WAHALA INU ẸGBẸ APC N LE SI I O *Amosun ati Akeredolu ni dandan ni ki Oshiomhole lọ *Ṣugbọn Tinubu ni wọn o to bẹẹ!

Spread the love

Alaga ẹgbẹ APC wa ninu idaamu o. Ọkunrin ti wọn n pe ni Adams Oshiomhole naa paapaa ko le sọ ọna ti yoo ba yọ ninu idaamu yii, bi ko ba si ṣọra, idaamu naa le bọ ṣokoto nidii rẹ, ti yoo si sọ ọ di korofo ọkunrin. Bi a ti n sọrọ yii, awọn alaga ẹgbẹ APC lawọn ipinlẹ kan ti n mura pe ko sọna ti Adams le gbe e gba, awọn yoo yọ ọ danu nipo alaga gbogbogboo to wa yii, nitori awọn ti ri i pe ipo naa ko ba a mu, ko ni iwa ati iṣesi alaga rara. Ṣugbọn Oshiomhole funra rẹ ti sọ pe ala lasan lawọn eeyan naa n la, o ni ọrọ wọn ko yatọ si igba ọkọ, igba ada, ti wọn n ba oke e ṣọta, oke ko jẹ, oke ko mu, oke naa ni yoo rẹyin gbogbo wọn. O ni oun mọ pe awọn gomina kan ni wọn n ran wọn niṣẹ soun, ṣugbọn bi wọn pọ ju bẹẹ lọ, wọn ko ti i pọ to ni o, nitori ko sẹni to to lati yọ oun nipo alaga ninu wọn.
Ọrọ yii le gan-an lọsẹ to kọja debii pe Oshiomhole ko awọn oniroyin jọ, nibẹ lo si ti sọ awọn kobakungbe ọrọ si awọn gomina ipinlẹ meji kan, Ibikunle Amosun ti Ogun ati Rochas Okorocha ti Imo. Ohun ti eyi fihan ni pe alaga APC naa mọ pe awọn gomina meji yii gan-an ni wọn ṣaaju awọn to ku ti wọn fẹẹ yọ oun nipo. Oun naa ko si ba wọn mu ọrọ naa ni kekere rara. O ni alainitiju ni gomina Okorocha, oun tabi APC kọ ni yoo si lo lati sọ ipo iṣẹ ijọba di oye ti wọn n jẹ ni idile rẹ laarin oun atawọn ẹbi ẹ nikan. O ni bi gomina yii ba nitiju ni, ko ni i sọ pe dandan ni ko jẹ ọkọ ọmọ oun, Uche Nwozu, ni yoo jẹ gomina lẹyin oun, to si n wa gbogbo ọna lati ri i pe ko sẹlomi-in ti yoo de ipo naa, afi ọkọ ọmọ oun toun ti fa kalẹ yii. Bẹẹ oun naa ko duro, o fẹẹ lọ sile-igbimọ aṣofin, o si fẹẹ mu iyawo rẹ lọ.
Oshiomhole ni ohun ti oun ṣe to n bi Okorocha ninu ree, to si tori rẹ gbe ẹni ati bẹẹdi to n sun ni Aso Rock, iyẹn nile Aarẹ Buhari, o ni bo si sun nibẹ ju bẹẹ lọ, ofo ni yoo mu bọ, nitori awọn ti ṣe ohun to yẹ ki awọn ṣe. Ni ti Amosun ẹwẹ, o ni ọkunrin gomina Ogun naa sọ ara rẹ di ooṣa kekere akunlẹbọ sawọn eeyan rẹ lọrun ni, pe o sọ ara rẹ di Ọlọrun wọn. O ni ko tẹle gbogbo eto ti wọn la kalẹ lati le yan awọn eeyan sipo, oun kan jokoo ni tirẹ, o n yọ awọn to ba fẹ kuro, o n fi orukọ awọn mi-in si i ni. O ni awọn ti ṣeto ibo nibẹ, awọn si ti mu Ọmọọba Dapọ Biọdun lati du ipo lorukọ ẹgbẹ awọn, ṣugbọn Amosun ko tori rẹ kuro nidii ọrọ naa, gbogbo igba lo n lọ lati daamu Aarẹ Buhari, o fẹ ki aarẹ paṣẹ fun awọn lati yi ohun ti awọn ti ṣe pada. Alaga APC yii ni iyẹn ko ni i ṣee ṣe, ati pe ohun to n bi Amosun ninu soun niyẹn.
Amosun ko jẹ ki ọrọ ti ọkunrin yii sọ tutu to fi da a lohun, o ni ọti lo n pa a, nitori bi ko ba jẹ bẹẹ, ko ni i maa sọ kantankantan lẹnu. O ni ko si ohun meji ti ọkunrin yii fẹẹ ṣe ju ko fa ipinlẹ Ogun le awọn alagbata ọja oṣelu kan lọwọ lọ, awọn ti wọn wa l’Ekoo ti wọn n wa agbara lọ sibomi-in. Olowe mọ owe lọrọ naa, Amosun ko si fi bo rara pe Aṣiwaju Bọla Tinubu loun n ju oko ọrọ naa ranṣẹ si. O ni Tinubu ati Oloye Oluṣẹgun Ọṣọba ni wọn wa nidii ọrọ oun, awọn ni wọn si n lo Oshiomhole lati dojuti oun, ṣugbọn Ọlọrun yoo dojuti wọn nitori oun yoo bori gbogbo wọn. Amosun ko sọ ọna ti yoo fi bori awọn eeyan yii, ṣugbọn lọjọ keji lo ti mu ẹwu rẹ wọ, Abuja lo kọri si lẹlẹ, oun ati Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu ati Kayọde Fayẹmi ti Ekiti si tun jọ ri Buhari.
Ko ti i sẹni to mọ ohun ti Buhari yoo ṣe si ọrọ naa, nitori Alaga ati awọn igbimọ apaṣẹ ẹgbẹ APC ti fi orukọ gbogbo awọn ti yoo dupo gomina lorukọ ẹgbẹ wọn ranṣẹ si ajọ to n ṣeto ibo, ko si sẹni to mọ boya Buhari yoo ni ki Oshiomhole fa awọn orukọ naa yọ tabi ko fi wọn silẹ ni. Alaroye gbọ pe ẹjọ ti awọn gomina ilẹ Yoruba yii n ro fun Buhari ni pe Tinubu lo n lo Oshiomhole, ati pe gbogbo ohun to n ṣe ni bi yoo ṣe da ẹgbẹ APC ru ni awọn ipinlẹ naa, to jẹ nigba tawọn ba dibo, Atiku ni yoo wọle, nitori ọrẹ loun ati ọkunrin PDP naa. Boya Buhari gba ọrọ naa tabi ko gba a lẹnikan ko ti i mọ, nitori alaye kan ko jade lati ileeṣẹ aarẹ lẹyin ti awọn gomina naa ba a ṣepade tan.
Yatọ si awọn gomina meji to gbe ọrọ naa ru yii, iyẹn Amosun ati Okorocha, awọn gomina mẹta mi-in tun wa ti inu wọn ko dun si Oshiomhole rara, gbogbo wọn lo si n daamu Buhari pe ko jẹ ki awọn yọ ọ danu bi awọn ba fẹ ilọsiwaju ninu ẹgbẹ APC, nitori gẹgẹ bi Okorocha ti sọ, lati igba ti Oshiomhole ti di alaga ẹgbẹ awọn ni ina ẹgbẹ naa ti n jo ajorẹyin. Gomina Ondo naa ti binu daadaa, ko si jọ pe kinni kan wa ti alaga APC yii yoo ṣe ti yoo tẹ ẹ lọrun mọ rara. O ni ọkunrin naa ko kun oju oṣuwọn lati ṣe iru iṣẹ ti wọn gbe fun un yii, Akeredolu ni ọgbọn ori ati iriri Oshiomhole ko gbe iṣẹ naa rara. Bẹẹ ni Gomina Zamfara, Abdulaziz Yari, naa binu ju, o ni kẹnikẹni ma darukọ Oshiomhole leti oun. Nasir El-Rufai ti Kaduna tilẹ le ṣe alaga APC yii leṣe bo ba ri i ni kọrọ, o ni eeyan jatijati ni.
Ki lo de ti awọn gomina naa n ṣe bayii, tabi bawo ni agbara awọn gomina naa ti to ti wọn fi lero pe awọn le yọ alaga ẹgbẹ wọn, ati pe ohun ti wọn ba fẹ lo gbọdọ ṣẹlẹ ninu APC. Shehu Sani, Sẹnetọ lati Kaduna to ṣẹṣẹ binu kuro ninu ẹgbẹ yii lo ṣalaye, o ni APC ti ẹ ri yẹn, awọn gomina lagbara debii pe ko sohun ti wọn ko le ṣe. O ni ko si ohun to fa agbara wọn ju pe Buhari ko laapọn mọ lọ, apa rẹ ko si ka awọn gomina naa, nitori o ro pe awọn ni wọn le ṣe e ki oun fi wọle ibo lẹẹkeji, bi wọn ba si n ṣebajẹ, ki i ba wọn wi. O ni nitori pe Buhari ko lagbara lori awọn gomina yii, alaga APC kankan ki i lagbara lori wọn. Shehu Sani ni ni ti Tinubu, ọkunrin naa ti ṣe gbogbo ohun to le ṣe, ṣugbọn apa rẹ ko ka ija naa nitori ko wa lati ilẹ Hausa, awọn gomina ilẹ Hausa ko si ka a si nnkan gidi kan.
Bẹẹ, gbogbo ohun to si ṣẹlẹ yii, ibo abẹle ẹgbẹ wọn ti wọn di kọja yii lo fa a o. Awọn gomina wọnyi ti ni ẹni ti awọn fẹ ko wọle, tabi ẹni ti wọn fẹ ko gbajọba lọwọ wọn, ṣugbọn awọn igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ APC yi erongba wọn pada, inu si bi wọn pe Oshiomhole lo ṣe awọn pa. Paripari rẹ ni ti awọn gomina kan ti wọn ti kọyin si Tinubu tẹlẹ ti wọn jabọ yii, wọn ni Tinubu lo ṣe awọn leṣe nitori oun lọga Oshiomhole, ohun to ba sọ niyẹn n ṣe. Tinubu naa si ti jade, o ni ki wọn fi Oshiomhole silẹ, iṣẹ ti ẹgbẹ gbe fun un lo n ṣe, bẹẹ ni ko ṣẹ sofin ẹgbẹ kankan. Eyi tubọ run awọn eeyan naa ninu, bi wọn si ti n paara ọdọ Buhari ni wọn n ba awọn alaga ẹgbẹ ni ipinlẹ kọọkan sọrọ, wọn ni ki wọn jẹ ki awọn yọ Oshiomhole danu ko too ko wahala wọ inu ẹgbẹ wọn.
Bẹẹ lo jẹ lati ilẹ Yoruba titi de ilẹ Ibo, titi ṣe bẹẹ wọ ilẹ Hausa, ko si adugbo kan ti ko ti si wahala ninu APC, nitori ibo abẹle ti wọn di lọ yii, ọrọ naa si ti kọja agbara ẹnikẹni ninu ẹgbẹ, afi Buhari nikan. Bi Aarẹ yoo ti waa yanju ọrọ naa lẹnikan ko mọ, nitori ohun to le ko ifasẹyin nla ba ẹgbẹ wọn ni.

(34)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.