Were ṣa ọlọpaa ati baba agbalagba pa labule Onipẹtẹẹsi l’Ondo

Spread the love

Aarọ ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja ni nnkan daru labule Onipẹtẹsi, nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ondo, nigba ti ọkunrin kan ti wọn n pe ni ‘At all at all’, deede fa ada yọ, to si ṣa baba ẹni ọdun marundinlọgọrin pa.
Gẹgẹ bi iwadii ta a ṣe, ipinlẹ Delta ni wọn lọkunrin alaaganna yii ti wa si abule naa, nibẹ lo si ti n ṣiṣẹ. A ri i gbọ pe abule Ọrin ni ọkunrin naa kọkọ de si, ṣugbọn nigba ti awọn eeyan agbegbe naa ṣakiyesi pe ko jọ were, ko jọ ẹni ti ara rẹ ko ya ni i ṣe ni wọn fi le e kuro labule naa. Wọn ni ọkunrin naa ki i saaba ba eeyan sọrọ, ṣe lo maa n kun yunmu-yunmu, bẹẹ ko si ẹni to maa n gbọ nnkan to n sọ. Nitori idi eyi ni wọn fi le e kuro labule naa, to si fi di ara abule Onipẹtẹẹsi, nibẹ lo si ti tun bẹrẹ iṣẹ mi-in, iyẹn iṣẹ akọpẹ.
Ohun tawọn eeyan abule Onipẹtẹsi tun ṣakiyesi ninu iwa ọkunrin naa ni pe ọpọ igba ni wọn lo maa n fi ada to fi n kọ ẹyin gunlẹ, ti yoo si so aṣọ pupa mọ eeku ada naa, lẹyin eyi loun funra rẹ yoo waa sun si ẹgbẹ ada to ri mọlẹ, ti yoo si ṣiju soke ọrun, bẹẹ ni yoo maa jẹnu wuyẹwuyẹ.
Igba mi-in wa ti wọn ni oke ọpẹ lo maa n gbe Indomie rẹ lọ, lẹyin to ba se e tan nibẹ ni yoo jẹ ẹ.
Ọsẹ to kọja lọ lọhun-un ni wọn lo lọọ ba iya agbalagba kan ti wọn n pe ni Iya Pupa, to si bẹ ẹ pe ko ba oun wa iṣẹ to le mu owo wọle foun.
Ohun to sọ yii lo mu ki iya naa bẹ ẹ lọwẹ pe ko ba oun ko koko oko oun wale, ti wọn si fẹnu ọrọ jona si ẹgbẹrun kan ati igba Naira.
Ko too di pe o bẹrẹ iṣẹ ni iya naa ti fun un ni ẹẹdẹgbẹta Naira, iṣẹ naa ko si ti i pari nigba to ti n beere owo rẹ to ku lọwọ mama yii.
Ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja lọhun-un ni wọn lo tun lọọ ka iya mọle, to si fi dandan le e fun un pe o gbọdọ sanwo iṣẹ oun.
Loju ẹsẹ ni wọn ni mama naa ti wọle, to si ko ẹgbẹta Naira fun un, owo naa lo si bi ọkunrin yii ninu to fi bẹrẹ si i fa wahala pẹlu iya yii, wọn ko si ti i sọrọ jinna to fi fa ibọn yọ, to si yin in lu iya yii lẹsẹ.
Titi di asiko yii, ọsibitu kan lagbegbe Sabo, niluu Ondo, ni obinrin naa wa, nibi to ti n tọju ara rẹ.
Awọn ara abule kan lo mu ẹjọ ohun to n ṣẹlẹ yii lọ si tesan ọlọpaa to wa ni Ẹnuọwa. Nigba ti awọn ọlọpaa si lọ si abule naa lero ati lọọ mu afurasi ọdaran naa, ada lo yọ si wọn, to si sọ fun awọn ọlọpaa to waa mu un pe ẹni to ba laya ninu wọn ko maa bọ.
Ẹyin ni gbogbo awọn ọlọpaa naa fi rin pada siluu Ondo. Aarọ ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja ni ọkunrin ọhun tun gbe ara mi-in yọ, eyi to ko gbogbo awọn ara abule naa atawọn to wa nitosi wọn sinu ipaya nla.

Baba agbalagba kan, Oluṣẹgun Ọyadele, ni wọn lo n sa koko rẹ niwaju ita ile rẹ nigba ti ọkunrin Urhobo ọhun lọọ ka a mọbẹ, to si ṣa baba naa pa.
Eyi ni awọn ara abule naa ri ti olukuluku wọn fi ba ẹsẹ rẹ sọrọ, to si waa ku ọkunrin ọhun nikan ati oku baba to ṣa pa ni gbogbo abule.
Awọn eeyan kan ninu abule naa ni wọn tun mu ẹjọ lọ si teṣan ọlọpaa to wa niluu Ondo, ere lasan ni awọn ọlọpaa si pe ọrọ naa, nitori awọn diẹ ni wọn ko ara wọn jọ sinu ọkọ lero ati lọọ mu ọkunrin yii.
Ibi ti awọn ọlọpaa ti n gbiyanju ati mu un lo ti yari mọ wọn lọwọ, to si fi ada ọwọ rẹ ge apa ọkan ninu awọn ọlọpaa naa, to si tun gba ibọn ọwọ rẹ, kiakia lawọn yooku si sa lọ.
Iroyin ohun to ṣẹlẹ yii lo mu ki ikọ ọlọpaa mi-in tun ko si motọ lati lọọ mu ọkunrin ọhun ni tipatipa, ori lo tun ko isọri keji awọn ọlọpaa naa yọ lọwọ iku ojiji, bo tilẹ jẹ pe o tun ṣa ọkan ninu wọn ladaa yanna-yanna.
Ọga ọlọpaa kan tawọn eeyan mọ si Alaaji, lo ṣaaju awọn isọri ọlọpaa kẹta lọ sibi iṣẹlẹ ọhun, bi wọn si ṣe n lọ ni wọn ko awọn ọmọ ẹgbẹ OPC atawọn tọọgi kan dani la ti lọọ koju ọkunrin to ti dẹru jẹjẹ naa.
Fun bii ọgbọn iṣẹju ni wọn kọkọ fi wa a kaakiri abule naa ti wọn ko ri i, ko too di pe o yọ si wọn lojiji, ọga awọn ọlọpaa ọhun lo kọkọ fa ibọn yọ, to si bẹrẹ si yin in si i, ṣugbọn ibọn ko dahun.
Lẹyin eyi ni wọn lọgaa wọn ọhun kunlẹ, to si pe ibọn ọwọ rẹ lorukọ to n jẹ ko too di pe ibọn dahun, nigba ti gbogbo wọn yinbọn titi, ṣugbọn ti ibọn kọ ti ko wọle si anjannu ibẹru ọhun lara, to si n sunmọ ọdọ wọn pẹlu ada to mu lọwọ, ni gbogbo wọn yiju pada, ti wọn si n sa lọ.
Nibi ti wọn ti n sa lọ ni ọkan ninu awọn ọlọpaa ti wọn jọ lọ, Sajẹnti Abiọdun Ọmọtẹhinwa, ti ṣeeṣi ṣubu lulẹ, nibi to ti n gbiyanju ati dide lọkunrin ọhun ka a mọ, to si sa a pa.
Ko pẹ ti okiki ọrọ naa fi kan kaakiri ilu Ondo, eyi to si da jinnijinni bo awọn eeyan. Osemawe ilu Ondo, Ọba Victor Kiladejọ, to wa niluu Eko lasiko ti iṣẹlẹ ọhun ṣẹle ni wọn lo sare pe Oloye Ayadi tilu Ondo lati tete ko awọn ọlọdẹ ati babalawo jọ, ki wọn si wa gbogbo ọna lati lọọ koju iṣẹlẹ naa.
Ni nnkan bii aago marun-un aabọ irọlẹ ọjọ naa ni awọn ọlọpaa adigboluja ti wọn to ogun niye, awọn ọdẹ ati babalawo ko ara wọn sinu ọkọ bii mẹta, pẹlu ọpọlọpọ ọkada, ti wọn si mori le abule naa lati lọọ koju ọkunrin ọhun.
Aago mẹsan-an alẹ kọja ni wọn pada de, ti wọn si ni ọkunrin naa ti sa kuro labule. Ọsan ọjọ yii ni awọn ọmọ baba agbalagba to ṣalabaapade iku ojiji naa ṣeto mọto ti wọn fi gbe baba wọn lọ si ilu Mọdakẹkẹ, nipinlẹ Ọṣun, nibẹ ni wọn si ti lọọ fi eepẹ bo o laṣiiri.
Oku ọlọpaa to ba iṣẹlẹ ọhun rin la gbọ pe o ṣi wa ni mọṣuari ileewosan ijọba to wa niluu Ondo, nigba ti awọn ọlọpaa mejeeji to farapa naa ṣi n gba itọju lọwọ nileewosan kan naa.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Fẹmi Joseph, sọ fun akọroyin wa pe ọwọ ọlọpaa ti tẹ ọkunrin yii ni nnkan bii aago mẹwaa alẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja naa.
Abule kan ti wọn n pe ni Tẹkunlẹ lo sọ pe wọn ti ri i mu. O fi kun un pe ọkunrin yii tun gbiyanju lati ṣakọlu si awọn ọlọpaa to fẹẹ mu un ko too di pe wọn kapa rẹ, ti wọn si fi panpẹ ọba gbe e.
Ileewosan kan niluu Akurẹ lo sọ pe o ṣi wa lasiko ti a fi n ko iroyin yii jọ, nibi to ti n gba itọju.

(5)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.