Wahala ilu Isaoye Ekiti: Ijọba fun kabiyesi loṣu meji lati ṣeto alaafia

Spread the love

Latari wahala to waye niluu Isaoye Ekiti, nijọba ibilẹ Mọba, laarin awọn eeyan ilu naa ati Ọba Gabriel Dare Ọlajide, ijọba ipinlẹ Ekiti ti fun kabiyesi naa loṣu meji lati pari aawọ ọhun.

 

Lopin ọsẹ to kọja nipade alaafia waye lọdọ igbakeji gomina ipinlẹ Ekiti, Ọtunba Bisi Ẹgbẹyẹmi, nibi ti kabiyesi, awọn oloye rẹ ati Oore tilu Ọtun Ekiti to tun jẹ olori awọn ori ade Mọba, Ọba Adedapọ Popoọla, pesẹ si.

 

Awọn ẹsun ti wọn fi kan Ọba Ọlajide ni pe o n fi ọwọ lile tukọ ilu naa, o n fọlọpaa halẹ mọ araalu, ki i ṣe awọn nnkan aṣa ati iṣe, o ṣakọlu sawọn ọmọ ilu kan, o ba awọn nnkan Ifa jẹ, bẹẹ ni ki i ṣepade pẹlu awọn oloye rara.

Ẹgbẹyẹmi to fun awọn tọrọ ọhun kan di ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu keji, ọdun to n bọ sọ pe ijọba ko ni i lọkan lati yọ ọba kankan, ki alaafia le jọba ni tolori tẹlẹmu n le. O fi ẹdun ọkan han lori awọn ẹsun ti wọn fi kan ọba naa, o ni o yẹ ko ti mọ awọn aṣa ilu naa ko too gba lati de ade.

Nigba to n fesi, Ọba Ọlajide ni ko si ootọ ninu awọn ẹsun ti wọn ka soun lẹsẹ nitori gbogbo erongba oun fun ilu naa ni ki alaafia jọba. O ni Isaoye ko ni ilọsiwaju, idi si ni pe awọn aṣa kan ko ba igba mu mọ.

Ninu ọrọ tiẹ, Ọba Popoọla dupẹ lọwọ Ọtunba Ẹgbẹyẹmi lori igbesẹ to gbe, bẹẹ lo ni gbogbo ipa loun ti sa lati pari ọrọ naa, ṣugbọn kabiyesi ti wọn fẹsun kan ko fọwọ sowọ pọ pẹlu ẹnikẹni. O waa ṣeleri pe laarin oṣu meji naa lawọn yoo pari ọrọ ọhun, ti alaafia yoo si jọba.

 

 

(0)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.