Wọn le Ọdunayọ kuro lẹnu iṣẹ ọlọpaa, lo ba n jale kiri n’Ibadan

Spread the love

Lẹyin to ti fi aṣọ ọlọpaa jale, to si ti lu ọkẹ aimọye eeyan ni jibiti fodidi oṣu mẹfa, ọwọ awọn ojulowo ọlọpaa tẹ ayederu ọlọpaa kan, Ayọbami Ọdunayọ, n’Ibadan.
Ọdunayọ yii ni wọn lo ti ṣiṣẹ ọlọpaa ri ko too di pe wọn le e danu lẹnu iṣẹ naa nigba to n huwa to n ba ileeṣẹ yii loju jẹ. Ṣugbọn niṣe lo kọ lati wa iṣẹ gidi mi-in ṣe, to si bẹrẹ si i jale, to n gbowo kiri lọwọ awọn onimọto nigboro Ibadan pẹlu aṣọ iṣẹ rẹ atijọ.
Awọn iṣesi to lodi si iṣẹ agbofinro bii ka gba abẹtẹlẹ lọwọ awọn afurasi ọdaran, bii ka gbe are fẹlẹbi lo jẹ ki wọn le e danu nigba naa ko ma fi tiẹ ba tiwọn jẹ.
Aye ti awọn ojulowo agbofinro mi-in ki i jẹ paapaa lobinrin ẹni ọdun mejidinlogoji (38) naa n jẹ pẹlu bo ṣe maa n wọ mọto ọfẹ kaakiri igboro Ibadan nitori to wọsọ ọlọpaa sọrun.
ALAROYE gbọ pe nitori aye ijẹkujẹ to dun mọ ọn yii lo mu un fi ami idanimọ ipo ASP lẹnu iṣẹ ọlọpaa si ara aṣọ rẹ, bo tilẹ jẹ pe ipo kọburu, eyi to kere jọjọ si ipo ASP to n pera ẹ yii lo wa ti wọn fi le e danu lẹnu iṣẹ. O jọ pe awọn ole nla nla to n ja atawọn jibiti to n lu awọn eeyan kiri igboro naa lo n lo gẹgẹ bii ohun amuyẹ lati ṣe agbega funra ẹ gẹgẹ bii ẹni to mura siṣẹ.
Gẹgẹ bi ọga agba ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CP Abiọdun Odude, ṣe fidi ẹ mulẹ fawọn oniroyin n’Ibadan, lọjọ kẹrin, oṣu kẹta, ọdun yii, l’Ọdunayọ dibọn bii ẹni to fẹẹ ra aṣọ ni ileetaja nla kan ni Bodija, n’Ibadan, to si ji owo ati ẹrọ ibanisọrọ laarin ka diju ka la a.
Ẹgbẹrun marun-un naira ati ẹrọ ibanisọrọ kan ti wọn n pe ni Gione ti owo ẹ to ẹgbẹrun lọna ọgọrin naira (N80,000), to jẹ ti ọkunrin oniṣowo naa ni jagunlabi ji mu sọ sapo lai beṣu bẹgba.
Bakan naa ni wọn lo ji pọọsi onipọọsi ninu ṣọọbu kan laduugbo Moniya, n’Ibadan, to si ṣe bẹẹ gbe foonu ati ẹgbẹrun mẹẹẹdogun naira ti onitọhun ti pa nidii ọja rẹ lataarọ lọ.
Ole to ja ni Bodija leyi to ṣe gbẹyin tọwọ awọn agbofinro teṣan Agodi fi tẹ ẹ. Iwadii ti wọn ṣe siwaju nipa obinrin naa fidi ẹ mulẹ pe o ti gbówọ́ ninu iṣẹ ibi.
Kaadi idanimọ meji ọtọọtọ, ti ọkan jẹ ti sajẹnti ọlọpaa, ti ekeji si jẹ ti ripẹtọ ati bẹliiti pẹlu aṣọ ọlọpaa loriṣiiriṣii lawọn agbofinro ba ninu ile ẹ.
Ọdunayọ, ẹni to ti bimọ meji lai si nile ọkọ fidi ẹ mulẹ pe lati ọdun mẹfa sẹyin ni wọn ti le oun kuro lẹnu iṣẹ ọlọpaa nigba ti awọn afurasi ọdaran ti awọn ti mọnu ahamọ sa lọ mọ oun lọwọ, ati pe awọn ounjẹ tutu bii irẹsi, ẹwa, gaari ati bẹẹ bẹẹ lọ loun n ta lati igba naa.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, ”Mi o fi iṣẹ ọlọpaa jale, emi pẹlu obinrin kan la jọ ja. Ẹni yẹn lo fẹjọ mi sun ni teṣan ti wọn fi mu mi.”
O ni, ko si ohun to le dun mọ oun ninu bii ki oun tun lanfaani lati ṣiṣẹ ọlọpaa lẹẹkan si i, nitori iṣẹ naa ṣi wu oun i ṣe.
CP Odude gba gbogbo ọmọ Naijiria niyanju lati maa kiyesara nigba ti wọn ba ṣalabaapade ọlọpaa ti iṣẹsi ẹ yatọ si ti ojulowo agbofinro.

(22)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.