Wahalani PDP Ekiti: Awọn to fẹẹ dije ile igbimọ kọlu sẹkiteriati ẹgbẹ

Spread the love

Ṣe lawọn oloṣelu to fẹẹ dupo ile igbimọ aṣoju-ṣofin ninu ẹgbẹ oṣelu People’s Democratic Party(PDP), ya bo sẹkiteriati ẹgbẹ naa lọjọ Aiku, Sannde ijẹta, pẹlu awọn ololufẹ wọn, nibi ti wọn ti da rogbodiyan silẹ lori ẹsun pe Gomina Ayọdele Fayoṣe fẹẹ fi agbara fun awọn to wu u ni tikẹẹti ẹgbẹ.

Ṣe lawọn ololufẹ awọn oloṣelu naa kọlu awọn ọmọ ikọ igbimọ ko-tẹ-mi-lọrun ti Ọgbẹni Kazeem Ọladipupọ ṣaaju, wọn si din dundu iya diẹ fun wọn ki onikaluku too wa ibi gba sa lọ, bẹẹ ni wọn fọ gilaasi atawọn nnkan mi-in ni sẹkiteriati naa.

Awọn ti wọn fi erongba han lati dupo ile igbimọ aṣoju-ṣofin naa ni:Ṣẹgun Ọlanipekun, Ademọla Salami, Temitọpẹ Oluwatosin Ajayi, Goke Omidiran, David Arowolo, Adekunle Ojo, Ibrahim Mumini Adewale, Victor Alale ati Abilekọ Kẹmi Adewumi.

Wọn fẹsun kan awọn ọmọ igbimọ to fẹẹ ṣayẹwo fawọn oludije, eyi ti Ọgbẹni Ṣẹyẹ Shonuga jẹ olori fun pe wọn n wa ọna lati fun awọn ọrẹ Fayoṣe atawọn to wa nipo lọwọ ni tikẹẹti ẹgbẹ fun idibo ọdun to n bọ.

ALAROYE gbọ pe awọn agbofinro atawọn ọmọ ẹgbẹ kan lo sare gbe alaga yii sa kuro nibudo naa ki wọn too da sẹria fun un.

Nigba to n sọrọ lorukọ awọn to ku, Ṣẹgun Ọlanipẹkun ni aṣẹ Fayoṣe ni igbimọ ti wọn ran wa si Ekiti n tẹlẹ, nitori ṣe ni wọn n sọ pe awọn ko san owo-ori, eyi ti ko si ootọ nibẹ, wọn si fọgbọn yọ gbogbo awọn ki wọn le fun awọn ti wọn fẹ ni tikẹẹti.

O fẹsun kan Fayoṣe pe o ti kọkọ pe awọn sipade kan pe kawọn fopin si erongba awọn nitori oun yoo yan awọn toun fẹ, ṣugbọn awọn ko ni i gba, nitori idibo abẹle gbọdọ waye.

O ni ki i ṣe PDP to ṣẹṣẹ padanu ibo Ekiti lo yẹ ko maa ni iru iṣoro yii nitori araalu yoo maa ro pe awọn ko mọ nnkan tawọn n ṣe ni.

Nigba to n fesi si ọrọ yii, Ọgbẹni Jackson to jẹ akọwe iroyin ẹgbẹ naa l’Ekiti ni oun ko si nile lati ri itu tawọn eeyan naa pa, ṣugbọn irọ ni awọn ẹsun ti wọn ka silẹ. O ni awọn ko ti i ṣe idibo abẹle lati mu oludije nitori ọgbọnjọ, oṣu yii, ni awọn yoo yan awọn oludije ile igbimọ aṣoju-ṣofin, ti ile igbimọ aṣofin agba yoo waye lọjọ kin-in-ni, oṣu to n bọ, nigba ti tile igbimọ tipinlẹ yoo waye lọjọ kẹta, oṣu to n bọ.

(26)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.