Wẹda fi aṣọ ọlọpaa lu jibiti daran n’Ibadan, awọn ọlọpaa ti gba a mu

Spread the love

Ọpọ awọn to fẹran ìfà n’Ibadan, ni ìfà ti fa lapo ya bayii pẹlu bi wọn ṣe ko sọwọ onijibiti nibi ti wọn ti n wa mọto olowo pọọku kiri.
Ṣugbọn ọwọ awọn agbofinro ti tẹ onijibiti ọhun, Adebisi Kayọde, ẹni to n gbowo ọkọ lọwọ awọn eeyan bii dílà lai ni kẹkẹ kankan to fẹẹ ta fun ẹnikẹni, beletase mọto.
Kayọde ti iran rẹ kankan ko ṣiṣẹ ọlọpaa ri lo maa n purọ fawọn eeyan pe ripẹtọ ọlọpaa loun ni ẹka awọn saasi (SARS), iyẹn awọn agbofinro to n gbogun ti idigunjale n’Ibadan. Aṣọ ọlọpaa ti wọn si maa n ri lọrun ẹ lẹẹkọọkan lo mu ki awọn yẹn gba a gbọ.
Gẹgẹ bi ọga agba awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CP Abiọdun Odude, ṣe fidi ẹ mulẹ fawọn oniroyin lolu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ ọhun to wa l’Ẹlẹyẹle n’Ibadan, niṣe lafurasi onijibiti yii maa n fi awọn eeyan lọkan balẹ lori ohun ti agbara ẹ ko ka, yoo ni oun yoo ba wọn ri ọkọ olowo nla ra lọwọ ileeṣẹ ọlọpaa pẹlu owo pọọku.
Gbogbo aye lo mọ pe tita lawọn ileeṣẹ agbofinro gbogbo maa n ta awọn awọn nnkan irinsẹ atawọn dukia mi-in ti wọn ba ti gba lọwọ awọn afurasi ọdaran ṣugbọn ti wọn ko ri ẹni beere wọn mọ lẹyin ọpọlọpọ ọdun ti awọn nnkan irinsẹ ọhun ba ti wa ninu ọgba wọn.
Lẹyin ti Kayọde ba gba owo lọwọ awọn eeyan tan ni wọn yoo wa a tìtí, ti wọn ko ni i ri i, bẹẹ ni wọn ko ni i ri i pe lori foonu nitori bo ba ti huwa ọdaran bẹẹ fẹnikan ni yoo ti paarọ opo ibanisọrọ rẹ.
“Ọpọ igba lawọn eeyan ti mu ẹsun ọkunrin yii wa sọdọ wa, wọn aa ni awọn fẹẹ ra mọto lọwọ ileeṣẹ ọlọpaa, o si ti gbowo lọwọ awọn, ṣugbọn ko gbe ọkọ fawọn. O pẹ ta a ti n dọdẹ rẹ kiri ko too di pe ọwọ awọn ọlọpaa to n gbogun ti iṣẹlẹ ijinigbe (AKS), tẹ ẹ”, bẹẹ lọga agba awọn ọlọpaa sọ.
Ṣẹkẹṣẹkẹ (ankọọbu), kòbòkóbò, kaadi idanimo ileeṣẹ MTN meji, opo ibanisọrọ MTN mẹrin ọtọọtọ pẹlu oogun abẹnu gọ̀ǹgọ̀ ni CP Odude sọ pe awọn ọlọpaa ba lọwọ afurasi ọdaran yii lẹyin ti ọwọ tẹ ẹ tan.
Ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu awọn oniroyin, Kayọde jẹwọ pe loootọ loun maa n purọ gbowo mọto lọwọ awọn eeyan lai ta mọto fun wọn, ati pe eṣu ló lo oun debi iwa èpè yii.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Mi o ki i ṣe ọlọpaa, ọrẹ mi kan lo jẹ ọlọpaa ti mo maa n wọ awọn nnkan rẹ. Miliọnu kan ati ẹgbẹrun lọna igba Naira (N1.2M), ati diẹ ni mo ti gba lọwọ awọn eeyan.
“Iṣẹ wẹ́dà ni mo n ṣẹ. Mi o jẹ ki iyawo mi mọ pe mo n lu jibiti. Ileeṣẹ MTN ni Pọtakọọtu ni mo sọ fun un pe mo ti n ṣiṣẹ nigba ta a fi n fẹra sọna. Nigba ta a fi maa ṣegbeyawo, mi o ṣiṣẹ nibẹ mọ, ṣugbọn mi o jẹ ko mọ
“Lọjọ to beere pe ki lo de ti mi o ṣiṣẹ nileeṣẹ MTN mọ, mo ni ọja o ya nibẹ mọ ni.”
Ọga agba awọn ọlọpaa sọ pe ni kete ti iwadii to n tẹsiwaju lori awọn ọran ti Kayọde da ba ti pari lawọn yo foju ọkunrin naa bale-ẹjọ.

(30)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.