Were o mọ pe ohun to n ṣe oun ko daa

Spread the love

Awọn Yoruba ni wọn maa n pa owe pe were ko mọ pe ohun ti n ṣe oun ko dara, nitori lọjọ ti were ba mọ pe ohun to n ṣe oun ko dara, lọjọ naa ni ko ni i ṣe were mọ, lọjọ naa ni ohun to n ṣe e ti pin, ti igbadun si de ba a. Ọrọ awọn aṣofin Naijiria leeyan yoo ro debẹ, o n lọ si bii ọdun mẹrin bayii ti wọn ti n jokoo nile igbimọ aṣofin agba yii to jẹ ojumo kan, ija kan ni, wọn ko ri ofin gidi kan ṣe, wọn ko si ba ijọba apapọ ṣọrẹ. Bi wọn ko ja nitori ọrọ owo, wọn yoo ja nitori ọrọ ofin, ko si si ọmọ Naijiria to le sọ pe oun gbadun wọn. Ojuṣe aṣofin orilẹ-ede ni lati ṣe ofin ti yoo mu ilọsiwaju wa, ofin ti yoo mu idagbasoke ba ilu ti yoo si mu nnkan gbogbo dara. Bi aṣofin ko ba ti le ṣofin idagbasoke, tabi ti awọn ile aṣofin kan ba wa ti awọn ati awọn ti wọn n ṣejọba ko ba le jọ ṣiṣẹ papọ, ilọsiwaju kan ko le ba iru orilẹ-ede bẹẹ, ina wọn yoo maa jo ajorẹyin ni. Lara ohun to n ko aburu ba wa lati ọjọ yii wa ree, nitori awọn aṣofin wa ati Aarẹ Muhammadu Buhari pẹlu awọn eeyan rẹ ko ni ajọṣe gidi kan ti wọn jọ n ṣe, ija loni-in, asọ lọla ni. Bi awọn aṣofin ṣe ofin, Buhari ko ni i tẹle e, bi oun naa si gbe iwe kan de ọdọ wọn, awọn naa ko ni i fọwọ si i, wọn si ṣe bii ere bii ere, wọn ba gbogbo ilẹ yii jẹ, wọn ko si mu nnkan ilọsiwaju kan ba wa. Ṣugbọn ni bayii ti ọkan ninu awọn oniwahala ile-igbimọ yii, Sẹnetọ Ali Ndume, ti sọ pe awọn ti ṣetan lati ṣiṣẹ pọ bayii, to ni awọn ti jọ sọrọ lati ma ba ara awọn ja mọ, a jẹ pe ka ronu pe nnkan daadaa yoo bẹrẹ si i ṣẹlẹ lati ile-igbimọ aṣofin. Ṣugbọn njẹ wọn le ṣiṣẹ owo Naijiria ti wọn ti fi ṣofo bayii, tabi wọn yoo da owo ti wọn gba pada fun wa ni. Gbogbo bi wọn ṣe n ba ara wọn ja, ti wọn n fa wahala, ti wọn si n di ilọsiwaju wa lọwọ, wọn ko ba ara wọn ja debi owo, wọn n gba owo lọ, koda, gbogbo alawansi to ba tọ si wọn ni wọn n gba, igba ti wọn ba nawo tan ni wọn yoo bẹrẹ wahala, ti wọn yoo si ko si mọto ti wọn fowo araalu ra fun wọn, ti wọn yoo gba ibi ti wọn ba fẹ lọ. Awọn aṣofin yii ti ba nnkan jẹ, ṣugbọn ka dupẹ pe were ti mọ pe ohun to n ṣe oun ko dara bayii, ka fọkan si i pe awọn eeyan naa yoo ṣejọba daadaa. Bi ọrọ wọn ko ba si tẹ wa lọrun, ka fi ibo le wọn danu ni adugbo yoowu ti wọn ti wa, ki wọn pada si ile wọn ki wọn kan yee nawo ijọba jẹ lasan. Oniranu lo pọ ninu wọn o jare.

 

(3)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.