọle, ori awọn mẹkunnu yoo pada da a lẹbi ni. Bi Naijiria yii yoo ba dara, afi kawọn aṣaaju wa ṣe daadaa.

 

(8)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.