Wahala ni FUOYE: Awọn ọmọ ẹgbẹ da ipade ru, wọn lawọn fẹẹ yọ alaga

Spread the love

Wahala to n lọ lọwọ ninu ẹgbẹ awọn olukọ, Academic Staff Union of Univeristies (ASUU), ẹka ileewe giga ijọba apapọ, Federal University, to wa niluu Ọyẹ-Ekiti ko ti i jọ pe yoo pari bayii pẹlu bi awọn ọmọ ẹgbẹ ṣe sọ pe Ọmọwe Akinyẹmi Ọmọnijọ to jẹ alaga gbọdọ fipo silẹ.

 

Lọdun to kọja ni alaga yii pẹlu awọn mi-in ti Ọjọgbọn Olu-Olu Olufayọ to jẹ alaga ASUU lawọn fasiti to sun mọ ipinlẹ Ondo fẹsun kan Ọjọgbọn Kayọde Ṣorẹmẹkun to jẹ ọga-agba FUOYE pe o n gba awọn oṣiṣẹ lọna aitọ, ki i sanwo ifẹyinti, bẹẹ lo hu awọn iwa mi-in ti ko bofin eto ẹkọ mu.

 

Awọn ẹsun wọnyi ni Ṣorẹmẹkun atawọn mi-in bii Ọmọwe Opoọla Bọlanle Tajudeen sọ pe ko fẹsẹ mulẹ nitori ijọba apapọ lo n ṣeto ileewe ọhun, latigba naa si ni ASUU ti pin yẹlẹyẹlẹ. Awọn kan pe ara wọn ni Academic Staff Concerned Group, awọn kan n jẹ Congress of Nigerian Academics, nigba ti New Academic Staff Union of FUOYE da duro.

 

Latigba naa ni wọn ti n pe fun iyọnipo Ọmọnijọ, ẹni ti wọn fẹsun kan pe o n tukọ ẹgbẹ naa bii ẹgbẹ okunkun, nitori nnkan to wu u lo n ṣe. Alaye ti alaga naa ṣe ni pe awọn kan lo ko ara wọn jọ ti wọn fẹẹ da ẹgbẹ ru, ati pe ọna ẹburu ni wọn fẹẹ gba yọ oun.

 

Lasiko ipade ti ẹgbẹ naa ṣe, ninu eyi ti Olu-Olu wa lawọn tinu n bi ti ya bo ipade, ti wọn si gba mọto toun atawọn to ku gbe wa. Wọn tiẹ leri lati dana sun un ki adari eto aabo ileewe naa too ba wọn da si i, to si niyanju lẹyin bii wakati mẹta.

 

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Ọmọwe Opoọla ni Olu-Olu atawọn to ku rẹ gbọdọ fi awọn silẹ lati pari wahala to n lọ labẹnu ti wọn ba fẹ kọrọ lojutuu. O ni awọn ti dabaa pe Ọmọnijọ gbọdọ fipo silẹ kawọn too le ṣepade kankan, eyi si ni ọna abayọ kan ṣoṣo si awuyewuye naa.

 

(23)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.