Wọn ni Shittu, minisita Buhari, tun ṣe magomago owo-ori *Bee lo ko eru kuro nile ipolongo ibo to gba nitori Buhari Ọlawale Ajao, Ibadan

Spread the love

Lẹyin bii oṣu meji ti Minisita fun eto Ibanisọrọ lorileede yii, Amofin Adebayọ Shittu, padanu anfaani lati le dije dupo gomina ipinlẹ Ọyọ lorukọ ẹgbẹ oṣelu APC nitori ti ko ṣe agunbanirọ lati ṣiṣẹ sin ilẹ baba rẹ, ẹnu ti tun n kun un bayii, wọn lọkunrin naa ki i sanwo-ori deede sapo ijọba, iyẹn ni pe ki i ṣe ojuṣe ẹ si ijọba gẹgẹ bii ọmọ Naijiria rere.

Gẹgẹ bii ofin orileede yii ati nibi gbogbo kaakiri agbaye, ọran-an-yan ni fun gbogbo araalu lati maa sanwo ori, paapaa, awọn to ba ni ileeṣẹ to n mowo wọle fun wọn ninu ilu naa. Idi ree ti Yoruba fi maa n pa a lowe pe dandan lowo-ori. Bi eeyan ba ṣe ni dukia to ni yoo ṣe maa sanwo-ori to. Ki eeyan si too le di ipo pataki mu ninu ijọba, ẹni naa gbọdọ jẹ ẹni to n sanwo-ori deede, paapaa, ọdun mẹta ṣaaju asiko to fẹẹ dipo oṣelu mu. Idi ree ti awọn ti ki i sanwo-ori tẹlẹ ṣe maa n sare san gbogbo eyi to yẹ ki wọn ti san sẹyin lasiko ti wọn ba n lakaka lati dupo oṣelu. Bi bẹẹ kọ, oluwarẹ ko lẹtọọ si ipo adari ninu ijọba.

Wọn ni nigba ti Amofin Shittu naa fẹ dupo gomina ọdun 2015 loun naa sare lọọ sanwo-ori diẹ, risiiti owo ọhun lo si fi silẹ niwaju igbimọ awọn aṣofin ti wọn ṣayẹwo rẹ lati mọ boya ipo minisita tọ si i. Bawo waa lọrọ owo-ori to ti san lati ọdun 2014 ṣe tun di iroyin lasiko yii, wọn ni kinni naa lọwọ kan magomago ninu nitori ẹgbẹrun marun-un Naira pere lo san gẹgẹ bii owo-ori fun odidi ọdun mẹta.

Ki wọn too le fi eeyan ṣe minisita ninu ijọba apapọ ilẹ yii, awọn ọmọ ileegbimọ aṣofin apapọ gbọdọ kọkọ ṣayẹwo iru eeyan bẹẹ daadaa. Lara nnkan ti wọn yoo si wo mọ onitọhun lara ni iwe ẹri, akọsilẹ dukia ẹni naa pẹlu iwe akọsilẹ awọn owo-ori to ti san sapo ijọba sẹyin titi di asiko naa.

Ninu iwe akọsilẹ dukia ti Shittu fi ranṣẹ si awọn aṣofin, ileeṣẹ epo kan to n jẹ Al-Furqaan Petro-Gas & Gen. Services Ltd pẹlu ileewe aladaani kan ni wọn lo sọ pe oun ni. Ṣugbọn nigba ti yoo fi iwe owo-ori to san laarin ọdun mẹta silẹ, ẹgbẹrun marun-un Naira pere lo wa ninu ẹ, iyẹn ni pe ẹgbẹrun marun-un yii ni gbogbo owo to san sapo ijọba, eyi to kere pupọ ju si iye owo-ori to yẹ ko maa san lori awọn dukia olowo iyebiye to ni wọnyi.

Awọn to tọpinpin Shittu lori ẹsun yii sọ pe ninu gbogbo awọn to n ṣe minisita lọwọ ninu ijọba Aarẹ Buhari, Shittu nikan lo san owo-ori to kere ju bo ṣe yẹ lọ. Nibi ti oun ti san ẹgbẹrun marun-un Naira laarin odidi ọdun mẹta, owo to jọju lawọn akẹgbẹ ẹ ti wọn jọ fẹẹ fi ṣe minisita nigba naa san ṣaaju asiko iyansipo na. Diẹ ninu wọn ni ti Okechukwu Enelamah, ẹni ti owo-ori to san laarin ọdun 2012 si 2014 jẹ miliọnu mẹjọ Naira, ka ma ṣẹṣẹ ti i sọ tawọn to sanwo nla bii Sẹnitọ Ibe Kachikwu, ẹni to san miliọnu mejilelaaadọta ati ẹgbẹrun lọna ọgọrin Naira (N52.8m) gẹgẹ bii owo-ori ẹ laarin ọdun mẹta bakan naa.

Ninu iweeroyin oloyinbo kan to kọkọ gbe iroyin yii, wọn ni ohun iyanu lo jẹ pe awọn aṣofin paapaa faaye gba Shittu lati jẹ minisita pẹlu bi ko ṣe ṣiṣẹ kankan sin ilẹ baba rẹ, ti ko si tun ṣe ojuṣe rẹ fun ijoba pẹlu sisan owo-ori deede gẹgẹ bi ofin Naijiria ṣe la a kalẹ.

Wọn ni nigba to di ki kaluku maa sọ dukia to ni, gaga lara Shittu ya lati maa tọka si i pe oun loun nileeṣẹ eleyii, oun loun da tọhun silẹ, ṣugbọn nigba to di ibi owo-ori lọkunrin naa gbe risiiti owo ti ko ṣee maa gbọ seti silẹ. Bẹẹ, gẹgẹ bii akọsilẹ ti ọkunrin naa gbe siwaju awọn aṣofin, lati ọdun 2000 lo sọ pe oun ti da ileeṣẹ epo silẹ, ki i ṣe pe o ṣẹṣẹ da a silẹ debii pe kinni ọhun ko ti i maa mowo gidi wa fun un.

Ẹda risiiti ti wọn ni Shittu fi sanwo-ori ọhun tẹ akọroyin wa lọwọ. Ṣugbọn kinni kan to ṣe ni ni kayeefi lori risiiti ọhun ni pe ileeṣẹ to n mojuto agbekalẹ ati idagbasoke awọn ilu nla nla fun ijọba ipinlẹ Ọyọ ni minisita yii sanwo ọhun si ninu oṣu kẹta, ọdun 2014, ki i ṣe ileeṣẹ to n gbowo-ori sapo ijọba ipinlẹ naa.

Akọroyin wa pe Shittu lati gbọ awijare ẹ lori ẹsun yii, o ni ẹsun ti ko lẹsẹ nilẹ ara ni wọn fi kan oun yii, ati pe awọn ọta oun nidii oṣelu lo wa nidii ọran naa.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Ẹyin oniroyin ni lati maa ṣewadii daadaa kẹ ẹ too maa gbe iroyin jade. Ṣebi ileeṣẹ to n gba-owo ori fun ijọba wa lọtọ, ṣe ileeṣẹ to n ri si idagbasoke awọn ilu nla nla lo tun n gba owo-ori ni. Ti iwọ naa ba ri risiiti ti mo fi san owo ti wọn n sọ yẹn, wa aa ri i pe ileeṣẹ to n ri si idagbasoke ilu lo wa nibẹ, nigba wo lawọn yẹn di ẹni to n gbowo ori. Ile kan ti mo kọ nigba naa ni mo sanwo yẹn fun, ki i ṣe owo-ori rara.

‘‘Mo si le fi gbogbo ẹnu sọ ọ pe mo n sanwo-ori mi sibi to yẹ. Ṣugbọn wọn o le maa fi owo-ori ti iru emi yii n san we ẹni to jẹ pe ileeṣẹ epo Shell lo ti n ṣiṣẹ ko too gba ipo oṣelu, ẹni to jẹ pe o lagbara lati maa san ọkẹ aimọye miliọnu gẹgẹ bii owo-ori. Mo si fẹ kẹ ẹ mọ pe ileeṣẹ to n gba owo-ori lo maa sọ iye ti eeyan gbọdọ san gẹgẹ bii owo ori, ki i ṣe eeyan ni yoo sọ fun wọn pe iye bayii loun maa san. Wọn maa n bu owo yẹn le eeyan ni ibamu pẹlu bi dukia rẹ ba ṣe pọ to ni.”

Ninu iroyin mi-in, pẹlu gbogbo ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ati ariwo ti Amofin Shittu ti n pa lati ọjọ yii wa pe oun loun yoo ṣaaju ipolongo ibo fun Aarẹ Buhari ati igbakeji rẹ, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, ninu idibo ọdun 2019 ki wọn le ṣe saa keji nipo, o jọ pe minisita yii ti tun ero ara rẹ pa lori ọrọ naa.

Idi ni pe ile pẹtẹẹsi nla kan ti ọkunrin naa ti rẹnti si adugbo Mọkọla, n’Ibadan lati ibẹrẹ ọdun yii, niṣe lo deede ko gbogbo ẹru inu ẹ kuro, o si daju ṣaka pe ọkunrin naa ko lo ile ọhun fun ipolongo Buhari mọ.

Ko ju ọsẹ mẹta lọ lẹyin ti ẹgbẹ APC ko fun Amofin Shittu lanfaani lati dupo gomina lo ti kọkọ ko gbogbo aga atawọn nnkan to ti ko sinu ile naa lati lo fun ipolongo fun saa keji Aarẹ Buhari ati igbakeji ẹ, atunṣe rampẹ lawọn eeyan si kọkọ ro pe o fẹẹ sẹ ṣe si ọfiisi naa, afi lọsẹ to kọja, nigba ti wọn deede kọ (to lease) si ara ile naa, eyi to tumọ si pe wọn fẹẹ fi i rẹnti fun ẹnikẹni to ba ti le sanwo ẹ.

Ohun ti awọn eeyan n sọ nipa igbesẹ yii ni pe nitori bi Buhari ko ṣe gba Shittu silẹ nigba ti igbimọ amuṣẹya ẹgbẹ oṣelu APC yẹgi mọ ọn nidii lati dupo gomina ninu idibo ọdun to n bọ loun paapaa fi jawọ ninu wahala ipolongo fun saa keji Buhari.

Nigba to n fun akọroyin wa lesi lori iroyin yii, minisita fun eto ibanisọrọ sọ pe oun ko figba kankan pada lẹyin Aarẹ Buhari, ṣugbọn agbara oun ko ka owo rẹpẹtẹ ti awọn to ni ile nla ti oun n lo fun ọfiisi ipolongo ibo Aarẹ yii fẹẹ gba mọ loun ṣe káàásá oun kuro ninu ẹ.

(25)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.